Ọ̀rọ̀ di gbas-gbos láàárín Makinde àti Fayose lórí ₦50bn tí Fayose ní Tinubu fún ìpínlẹ̀ Oyo lórí ìbúgbàmù Bodija n'Ibadan

Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo wọ aṣọ buluu ati fila, Ayo Fayose gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ wọ buba funfun

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti sọ pe irọ to jina si oootọ ni ọrọ ti Ayo Fayose, gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, sọ pe oun dari owo iranwọ toun gba lati ọdọ ijọba apapọ lori ibugbamu to ṣẹlẹ lagbegbe Bodija niluu Ibadan si ibomiran.

Ṣaaju ni Fayose sọ lori eto tẹlifisan TVC kan wi pe aadọta biliọnu naira (N50bn) ni Makinde ri gba gẹgẹ bi owo iranwọ lati ọdọ Aarẹ Bola Tinubu, ko to di pe o bẹrẹ si ni sọ oriṣiiriṣii bayii nipa aarẹ.

Amọ, nigba to n fesi si ẹsun ti Fayose fi kan an, oludamọran gomina Makinde lori eto iroyin, Sulaimon Olanrewaju, ṣalaye pe ọgbọn biliọnu (N30bn) ni aarẹ fi ṣọwọ si ipinlẹ Oyo gẹgẹ bi owo iranwọ lori ibugbamu to sọ ọpọ eeyan di alainile lori mọ n'Ibadan.

Ọgbẹni Olanrewaju sọ pe kii ṣe aadọta biliọnu (N50bn) ti gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ sọ.

Oludamọran Makinde ṣalaye pe awọn iwe akọsilẹ lori owo naa ti Fayose sọ nipa rẹ niṣe pẹlu erongba ijọba apapọ lati fowo naa ṣọwọ si ipinlẹ ni, akọsilẹ naa ko sọ pe ijọba ti fun ipinlẹ Ọyo aadọta biliọnu.

Makinde ṣalaye ninu atẹjade ti oludamọran rẹ fi sita pe oun lọ ba Aarẹ Tinubu lẹyin ibugbamu to waye ni Bodija lati beere fun iranwọ ijọba apapọ.

O ni nigba naa ni ijọba apapọ ṣeleri lati fi N50bn ranṣẹ gẹgẹ bi owo iranwọ, amọ, N30bn ni aarẹ pada fi ṣọwọ si ipinlẹ Oyo.

''Ṣiṣe ileri yatọ si fifi owo ranṣẹ, N30bn ni ijọba apapọ pada fi ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Oyo.

N20bn toku ko tii tẹ ijọba ipinlẹ Oyo lọwọ titi ti asiko yii tori Makinde ko ṣetan lati ṣe awọn nnkan ti wọn ni ko ṣe ki owo naa le jade.

Bi ijọba Oyo ṣe na N30bn ti ijọba apapọ fi ranṣẹ lori ibugbamu Bodija

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oladamọran gomina sọ pe Makinde ṣe ikede fun gbogbo eeyan lori owo iranwọ to rigba lati ọdọ ijọba apapọ ati bo ti gbe igbimọ kan dide lati ṣakoso lilo owo naa.

Ọgbẹni Olanrewaju ni igbimọ ọhun ko fi nnkankan pamọ lori bi wọn ṣe lo N30bn owo iranwọ naa fawọn eeyan ti isẹlẹ ibugbamu ọhun ṣakoba fun.

O ni ijọba tun lo lara owo naa lati tun awọn ile kan kọ nibi ti ibugbamu naa ti ṣẹlẹ.

Ọgbẹni Olanrewaju fikun ọrọ rẹ pe ijọba ti ṣe atunṣe ọna ti ibugbamu naa bajẹ.

O ni ijọba tun n gbero lati kọ odi sibi ti ibugbamu naa ti ṣẹlẹ fun iranti awọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Olanrewaju tun sọ ninu atẹjade to fi sita pe N4.5bn ti ọpọ eeyan maa n sọ nipa rẹ jẹ diẹ lara owo ti ijọba san fawọn onile, awọn ayalegbe atawọn to farapa nibi iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi owo iranwọ.

O ni Makinde ri wi pe ijọba sanwo iranwọ fawọn ti iṣẹlẹ naa ṣakoba fun, bakan naa lo ni ijọba ti tun n ṣe atunkọ awọn ile kan ti ibugbamu naa bajẹ ni Bodija.

Oludamọran gomina ipinlẹ Oyo lori eto iroyin sọ pe gbogbo ẹsun ti Fayose fi kan Makinde ko ṣẹyin ọrọ ti gomina sọ laipẹ yii pe oun ko ni ṣatilẹyin fun Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2027.

Ọgbẹni Olanrewaju sọ pe ọrọ naa lọwọ oṣelu ninu.

Tinubu fún Makinde ní N50bn owó ìrànwọ́ lásìkò ìbúgbàmù Bodija - Fayose

Ṣaaju ni Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayo Fayose, ti sọ pe Gomina Seyi Makinde gba iranwọ aadọta biliọnu naira (N50bn) lati ọwọ Aarẹ Bola Tinubu lasiko iṣẹlẹ ibugbamu to wo ọpọ ile lulẹ lagbegbe Bodija niluu Ibadan.

Fayose sọrọ yii lori eto kan to waye nileeṣẹ tẹlifisan TVC niluu Eko.

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ ni loootọ ni Tinubu ko fun Makinde lanfaani lati fa eeyan kalẹ fun ipo minisita, amọ, o ni gomina ipinlẹ Oyo ri awọn anfaani miran jẹ lati ọdọ Tinubu.

''Nnkan ti Makinde sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe ni pe Tinubu ni koun lọ ṣagbatẹru ifẹsẹmulẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo, ṣugbọn oun kọ.

Amọ, Makinde ko sọ fawọn eeyan pe aarẹ foun ni N50bn nigba ti iṣẹlẹ ibugbamu to waye ni Bodija sọ ọpọ araalu di alainilelori n'Ibadan.

Mo ni ẹri to daju fun nnkan ti mo n sọ yii, to ba si jẹ pe iro ni mo n pa, mo fẹ ki Makinde wa sọ fun araye.

Nitori naa, bi Makinde ṣe n bu ẹnu ẹtẹ lu aarẹ ati ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣelu PDP, bakan naa lo yẹ ko maa ṣalaye fun awọn eeyan ipinlẹ Oyo awọn iranwọ ati anfaani to n ri gba.''

Fayose ni nnkan to n fa faakaja laarin Makinde ati Nyesom Wike ati oun naa ni erongba Makinde lati dupo aarẹ Naijiria.

Gomina ipinlẹ Ekiti fikun ọrọ rẹ pe oun ti beere lọwọ Makinde nipa awọn to n pin iwe ilewọ kiri fun ipolongo ibo aarẹ fun un.

O ni idahun Makinde ni pe irọ nla ni ọrọ naa wi pe owo lawọn eeyan ọhun n wa.

Fayose ni gbogbo laaṣigbo to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ osẹlu PDP ko ṣẹyin erongba Makinde lati dupo aarẹ.