Curruption Scandal: Ọ̀gá NIMASA tẹ́lẹ̀ r'ẹ́wọ̀n ọdún méjìlélógójì he

Calistus Obi

Oríṣun àwòrán, EFCC

Àkọlé àwòrán, Ọ̀gá NIMASA tẹ́lẹ̀ r'ẹ́wọ̀n ọdún méjìlélógójì he

Ile ẹjọ giga kan niluu Eko ti dajọ ẹwọn ọdun mejilelogoji fun adele ọga ajọ NIMASA (Nigerian Maritime Administration and Safety Agency), Ọgbẹni Calistus Obi.

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede Naijiria EFCC lo gbe Ọgbẹni Obi lọ sile ẹjọ lori ẹsun iṣowo to to miliọnu mẹrindinlogoje (#136m) kumọkumọ.

Amọ, ile ẹjọ fun Obi lanfaani lati san owo itanran to le igba miliọnu (N252 million) fun ẹsun ti wọn kan an.

Àkọlé fídíò, 'Mo ń ṣa ike jọ láti san owó ilé iwé ọmọ mẹ́ta'

Ileẹjọ tun dajọ ẹwọn ọdun mejilelogoji fun Ọgbẹni Alu Dismas to jẹ oluranlọwọ fun ọga NIMASA tẹlẹ, Patrick Akpobolokemi.

Àkọlé fídíò, Omar Al-Bashir ti wọ́n gbajọba lọ́wọ́ ẹ ló di wàhálà

Wọn ni wọn jẹbi ẹsun 2, 3, 4. 6, 7 ati 8 ti ajọ EFCC fi kan wọn nile ẹjọ lọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun 2016.

Ami ileẹjọ

Oríṣun àwòrán, NJC

Ninu oṣu kẹrin, ọdun 2016 ni EFCC kọkọ gbe awọn mejeeji lọ sile ẹjọ, ṣugbọn wọn ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn nigba ti igbẹjọ naa bẹrẹ.

Ẹlẹri mẹjọ ati ọpọ akọsilẹ ninu iwe lawọn olupẹjọ lo gẹgẹ bi idaniloju nigba ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ.

Ileeṣe Global Sea Investment ati Grand PAct Limited ni wọn jọ fẹsun ọhun kàn.

Igbẹjọ iwa ajẹbanu yii jẹ ọkan lara awọn ẹsun igbogun ti iwa ibajẹ tijọba Buhari ri ṣe lati ọdun 2015 to ti gori aleefa.