Àwọn agbésùnmọ̀mí tó sá láti ìpínlẹ̀ Sokoto lẹ́yìn ìkọlù America kó sọ́wọ́ Àmọtẹ́kùn l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ondo
Lẹyin ikọlu ti ile America ṣe si awọn agbesunmọmi nipinlẹ Sokoto, ikọ alaabo Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti fi panpe ọba mu awọn afurasi mokandinlogooji
Ikọ Amọtẹkun Ondo sọ pe lara awọn agbesunmomi ipinlẹ Sokoto ti wọn sa wa si igbo ọba ipinlẹ Ondo ni awọn eeyan yii.
Bakan naa ni wọn tun mu afurasi mokanlelọgọta (61) miran fun ẹsun ijinigbe, idigunjale ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọga agba ikọ Amọtẹkun Ondo, Akogun Adetunji Adeleye, sọ eyi di mimọ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nillu Akure.
O ni afurasi ọgọrun-un ni awọn fi panpe ọba mu jakejado ipinle Ondo.
Adeleye salaye pe agbegbe Elegbeka ni awon ti mu awọn afurasi agbesunmomi naa, eyi to wa nijọba ibilẹ Ose.
O fi kun un pe awọn n se ayẹwo finni-finni fun wọn lọwọ lati mọ iru ijiya ti wọn yoo koju ni ibamu pẹlu ofin.
Ọga agba Amọtẹkun náà salaye pe agbegbe Elegbeka yii jẹ oriko to buru jai nipinlẹ Ondo, latari awọn iwa ibi to maa n waye nibẹ.
Awọn iwa bii idigunjale, ijinigbe ati ipaniyan ni Adeleye sọ pe o kun Elegbeka.
O ni idi si niyẹn tawọn fi gbe oriko kan kalẹ ni agbegbe naa, ki awọn olugbe agbegbe ibẹ le maa gbe ni alaafia.
Àwọn afurasi naa jẹwọ

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ondo
Akọgun Adeleye,Olori Amọtẹkun Ondo, tẹsiwaju pe awọn afurasi agbesunmọmi naa jẹwọ ẹṣẹ wọn.
O ni ọjọ ori wọn wa laarin ogun ọdun si ogoji ọdun.
Bakan naa lo ni awọn afurasi yii jẹwọ pe oniruuru ikọlu ni awọn ti ṣe si apa Ariwa orileede yii.
Eyi ni wọn lo jẹ kawọn sa kuro nibuba lati Ariwa, lẹyin ti ilẹ America kọlu ipinlẹ Sokoto loru ọdun Keresimesi.
Wọn ni awọn sa wa si igbo ọba Ondo fun aabo ẹmi awọn, gẹgẹ bi ọga Amọtẹkun ṣe fidi ẹ mulẹ.
Oga agba Amotekun naa sọ pe eeyan ko kan le sa wa sigbo ọba lai gba aṣẹ lọwọ ijọba ilu.
O kilọ pe enikeni ti ọwọ ba tẹ ninu awọn igbo ọba ipinlẹ Ondo lai gba aṣẹ yoo foju wina ofin.
O wa rọ awọn ara ilu lati fi iroyin ohun to bá ń ṣẹlẹ ni ayika wọn to Amọtẹkun leti, pẹlu ileri pe Amọtẹkun yoo dide si i.
Bakan naa lo ni awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu gbogbo ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba, lati ri I daju pe awọn agbesunmomi to n sa kuro ni Ariwa orilẹede yii ko ri aaye lati sa si tabi ṣọṣẹ ni gbogbo ilẹ kaaro-oo- jiire.














