Church Reopening in Ogun: Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi dunnú bí sọ́ọ́sì ṣe di ṣíṣí padà

Church

Oríṣun àwòrán, RHCC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ọmọlẹyin Kristi ni ipinlẹ Ogun ti sọ pe, inu wọn dun lati jọsin ninu ṣọọṣi wọn lẹyin ti ijọba ipinlẹ naa ṣi awọn ile ijọsin pada.

Idunnu ati ayọ ni awọn Kristẹni naa fi n yin Ọlọrun ninu isin akọkọ ti wọn ṣe, lẹyin igbele Coronavirus.

Pupọ lara awọn olujọsin ọhun lo tẹle ofin ati awọn ilana ti ijọba gbe kalẹ, lọna ati dena itankalẹ ajakalẹ arun Cvoronavirus.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oludasilẹ ijọ Redeeming Hope Christian Centre, to wa ni Baale-Ajuwon, Abiodun Wright sọ fun BBC pe, "Inu wa dun pe ijọ ti di ṣiṣi pada lonii yii, ijọ wa si tẹle ilana ti ajọ eleto ilera gbe kalẹ."

Pasitọ naa ni "Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, igbagbọ wa ni pe Ọlọrun yoo daabo bo awọn eeyan rẹ, yoo si gbe ijọ ro."

Church

Oríṣun àwòrán, RHCC

Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ ijọ rẹ atawọn ọmọlẹyin Kristi lati maa ṣora, ki wọn maa gbadura, ki wọn si tun tẹle gbogbo amọran ati ilana eto ilera lọna ati dena itankalẹ arun Cpvid-19.

Lara awọn ọmọlẹyin Kristi miran to ba BBC sọrọ, Bode Alonge sọ pe "Inu awọn eeyan dun lati wa sile ijọsin o, o han loju wọn pe o wu wọn lati pada bẹrẹ si n jọsin ninu ṣọọṣi."

O ni gbogbo wọn lo wọ ibomu wa sile ijọsin, gbogbo wọn lo si fọ ọwọ wọn pẹlu omi ati ọṣẹ ki wọn to wọle sinu ile ijọsin naa.

Ẹwẹ, awọn kan to ba BBC sọrọ ni ilu Abeokuta, to jẹ olu ilu ipinlẹ Ogun, ṣugbọn ti wọn ko fẹ fi orukọ tabi orukọ ijọ wọn sita ni, ero ko gbẹsẹ nile ijọsin wọn.

Àkọlé fídíò, The Polytechnic Ibadan: Ẹ̀rọ abẹ́lé tó ń fọ ọwọ́ àti ‘Ventilator’ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde

Ọkan lara wọn sọ pe "Wọn ko jẹ ki a wọle si ṣọọṣi o, nitori a ti ju igba lọ, wọn si ti tilẹkun mọ wa."

Wọn ni awọn pasitọ ijọ wọn pin isin wọn si abala mẹta, ki gbogbo awọn to wa sile ijọsin naa le e kopa ninu isin ọhun nitori ero ti pọ ju.

Day Star, Synagogue àti àwọn ilé ìjọsin míràn ti wọ́n kọ̀ láti ṣi ilé ìjọsin lẹ́yin ti ìjọba dẹ okùn kóníléógbélé

Sam Adeyemi àti Daniel Olukoya ni adari ìjọ Daystar àti MFM

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Àwọn ilé ìjọsin ńla-ńla to ni olú ilé ìyá ìjọ wọn ni ilú Eko ti kéde pé àwọn kò tíì ṣetan láti ṣílẹ̀kun ilé ìjọsìn wọ́n lẹ́yìn ti gómìnà ìpínlẹ̀ Eko ti dẹ́wọ kóníléógbéle nitóri ààrùn Covid-19 nípìnlẹ̀ Eko

Láti inú oṣù kẹta ọdún ni ìjọba ti ti àwọn ilé ìjọsin pa láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ààrùn Covid-19

Láti inú oṣù kẹfa ọdún ni ìgbìmọ̀ amúṣẹṣe lóri ọ̀rọ̀ Covid-19 ti ààrẹ yàn ti ni kí àwọn ilé ìjọsin ṣí, sùgbọ́n, ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kò gba ètò yìí láàyè nítori bí ààrùn náà ṣe ń peléke síi nípìnlẹ̀ Eko.

Ẹ̀wẹ̀ ní báyìí ìjọba ìpińlẹ̀ Eko ti páa láṣẹ pé kí olúkúlùkù, mùsùlùmí àti Kristẹni pada sí ibi ìjọ́sìn wọn láti ọjọ́ kèje, oṣù kẹ̀jọ, ọdún 2020.

Àkọlé fídíò, Ohun tẹ́ẹ gbúdọ mọ nípa kókó orí ọyàn yín lásìkò fífọ́mọlọ́yàn

Sùgbọ́n o, àwọn ilé ìjọsin kan ti jáde pé, àwọn kò tíi ṣetán láti ṣí ilé ìjọsìn tàwọn.

Àwọn ilé ìjọsin náà ló ni onírúurú ìdí ti wọ́n kò fi ni ṣí ilé ìjọsin wọ́n, àwọn kan ni àwọn gbọdọ kọ́kọ́ ṣeto sílẹ̀ ni ìbámu pẹlú ìlàna ààbò ìjọba àpapọ̀ kí àwọn ará ìjọ to maa wá, àwọn kan bákan náà ni àwọn yóò dúro títí ti àwọn yóò fi gbọ́ láti ọdọ Ọlọ́run kí àwọn tó ṣílẹ̀kùn.

Wo àwọn ilé ìjọsin tí wan kọ̀ láti sílẹ̀kùn ilé ìjọsìn wọ́n lọ́ja kẹsàn oṣùn kẹjọ

MOUNTAIN OF FIRE AND MIRACLE MINISTRIES

Àwọn adarí ìjọ MFM sọ pé, àwọn ẹ̀ka ìjọ àwọn yálà ní ìpińlẹ̀ Eko, Ogun tàbi ní ibikíbi kò ní sílẹ̀kùn títí di ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kẹsán, ọdún yìí bá àwọn yóò ṣe máa ṣetò àwọn ǹkan ààbò nmi ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí ìjọba ìbílẹ̀ àti àjọ NCDC là sílẹ̀

DAYSTAR CHRISTIAN CENTRE

Bákan náà ni ìjọ ilúmọ̀ọ́ká Day Star, ti adari wọn jẹ́ olùsọàgùntan Sam Adeyemi náà ṣe ti sàlàyé pé àwọn yóò máa tẹ ìsìn síwájú lóri ayélujára.

Wọ́n ni èyí ko sì ni dáwọ́ dúro titi àrídájú yóò fi wà pé àyíka ilé ìjọsin ti dára láti maa pẹ́jọpọ̀ níbẹ̀.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

SYNAGOGUE CHURCH OF ALL NATIONS

Adarí ìjọ Synagogue náà kò gbẹ́yìn, ìyẹn olùṣọ́àgùntàn TB Joshua, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ fún akitiyan wọ́n láti dáàbò bo àwọn ará ilú kúrò lọ́wọ́ ààrùn náà.

Ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba fún ìkéde wọn pé kí àwọn ilé ìjọsìn tún ṣí ìlẹkùn wọ́n padà, sùgbọ́n síbẹ̀, ó ní òun yóò ni sùúrù láti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun náà kí àwọn tó ṣi ilé ìjọsìn.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

FOUNTAIN OF LIFE CHURCH

Ní ti ìjọ Fountain Life, wọ́n ti kọ síjú òpó twiktter wọ́n pé, àwọn yóò fi àsìkò tí ilé ìjọsìn àwọn yóò sílẹ̀kùn síta ti àsìkò bá tó, nmítori náà, ìjọ yóò máa tẹ̀síwájú lórí ayélujára

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3