Ramadan: Kí ni Buhari, Saraki, àtàwọn gómìnà kan sọ?

Buhari ni mọṣalasi ile aarẹ nilu Abuja

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Buhari, Saraki, Dogara àtàwọn gómìnà kan tí ránṣẹ́ ìkíni kú ọdún sí àwọn mùsùlùmí

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi da awọn ọmọ orilẹede Naijiria loju pe opin ko ni pẹ de si iwa ijinigbe, igbesunmọmi atawọn iwa miran to n tigi boju alaafia lorilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ ikini ku ọdun Eid-el-Fitir rẹ to fi ransẹ si awọn musulumi lo ti kede eyi. Aarẹ Buhari ni gbogbo ipa to ba yẹ ni ijọba oun yoo sa lati rii pe wọn dẹkun wahala igbesumọmi ati ijinigbe gbogbo to n waye lorilẹede Naijiria ati pe gbogbo awọn to ba wa ni idi ibajẹ ni wọn yoo lọ si i.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun fifi ile, ọna ati okoowo wọn silẹ lati jade dibo lasiko idibo apapọ to waye ṣaaju lọdun yii, lai naani ohun to pe ni ọrọ alufansa to ni awọn eeyan kan ṣaaju ọdun yii lori ohun ti yoo ti ẹyin idibo naa jade pe ko ni rọgbọ.

O ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria, paapaa julọ, awọn musulumi ni ọpọ ẹkọ lati kọ lara Ramadan eleyi to ni o wa lati 'ro awọn eeyan lagbara nipa ti ẹmi. Awọn amuyẹ Ramadan gbọdọ wa pẹlu wa kọja asiko wẹjẹwẹmu yii lọ."

Saraki: Adura fun orilẹede Naijiria gbọdọ tẹ siwaju

Bukọla Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Àkọlé àwòrán, Adura fun orilẹede Naijiria gbọdọ tẹ siwaju

Ninu ọrọ tirẹ, aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki rọ awọn musulumi lati ma ṣe rẹyin ninu iwa ikoraẹni nijanu, ati ifẹ ọmọnikeji wọn.

"A ko gbọdọ rẹyin ninu adura fun iṣọkan orilẹede Naijiria ati alaafia laarin awọn eeyan rẹ."

Yakubu Dogara: Ẹ maṣe gbagbe ẹkọ nipa ifiraẹnijin, idariji, ijọsin fun Ọlọrun ati ikoraẹni-ni- ijanu pẹlu ifẹ tootọ fun ọmọlakeji

Yakubu Dogara

Oríṣun àwòrán, @YakubDogara

Àkọlé àwòrán, Ẹ maṣe gbagbe ẹkọ nipa ifaraẹnijin, idariji, ijọsin fun Ọlọrun ati ikoraẹni-ni- ijanu pẹlu ifẹ tootọ fun ọmọlakeji

Olori ile aṣoju-ṣofin, Yakubu Dogara rọ awọn musulumi lati fi asiko opin awẹ yii ṣe arojinlẹ lori ẹkọ ti wọn ba kọ, ki wọn si ranti awọn to ku diẹ kaa to fun lawujọ.

"Mo rọ yin lati ro arojinlẹ lori awọn ẹkọ bii ifaraẹnijin, idariji, ijọsin fun Ọlọrun ati ikoraẹni-ni- ijanu pẹlu ifẹ tootọ fun ọmọlakeji, eyi to suyọ lasiko Ramadan."

Gomina Dapọ Abiọdun (Ogun): Ẹ jẹ ki ifarajin ti ẹ ṣe lasiko Ramadan tubọ fa yin sunmọ Ọlọrun.

Gomina Dapọ Abiọdun

Oríṣun àwòrán, @ogun_state

Àkọlé àwòrán, Ẹ jẹ ki ifarajin ti ẹ ṣe lasiko Ramadan yẹ ko tubọ fa yin sin mọ Ọlọrun

Gomina Abiọdun rọ awọn musulumi lati ma ṣe gbagbe ẹkọ ifara ẹni jin ati titẹle ilana, iwa ati ẹkọ Anọbi Mohammed.

"Awọn ifarajin ti ẹ ṣe lasiko Ramadan yẹ ko tubọ fa yin sunmọ Ọlọrun sii"

Babajide Sanwo-Olu: Ẹ ranti awọn eeyan miiran ninu ajọyọ yin

Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Àkọlé àwòrán, Ẹ ranti awọn eeyan miran ninu ajọyọ yin

Adura ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu gba fun awọn musulumi ni tirẹ.

Ninu atẹjade kan to fi si oju opo twitter rẹ, Sanwo-Olu gbadura fun alaafia, ilọsiwaju ati igberusi fun awọn musulumi bi wọn ṣe n ṣajọyọ naa.

"ki Ọlọrun ko fi ifẹ kun ile yin, ki o si gba gbogbo adura yin."