INEC kéde orúkọ àwọn olùdíje fún ìbò Gómìnà Ekiti lọ́dún 2026, olùdíje fẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP kò sí níbẹ̀, ìdí rèé

Dokita Wole Oluyede wọ aṣọ buba pupa

Oríṣun àwòrán, Gboyega Adeoye

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ eleto idibo INEC ti kede awọn oludije sipo gomina fawọn ẹgbẹ oṣelu ṣaaju eto idibo ọdun 2026 to n bọ, amọ, ko si orukọ oludije fẹgbẹ oṣelu PDP, Wole Oluyede, nibẹ.

Awọn orukọ oludije sipo gomina ọhun pẹlu awọn to fẹ ṣe igbakeji wọn lati ẹgbẹ oṣelu mejila ni INEC lẹ si ọfiisi rẹ to wa ni ilu Ado Ekiti lọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kejila yii.

Awọn oludije lati inu ẹgbẹ oṣelu mejila yii ni ajọ INEC ti ṣayẹwo fini fini lori wọn ko to gbe orukọ wọn jade.

Gẹgẹ bi atẹjade ti INEC fi sita ṣe sọ, awọn oludije ọhun ni Opeyemi Falegan fẹgbẹ oṣelu Accord Party; Akande Oluwasegun fun ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC); Ayodeji Ojo ti ẹgbẹ Action Democratic Party (ADP); Oluwadare Bejide fun ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC); ati Gomina Biodun Oyebanji fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).

Awọn mii ni Bidemi Awogbemi fun ẹgbẹ Action People's Party (APP); Joseph Anifowose ti ẹgbẹ Allied People's Movement (APM); Oyebanji Olajuyin fun ẹgbẹ Labour Party (LP); Blessing Abegunde ti ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People's Party (NNPP); Olaniyi Ayodele fun People's Redemption Party (PRP); Owoola Daramola fun ẹgbẹ oṣelu Young Progressive Party (YPP); ati Victor Adetunji to jẹ oludije sipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party (ZLP).

Amọ, orukọ oludije sipo gomina fẹgbẹ PDP, Oluyede, ko si ninu awọn orukọ naa bo tilẹ jẹ pe oun lo jawe olubori ninu ibo abẹnu ẹgbẹ naa to waye loṣu Kọkanla to kọja.

INEC kede pe oun ko ri igbimọ amuṣẹya PDP ti Kabiru Turaki jẹ alaga rẹ gẹgẹ bi igbimọ to ba ofin mu

Igbimọ amuṣẹya PDP, NWC, lo ṣagbatẹru eto idibo to gbe Oluyede wọle, Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo naa si ṣatilẹyin fun igbimọ ọhun.

Ibo 279 ni Oluyede ri ninu ibo abẹnu ọhun, nigba ti Ọgbẹni Funso Ayeni to ṣe ipo keji ri ibo 239.

A gbọ wi pe bi ko ti si orukọ oludije PDP lara awọn orukọ ti INEC kede ko ṣẹyin aawọ to n ṣẹlẹ laarin awọn adari ẹgbẹ naa.

Igun kan ninu ẹgbẹ PDP n tẹle minisita Abuja, Nyesome Wike.

Igun miran ẹwẹ ninu ẹgbẹ oṣelu naa n tẹle Gomina Makinde ipinlẹ Oyo ati Gomina Bala Mohammed ipinlẹ Bauchi.

Ti ẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja ni INEC kede pe oun ko ri igbimọ amuṣẹya PDP ti Kabiru Turaki jẹ alaga rẹ gẹgẹ bi igbimọ to ba ofin mu.

Ajọ INEC ṣalaye pe oun ko ni gbe akọsilẹ kankan nipa ẹgbẹ oṣelu PDP jade, ayafi ti ẹgbẹ naa ba yanju oniruuru ẹjọ to jẹyọ lẹyin ipade apero gbogbogbo ẹgbẹ naa to waye niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo loṣu Kọkanla ba yanju tan.