Wọ́n lu adarí eré lálùkì, já a síhòhò níta gbangba, ìdí rèé

Oríṣun àwòrán, Radio Nigeria HQ
Ana ode yii ti i ṣe ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kejila ọdun 2025 ki i ṣe ọjọ ire fun gbajugbaja adari ere kan ti orukọ rẹ n jẹ Don Pedro Obaseki.
Don Pedro Obaseki jẹ aburo fun gomina ipinlẹ Edo tẹlẹ, Godwin Obaseki,ṣugbọn eyi ko nitumọ kankan loju awọn to lu u lalubami nita gbangba.
Awọn to lu u naa fi lilu da bira si i lara tan, wọn tun ja a sihoho ki wọn too mu un lọ si aafin ọba ilu Benin, nipinlẹ Edo.
Ninu fidio kan to n ja ranin lori ayelujara, ile ẹkọ alakọọbẹrẹ Uwa, to wa niluu Benin, ni wọn ti fi lilu da bira si aburo gomina tẹlẹ naa lara.
Iya to jẹ ẹ naa bẹrẹ lori ipapa iṣere to wa nibẹ, lasiko to n gba bọọlu lọwọ pẹlu awọn kan.
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Don Pedro to ti gba oye PHD, to jẹ agba ọjẹ ninu didari ere, itan kikọ to si tun ti di agbẹjọro, jẹ ẹnikan ti ọpọ eeyan to mọ ọn maa n bọwọ fun un.
Ṣugbọn lọjọ Aiku, awọn kan ti wọn ni tọọgi ni wọn, ya a bo o, wọn si ni ọta ọba Benin ni.
Bi wọn ti bo o naa ni wọn ja a sihoho, ti wọn si n lu u ki wọn too wọ ọ de ẹnu abawọle aafin ọba Benin, nibi ti wọn ti da a kunlẹ.
Niwaju aafin ọba naa ni wọn ti sọ fun awọn ẹṣọ aafin naa lede Edo, pe awọn ti mu 'Oghion', eyi to tumọ si ọta ọba.
Iroyin sọ pe ọkan lara awọn oloye ọba naa sọ fun wọn pe Kabiyesi ko tiẹ raye bayii, nitori ọba n lọ sibi isin idupẹ lati sami opin ọdun Igue ti wọn maa n ṣe.
O sọ fun wọn pe awọn ko fẹ wahala, bi ẹnikẹni ba pe ara rẹ ni ọta ọba, ki wọn jẹ ko maa wi bẹẹ lọ, yoo pada ri ohun ti yoo ṣẹlẹ si i.
Ki ni Don Pedro Obaseki ṣe gan-an?

Oríṣun àwòrán, Don Pedro Obaseki
Gẹgẹ bi Don Pedro Obaseki funra rẹ ṣe ṣalaye, kete lẹyin to bọ lọwọ awọn to lu u, o ni :
"Nigba ti mo n gba bọọlu pẹlu awọn ẹgbẹ mi nile ẹkọ alakọọbẹrẹ Uwa, ni Benin, awọn kan kọlu ibẹ, wọn si ji mi gbe.
" Wọn ji mi gbe ni.
"Awọn kan ninu wọn mu ibọn dani, awọn kan jẹ janduku ti gbogbo eeyan mọ, o si tun waa daa pe mo mọ orukọ wọn.
"Wọn bẹrẹ si i wọ mi kiri awọn opopona ni Benin, wọn ni aafin ọba Benin ni wọn ti paṣẹ pe kawọn ji mi gbe.
"Mo bẹ wọn pe ki wọn fi ami idanimọ han mi, ṣugbọn wọn wọ mi, wọn lu mi, wọn ṣe mi baṣubaṣu gbogbo adugbo titi de Ring Road, nibi ti wọn ti ja mi sihoho, ti wọn si mu mi lọ si aafin."
Don Pedro ni oun ko ṣe ẹsin iru eyi ri, wọn da oun kunlẹ loju taye, bẹẹ ọmọ ibilẹ loun naa, amọ wọn yẹyẹ oun nigboro.
"Mo si gbọ pe ẹṣẹ ti mo ṣe naa ni pe nigba ti mo lọ si London, mo sọ pe kawọn eeyan Edo pẹ, wọn ni ohun to yẹ ki n sọ ni pe ki ọba pẹ ko si ṣe oriire."
Aburo gomina Edo tẹlẹ naa sọ pe wọn ni ẹṣẹ nla loun ṣe, nigba toun ki I ṣe ajeji ilẹ Benin, ti oun mọ ilana ikini, ṣugbọn ti oun sọ nnkan miran.
Wọn pada fi I silẹ, wọn si mu un lọ si agọ ọlọpaa kan, ki kọmiṣanna too paṣẹ pe ki wọn yọnda rẹ.
Ọpọ eeyan lo ti n koro oju si ohun to ṣẹlẹ si Don Pedro Obaseki yii, koda, ẹgbọn rẹ, Godwin Obaseki, ti koro oju si i pẹlu.
O ni oun ka iwa ti wọn hu si aburo oun si ifiyajẹni lọna aitọ.
Ta a ni Don Pedro Obaseki?
Ọmọwe to gboye Phd ni Don Pedro Obaseki.
Ipele aṣeyọri to daa ju ni yunifasiti (First class) lo gbe jade ni yunifasiti Benin. Ẹni ọdun mọkandinlogun (19) lo wa nigba yẹn.
Ọdun mọkanlelogun (21) ni Don Pedro wa nigba to di olukọ ni yunifasiti, nigba to si pe ọdun mẹrindinlọgbọn (26) lo gboye ọmọwe (Phd).
Olootu ere ni, olukọtan ni, akọroyin to lorukọ ni pẹlu. O ti figba kan jẹ ọga agba nileeṣẹ agbohunsafẹ AIT, o si tun ti di agbẹjọro pẹlu.














