Olateru-Olagbegi II: Ìtàn ayé Ọba Olateru-Olagbegi Kejì, àkàndá ẹ̀dá tí kò ṣe fi ara wé

Olagbegi

Oríṣun àwòrán, @Omoola.yoruba/Facebook

Yoruba ni ori ti yoo de adé, kò ní ṣalai dade, ọrun tí yóò sì wọ ejigbara ilẹkẹ, kò ní ṣe aláì wọ ọ, bẹ́ẹ̀ ni ibadi tí yóò lo mọsaaji, aṣọ ọba tó jinna koro koro, kò kúkú ní ṣe aláì lo o.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ìgbé ayé ọba Ọlọ́lá James Titus Olateru-Olagbegi kejì, Ọlọwọ tilu Ọwọ tó ti di olóògbé.

O si ṣe pàtàkì ká fi igbe ayé aramọnda ọba yìí kọ ara wa ni ẹkọ, kò leè ye wa pé, ayanmọ ni kadara, ayé sì leè lè fa ọwọ aago sẹ́yìn ni, wọn kò leè pa kadara da.

Gẹ́gẹ́ bàa tí ká a ni ojú òpó itakun agbaye Wikipedia, ọba Olateru-Olagbegi keji jẹ́ akanda ẹ̀dá, ẹni tí Ọlọ́run ṣa ní ẹsa, èyí tí kò ṣe fi ara we, bí ìtàn ìgbé ayé rẹ sì ṣe lọ rèé.

Ìtàn ayé Ọba James Titus Olateru-Olagbegi keji:

Oṣù Kẹjọ ọdún 1910 ni James Titus délé ayé, bàbà rẹ Olateru-Olagbegi Kínní, náà sì jẹ ọba Ọlọwọ tilu Ọwọ, to wá ní ẹba ìlú Àkúré nipinlẹ Ondo

A gbọ pé nígbà tí wọn bi Titus, wọn difa láti mọ akọsẹdaye rẹ, gẹgẹ bo se wọ́pọ̀ nígbà náà, tí ifá sì ni yóò jẹ ọba gẹ́gẹ́ bíi bàbá rẹ̀

Àkọlé fídíò, Wo àwọn nǹkan mẹ́rin tó yẹ kó wà nínú báàgì rẹ lásìkò Covid-19 yìí

Ifa tún ní ọmọ tuntun náà yóò jọba fún ọdún mẹẹdọgbọn, yóò sì ní ipenija lórí ìtẹ́, tí wọn yóò sì lé kúrò bíi ọba fún ọdún mẹẹdọgbọn, àmọ́ yóò sì padà wa jẹ ọba fún ọdún mẹẹdọgbọn mii, kò tó jáde láyé, Ayanmọ ńlá.

Gẹ́gẹ́ bíi ohun tí ifá sọ, Titus de ipò àwọn baba ńlá rẹ lóòótọ́, tó sì di ọba James Titus Olateru-Olagbegi Kejì, Ọlọwọ tilu Ọwọ ni ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹta ọ́dún 1941.

James Titus jẹ ọba fún ọdún mẹẹdọgbọn, ayé roju, ìlú toro, tí gbogbo ìlú Ọwọ sì tuba tusẹ. Lọ́dún 1951 sì lo lewaju idasilẹ ilé ẹ̀kọ́ gírámà Imade College.

Olateru-Olagbegi

Oríṣun àwòrán, @Oddy4real

Àkọlé àwòrán, Ọba Olateru-Olagbegi kejì àti Oloye Obafemi Awolowo lọ́dún 1952

Kò tán síbẹ̀, ọba James Titus Olateru-Olagbegi kejì tún lakaka láti mú ayé dẹrun fáwọn èèyàn rẹ, tó sì rí dájú pé, ìlú Ọwọ ni omi ẹ̀rọ, iná ọba, ọ̀pọ̀ ilé ifowopamọ, ibùdó ìgbafẹ́, ilé ìwòsàn, gbọ̀ngàn ìlú, ilé ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ àti gírámà lorisirisi.

Owo oṣù Ọba Olagbegi nígbà náà jẹ ẹgbẹ̀rún kan àti pọn-un mẹrindinlọgọfa (£1,116) fún ọ́dún kan, èyí tí ọba náà kò gbé gbogbo ara le rárá, àmọ́ ó mú isẹ ọ̀gbìn nibaada, tó sì ṣe ọ̀gbìn koko, kọfi ati ọpẹ lọpọ yanturu, èyí tó fi ń tọju ẹbi àti ìlú rẹ.

Àmọ́ lai naani àṣeyọrí ọba yìí, ìgbà yípadà, wàhálà de, gbẹgẹdẹ gbiná, ruke rudo wọlu, èyí tó yọ ọba Olateru-Olagbegi kejì nípò ni ọdún 1966, lẹ́yìn ọdún kẹẹdọgbọn to jọba, aṣọtẹlẹ àkọ́kọ́ tí ifá sọ ṣáájú, si wá si ìmúṣẹ.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò sì sẹ́yìn bí ọba alaye náà ṣe lọ́wọ́ nínú ètò òṣèlú.

Ní kúkúrú, bí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun sì ṣe wáyé rèé

Nígbà tí eto ìṣèlú bẹ̀rẹ̀ ni ẹkún ìwọ oòrùn gúúsù Nàìjíríà ijọun lọ́dún 1951, tí wọn sì dá ẹgbẹ́ oselu Ọlọpẹ, Action Group (AG) silẹ, ọba James Titus Olateru-Olagbegi Kejì lọ́wọ́ nínú oselu, koda, inú ààfin rẹ ni wọn ti dá ẹ̀ka ẹgbẹ́ òṣèlú Ọlọpẹ ni ilu Ọwọ silẹ.

Oloye Obafemi Awolowo àti Samuel Ladoke Akintola sì ni wọ́n jẹ aṣáájú ẹgbẹ́ òṣèlú náà àmọ́ nígbà tó di ọdún 1962, ìjà de láàrin àwọn aṣáájú méjèèjì yìí,

Ija yí tó pín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Ọlọpẹ si méjì, àwọn kan to sẹ́yìn Awolowo nígbà tí àwọn míràn tó sẹ́yìn Akintola.

Àkọlé fídíò, Contortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún se èémí!

Ọrẹ kori-kosun, iyekan, àti alabarìn tòótọ́ si ọba Olateru-Olagbegi ni Oloye Michael Adekunle Ajasin, tí òun náà jẹ èèkàn nínú ẹgbẹ́ Ọlọpẹ n'ilu Ọwọ, àwọn méjèèjì si ni wọn dijọ ń ṣíṣẹ fún idagbasoke ìlú naa.

Àmọ́ nígbà tí aawọ de láàrin Awolowo àti Akintola, Ọba Olagbegi pọn sẹ́yìn Akintola, tí Ajasin sì pọn lẹ́yìn Awolowo, èyí tó mú kí ọrẹ méjì kọ ẹyin síra wọn, tí wọn si di ọ̀tá gidigidi.

Aawọ àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ méjèèjì yii si wa lara àwọn ohun tó fa rògbòdìyàn àti rukerudo ni ẹkun ìwọ oòrùn gúúsù Nàìjíríà ijọun, èyí tí wọn pe ni 'Wẹtiẹ', nínú èyí tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ti bọ, tí ọ̀pọ̀ dúkìá bajẹ, tí ẹkùn náà kò sì fararọ.

Àkọlé fídíò, Sogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Rògbòdìyàn yìí náà tún wa lára ohun tó mú kí àwọn ológun gba ìjọba Nàìjíríà lọ́dún 1966, tí wọn sì gba ẹ̀mí oloye Samuel Ladoke Akintola, bẹ́ẹ̀ si ni Oloye Obafemi Awolowo wa ni ọgbà ẹ̀wọ̀n lásìkò náà.

Ọ̀pọ̀ ọmọ bibi ìlú Ọwọ lo jẹ olólùfẹ́ Awolowo àti Adekunle Ajasin, bí ológun si se gba ìjọba tún ṣe iwuri fún làásìgbò láti fọn iná sójú n'ilu Ọwọ,

Won si gbógun ńlá ti Ọba James Titus Olateru-Olagbegi kejì, èyí sì lo mú kí ìjọba ológun, lábẹ́ Adekunle Fajuyi, tó ń darí ìjọba ẹkùn ìwọ oòrùn Naijiria nígbà náà, yọ ọba Olateru-Olagbegi kejì lórí ìtẹ́ ni oṣù kẹfà, ọdún 1966.

Olateru-Olagbegi

Oríṣun àwòrán, @ATIKULATE_2019

Àkọlé àwòrán, Ọbabìnrin Elizabeth Kejì ń bọ̀ Ọba Olateru-Olagbegi kejì lọ́wọ́ lọ́dún 1960

Oṣù kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ní igun ológun míràn ditẹ gba ìjọba ni Naijiria, tí wọn si rán Adekunle Fajuyi sajule ọrun ni ọjọ́ kọkandínlọgbọn, oṣù keje ọdún 1966 yìí kan náà, tí ìjọba ológun Yakubu Gowon sì gba àkóso.

Ọgagun Adeyinka Adebayo sì ni wọn yàn pé ko gba ipò Fajuyi, tó sì gbé ẹsẹ kúrò lórí òfin tó yọ ọba Olateru-Olagbegi kejì lórí ìtẹ́, àmọ́ eto ààbò ìlú Ọwọ kò tíì fararọ nígbà náà, eyi to mu kí ojú ọjọ́ má dáa fún ọba Olagbegi láti padà sí ààfin rẹ n'ilu Ọwọ.

Nígbà tó di ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kejì ọdún 1968, ọba Olagbegi gbìdánwò láti padà sí ààfin rẹ, tó sì gbéra láti ìlú Ibadan pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ rẹ kan àmọ́ àwọn ọ̀tá rẹ nínú ìlú náà tún dìde ogún sii, ìjà igboro míì tún bẹ silẹ, ni àwọn ọlọ́pàá ba sin-in padà silu Ibadan.

Lásìkò tí rògbòdìyàn lorisirisi ń wáyé sì ọba Olagbegi, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àwọn èèyàn tó sunmọ lo ṣòfò, tí wọ́n sì jó àwọn dúkìá wọn nínà pẹ̀lú.

Lára àwọn dúkìá olówó iyebíye ọba alaye náà tó ṣòfò sínú làásìgbò ni ile alaja kan tó wà ní òpópónà Oludasa nilu Ọwọ èyí tí owó rẹ tó ẹgbẹ̀rún mẹta pọn-un, àwọn ohun èlò ara fún ọba alaye náà, towo wọn tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé díẹ̀ pọn-un.

Àkọlé fídíò, Itan Omi Erin

Bákan náà, dúkìá àwọn Olorì mẹẹdogun tó ní àti onírúurú dúkìá mẹ́wàá miran tó bajẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún pọn-un, ilé alaja méjì tó wà ládùúgbò Imalefẹalafia n'ilu Ibadan towo rẹ to ẹgbẹ̀rún mẹta àti àbọ̀ pọn-un, ọkọ Land Rovers méjì towo wọn to tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin pọn-un, tó fi mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá míì lorisirisi tí a kò leè kọ silẹ.

Lapapọ, a ri ká pé àwọn dúkìá tí ọba Olagbegi pàdánù sínú rukerudo náà lè ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún pọn-un (£100,000) láyé ìgbà náà.

Akọtun rògbòdìyàn náà sì lo mu kí Ọgagun Adeyinka Adebayo gbé igbimọ kan dìde láti ṣèwádìí ohun tó ń ṣe idiwọ fún ípadabọ ọba alaye náà si ori ìtẹ́.

Amọ́, lẹ́yìn ìwádìí náà ni Ọgagun Adebayo bá kéde pé òun tún rọ ọba Olateru-Olagbegi Kejì lóye, tó sì le lọ silu Òkìtìpupa.

Ní ọjọ́ kẹrindinlogun, oṣù kejì, ọdún 1968, wọn gbé ọba Olagbegi lọ sílè igbalejo kan n'ilu Òkìtìpupa, níbi tó ti lo ọdún kan àti oṣù kan, tó sì kúrò n'ilu Òkìtìpupa lọ́jọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹta ọdún 1969.

Ọba Adekola Ogunoye jọba lẹ́yìn Olagbegi, tó sì waja losu kọkànlá ọdún 1992, o si jọba fún ọdún mẹẹdọgbọn gbáko.

Ní gbogbo ọdún mẹẹdọgbọn náà, ọba Olagbegi jà fitafita láti padà sórí ìtẹ́, ó lọ sílè ẹjọ́, ó kọ̀wé ẹ̀sùn lorisirisi, tó sì yọjú síwájú igbimọ oluwadii ni àìmọye ìgbà, àmọ́ síbẹ̀-síbẹ̀, pàbó ni gbogbo aayan rẹ ọhun jásí.

Gomina Bamidele Olumilua lo wa lori òye nígbà tí ìtẹ́ Ọlọwọ ṣófo, tó sì la ọ̀nà fún Ọba James Titus Olateru-Olagbegi kejì láti padà sí orí ìtẹ́ àwọn baba ńlá rẹ lọ́dún 1993, lẹ́yìn ọdún kẹẹdọgbọn tí wọn tí yọ kúrò lórí ìtẹ́, àsọtẹ́lẹ̀ ifa kejì sì sẹ nípa ọba alaye náà.

Olateru-Olagbegi

Oríṣun àwòrán, @D_Aruwajoye

Àkọlé àwòrán, Ọba Adesoji Aderemi pelu Ọba Olateru-Olagbegi kejì n'ilu London lọ́dún 1953

Ọba alaye yìí, akanda Olódùmarè padà lo ọdún márùn-ún lórí ìtẹ́ lẹ́yìn tó padà dé orí òye lẹẹkeji,

Kò tó dara pọ mọ àwọn baba ńlá rẹ ni ọdún 1998, tí kò sì jẹ ki àsọtẹ́lẹ̀ ifa kẹta sẹ, àmọ́ ọmọ rẹ, Victor Folagbade Olateru-Olagbegi Kẹta jọba lẹ́yìn rẹ.

Kò sì sí àní-àní pé ẹni tí Ọlọ́run dá, tí kò ṣe fi ara wé ni ọba Olateru-Olagbegi kejì, tí ìdílé rẹ si wa lara ìdílé tó tóbi ju to tun kàwé julọ n'ilu Ọwọ.

A ríi ka pé, ọba àlàyé náà ni ọpọlọpọ ìyàwó, táwọn ọmọ rẹ sì tó ogoje, tí mọkanlelọgọfa nínú wọn si jẹ akẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Fáṣítì.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Olateru-Olagbegi sì lo wa ni àwọn ẹ̀ka isẹ aayan láàyò loniran nran bíi ẹ̀ka eto ẹ̀kọ́, idajọ, àkóso owó, ilé ifowopamọ, imọ isegun àti bẹẹ bẹẹ lọ.

A sì leè ni ọba alaye náà jogún bá ọlá nílé ni nítorí bàbá rẹ̀ gan an, ọba Atanneye Olateru-Olagbegi Kínní, tó jẹ Ọlọwọ tilu Ọwọ láàárín ọdún 1913 sí 1933, náà ni ọpọlọpọ ọmọ àti ìyàwó bíi ọọdunrun, tí marun un nínú awọn aya rẹ náà, kò sì tíì mọ ọkùnrin nígbà tí ọba ọhun jáde láyé.

Ẹ̀kọ́ tí ìgbé ayé ọba Olateru-Olagbegi kejì kọ́ wa:

Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ tí a rí kọ́ láti ara ìtàn ìgbé ayé ọba alaye náà ni pé, àkọsílẹ̀ tí kò lórí ayé onikaluku. Ohun tí a jẹ́, á kúkú jẹ, ká sá máse kánjú.

Ẹ̀kọ́ kejì ni pé kò dáa tó kí ọba alaye lọ́wọ́ nínú òsèlú, àbùkù àti ẹṣin lo ń kó bá wọn.

Ẹ̀kọ́ kẹta ni pé rògbòdìyàn kò dára, ó leè gba ẹ̀mí alaiṣẹ̀, kò sì tún fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá ṣòfò, ẹ jẹ́ ká yàgò fún làásìgbò.

Ẹ̀kọ́ kẹrin ni pé kí àwọn ọrẹ méjì má ṣe torí ọ̀rọ̀ òṣèlú sọ ara wọn di ọ̀tá ayérayé. Kò sí ọ̀tá àbí ọ̀rẹ́ nínú òṣèlú.