NBA election 2020: Olumide Akpata di aàrẹ àjọ àwọn agbẹjọ́rò ní Nàìjíríà, Taiwo Taiwo, Ajibade àtàwọn míì kíi kú oríire

Oríṣun àwòrán, @hartng/others
Aarẹ ajọ awọn Amofin ni Naijiria, (NBA) ti paarọ ọwọ.
Ẹni ti ko tii gba oye imọ ijinlẹ ninu akọsẹmọsẹ ofin ni oye naa ja mọ lọwọ.
Orukọ e ni Ọgbẹni Olumide Akpata
Won se ikede yi ni nkan bi ago kan oru Ọjọbọ
Lati ọdọ Alaga awọn to n ri si eto idibo awon amofin, Ọgbeni Taiwo Taiwo (SAN).
Akpata gbe gba oroke pẹlu iwọn ida aadọta ninu ọgọrun un
Ọgbeni Babatunde Ajibade ni ẹni to tun tẹ le Ogbeni Akpata ninu eto idibo naa pẹlu ida mẹtalelogun ninu ọgọrun un

Oríṣun àwòrán, @hartng/others
Eeyan Ogoji ni ko kopa ninu eto idibo naa, ti isiro gbogbo oludibo si jẹ 16,519
29,636 ni akpapọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ ti o ko ipa ninu idibo naa.
Awon ipo to ku ti won dije fun ni igba keji aare akọkọ ati ẹkeji, akọwe apapọ ,igba keji akọwe, akapo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awon ti won jọ dije dupo ni Diakoni Dele Adesina (SAN) ati Omọwe Babatunde Ajibade (SAN).
Awọn miran ti wọn tun dije dupo mii ni: Ogbẹni John Martin fun ipo igbakeji akọkọ: Ogbẹni Adeyemo Kazeem fun igbakeji ẹkeji: Arabinrin Joyce Oduah, akọwe apapọ ati awọn mii
Mọ̀ diẹ sii nipa Olumide Akpata:
Akpata jẹ agbẹjọro to n soju awon oloko owo ati onisẹ aje.
O tun jẹ ẹni akọkọ ti ko gba oye imọ ijinlẹ ninu ofin ti yoo fi di akosemose (SAN) to dije dupo aarẹ to si wọle lati ọdun 1989 nigba ti oloogbe Alao Aka-Bashorun fi n dari gbogbo eto tẹlẹ.
Ajibade sọ ninu ọrọ rẹ pe: "Mo ti pe Olumide lati kii ku oriire gege bii Aare wa to jẹ́ ọgbọn iru aarẹ bee. ninu eto idibo to waye loojo kokandinlogbon si ogbon ọjọ, osu keje, ọdun 2020













