NNPC pàṣẹ fáwọn òǹtàjà epo pé owó epo bẹntiróòlù kò gbọdọ̀ lé ní N145

Awọn eeyan to n du epo pẹtrolu ra lasiko ọwọn epo

Oríṣun àwòrán, @Bolarinwaiyanu

Ileeṣẹ epo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC ti kede pe, oun ko ni erongba lati fi owo kun owo ori epo lorilẹede Naijiria.

Ninu atẹjade kan to fi sita nilu Abuja, ajọ NNPC rọ awọn onimọto lati maṣe tẹti si ahesọ kan to n lọ kaakiri pe ajọ NNPC n gbero ati fi kun owo epo.

Ajọ naa ni, oludari agba NNPC, Mallam Mele Kyari fara han niwaju ile igbimọ́ asofin apapọ Naijiria lọjọ iṣẹgun, ko si sọ ohunkohun nibẹ to lee tọka si pe, afikun fẹ de ba owo epo bẹntiroolu.

Agbẹnusọ fun ajọ NNPC, Ndu Ughamadu ṣalaye pe, lootọ̀ ni oludari agba ajọ NNPC lọ sọdọ aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnatọ Ahmad Lawan.

O ni lasiko ipade wọn, ohun ti wọn jiroro le lori ni pe akoso owo ori epo lorilẹede Naijiria buru pupọ, ta ba gbe yẹwo si tawọn orilẹede yoku lẹkun iwọ oorun Afirika.

Aa ile asofin agba ati olori ajọ NNPC

Oríṣun àwòrán, @NNPCgroup

O ni eleyi lo n fi aye silẹ fun awọn ti o n ṣe fayawọ epo lati maa tẹsiwaju ninu iwa ibajẹ wọn atipe, atilẹyin ile aṣofin apapọ ni ajọ NNPC n wa lati dẹkun iwa fayawọ epo rọbi naa.

Ajọ NNPC wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ọkan wọn balẹ o nitori ko si ohun to jọ fifowo kun epo bayii.

O ni gẹgẹ bii aṣẹ to wa lati ọdọ awọn ajọ to n mojuto owo ori epo, naira marundinlaadọjọ ṣi ni iye owo bẹntiroolu, ti ko si yi pada.

O wa kii nilọ fawọn ileeṣẹ to n ta epo, lati maṣe yi owo kuro ni naira marundinlaadọjọ lori lita epo pẹtiro kan.

Àkọlé fídíò, 'Àwa táa jẹ́ alágbàtọ̀ gan, èèyàn ni wá, ẹ ye ṣe wa bí ẹranko'