Ramadan 2020: Buhari, Ọọni, Sultan Sokoto ní kí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti fi ìtúnu àwẹ̀ gbàdúrà fún Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, others
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kesi awọn ọmọ Naijiria lati gbadura ni ile lasiko ọdun itunu aawẹ Ramadan, lẹyin to kọ fun awọn eniyan lati maṣe wa si Ile Aarẹ ni Abuja.
Aare Buhari fi ikede naa sita lati gba ọwọ agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu.
Buhari to rọ awọn ẹlẹsin Musulumi lati gbadura ni ile, ni oun gbe igbeṣẹ yii lati dena itankalẹ arun Coronavirus.
Ninu ọrọ tirẹ, Ọọni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi rọ awọn Mususlumi lati lo asiko fi dupẹ fun idasi ẹmi ati ojurere Allah si awọn ọmọ Naijiria.
Ọọni rọ awọn ọmọ Naijiria lati gbaruku ti ijọba ki wọn balẹ bori arun Coronavirus to n ja tan kaakiri agbaye.
O ni ọna ti awọn eniyan le gba ṣe atilẹyin fun gbogbo ilakalẹ ijọba apapọ ni lati ri wi pe aarun naa dinku lawujọ, ki ohun gbogbo le pada si ipo.
Bakan naa, Sultan ti ilu Sokoto naa rọ gbogbo awọn Musulumi lagbaye lati tẹlẹ ofin titakete sirani lasiko ọdun Ramadan yii, ki wọn si gbadura nile wọn.
Sultan ni awọn gbe ẹsẹ le ipejọpọ awọn Musulumi lasiko ọdun yii kaakiri orilẹede Naijiria, lati le daabo bo awọn eniyan lọwọ arun Coronavirus.
Gomina Ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun naa kesi awọn ọmọ Niajiria lati ni igbagbọ pe arun Coronavirus yii yoo dopin.
Gomina Abiodun sọ eyi ninu atẹjade to fi sita lati ki awọn ẹlẹsin musulumi ku ọdun itunu aawẹ Ramadan.
O kesi awọn ọmọ Naijiria lati gbe ni alaafia pẹlu ara wọn,paapaa lasiko arun Coronavirus yii ti gbogbo eniyan ni agbaye n la kọja.
Gomina ipinlẹ Ogun naa parọwa si awọn eniyan lati jawọ ninu sisọ ohun ti wọn ko mọ nipa arun Coronavirus, amọ ki wọn gbiyanju lati tẹlẹ gbogbo ofin ati ilakalẹ ijọba lọna ati bori ajakalẹ arun Coronavirus naa.

Lẹyin isenu fun oṣu Ramadan, olori ijọ ẹsin Islam gbogbo lorilẹede Naijiria, to tun jẹ Sultan ti ilu Sokoto, Alhaji Saád Abubakar III ti kede oni, ọjọ iṣẹgun ọjọ kẹrin oṣu kẹfa gẹgẹ bii ọjọ ọdun itunu aawẹ, Eid-el-Fitr fun gbogbo musulumi lorilẹede Naijiria.
Sultan ti ilu Sokoto ṣe ikede yii lori Redio ati Tẹlifiṣan kan ni ilu Sokoto lẹyin ti wọn ri oṣu to le fun oṣu Shawwal.
Ṣaaju ni Sultan pàṣẹ fún àwọn mùsùlùmí láti ṣ'ọdẹ òṣùpá lónìí ṣugbọn bayii oun funra rẹ ti ri i o si ti kede rẹ.
O ni awọn eeyan ti ri oṣu lawọn ipinlẹ bii Kaduna, Kebbi, Yobe, Borno, Jigawa ati Sokoto.
O ni, "Ni ibamu pẹlu ofin Islam, a ni oreọfẹ lati kede pe oni ọjọ aje, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Ramadan, 1440 AH to bọ si ọjọ kẹta oṣu kẹfa ọdun 2019 ni awẹ oṣu Ramadan wa sopin ti oṣu tuntun Shawwal si bẹrẹ.
Bakan naa ni ìjọba Nàìjíríà ti kéde ìsinmi lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun àti Ọjọ́rú ọjọ karun oṣu kẹfa gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati ṣajọyọ itunu awẹ Ramadan lorilẹede Naijiria.














