Coronavirus Update: Iná jó àwọn ènìyàn 10 tó ń gbà ìwòsàn àrùn Coronavirus ní Isolation Center

Oríṣun àwòrán, Others
Eniyan mẹwa lo ti ku ninu ina to sọ ni ile itura ti wọn n lo lati fi tọju awọn to ni arun Coronavirus lorilẹ-ede India.
Ni owurọ Ọjọ Isinmi, ni agbegbe Andhra Pradesh ni Vijayawada ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Ni oju opo ikansiraẹni Twitter ni Olotu Ijọba orilẹ-ede India, Narendra Modi ni o ti fi ọrọ naa lede, ti awọn si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
- Oluwatoyin Olanipekun: Wo àwọn òyìnbó tó ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ní Michigan, America
- Iná sọ nínú ilé Big Brother tó ń lọ lọ́wọ́ ní Cameroon
- Ta ló ń lọ sílé lónìí nílé ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà?
- Àwọn adarí lágbàyé ṣèpàdé láti ṣèrànwọ́ fún Lebanon lẹ́yìn ìbúgbàmù tó pa ènìyàn 158
- Afárá Third mainland gba ẹ̀gbọ́n
Bakan naa ni Modi ba awọn to padanu eniyan wọn kẹdun, to si gbadura iwosan pipe fun awọn ti wọn wa ni ileewosan lọwọ nitori iṣẹlẹ naa.
Wọn ni o kere tan, eniyan meje lo paya ti wọn si fo bọ silẹ nigba ti ina naa bẹrẹ si ni jọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn mejeeje to fo bọ silẹ naa lo ku, ti ooru ina si tun pa eniyan meji nigba ti eefin ina rubo ile itura ọhun.
Ohun ti o fa ina naa ni ẹrọ amuletutu to bajẹ, ti ina si sọ nibẹ.
Ijọba fikun un pe awọn to ye ninu ina naa ti wa ni ile iwosan miran lati tẹsiwaju iwosan wọn ni ile iyasọtọ miran.














