Àwọn jàǹdùkú kọlu àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn nítorí ìjínigbé nílé ìjọba Kwara

Oríṣun àwòrán, Kwara updates
Ikọlu kan waye lọjọ Aiku ọsẹ yii, si awọn eeyan to n fi ẹhonu wọn han sijọba ipinlẹ Kwara.
Gẹgẹ bí ẹni ti ọrọ naa soju rẹ ṣe ṣalaye fun BBC, iyẹn Ọgbẹni Ganiyu, o ni ile ijọba ipinlẹ Kwara gan-an ni wọn ti kọlu awọn olufẹhonu han naa.
Ọkan lara awọn obinrin to n fẹhonu han ọhun, Arabinrin Fatimọh, ṣalaye pe awọn fi ẹhonu han lori iṣẹlẹ ijinigbe to n waye nijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara.
O fi kun un pe awọn wa lati ilu Adanla, Babanla, Ṣagbẹ, Oreke ati Agbeku ti gbogbo wọn wa nijọba ibilẹ Ifẹlodun.
Fatimo sọ pe ifẹhonuhan alaafia lawọn se lọ sile ijọba Kwara, lori eto aabo ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ati bi awọn ajinigbe se n ji eeyan gbe lagbegbe naa, ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ.
"Bi a ṣe de iwaju ile ijọba ni awọn janduku kọlu wa, wọn bẹrẹ si i na wa lẹgba''
Arabinrin Fatimo ṣalaye pe bi awọn se de iwaju ile ijọba n'Ilọrin ni awọn janduku kọlu awọn, ti wọn si bẹrẹ si i lu awọn lẹgba.
O juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bí eyi ti ko ba ofin mu rara.
Obinrin naa ṣo pe awọn ko ba ijọba ja, ẹtọ awọn lawọn beere fun, ko too di ohun ti wọn n na awọn lẹgba.
Ẹwẹ, Agbẹnusọ Gomina ipinle Kwara, Rafiu Ajakaye, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Ajakaye sọ pe Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazak, bu ẹnu ate lu iṣẹlẹ naa.
O ni Gomina ti kesi ajọ ọlọpaa lati sewadii ọrọ naa, ki wọn si mu awọn to wa nidii ikọlu ọhun.
Ninu atẹjade to fi ṣalaye iṣẹlẹ yii, ni Gomina Abdulrahman Abdulrazak ti ni araalu lẹ́tọ̀ọ́ láti fẹhonu han, ko si yẹ ki ẹnikẹni kọlu wọn.
Ijọba ipinlẹ Kwara ni awọn kò mọ nnkan kan nipa ikọlu naa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi Toun, ko sọ nnkan kan lori iṣẹlẹ yii nigba ti a kan si i.














