State Police: Buhari pariwo síta, ó ní èmi kò buwọ́lu ètò ọlọ́pàá agbègbè o!

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Iroyin ayọ meji lo gbode kan fun ọpọ awọn ọmọ Naijiria ni ṣisẹ n tẹle lọjọ aje ṣugbọn ko pẹ ti awọn ọmọ Naijiria fi gbọ pe ahesọ lasan ni ekeji ninu iroyin naa.
Akọkọ ninu iroyin yii ni pe aarẹ ti tẹwọ gba abajade iwadi igbimọ ti aarẹ gbe kalẹ fun atunto ikọ agboguntiwa idigunjale nileeṣẹ Ọlọpaa, SARS, ekeji iroyin si ni pe aarẹ Buhari ti buwọlu eto ọlọpa agbegbe fun orilẹede Naijiria.
Bi awọn eeyan kan ṣe n kan sara si igbesẹ naa ni awọn eeyan kan n pariwo pe ko ṣeeṣe nitori eto to jẹ mọ ilana iwe ofin orilẹede Naijiria ni ọrọ ọlọpaa agbegbe ti yoo si nilo atunṣe ile igbimọ aṣofin apapọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lẹyin-o-rẹyin ni o to han gbangba pe ọrọ naa ko ri bẹẹ rara. Aarẹ Buhari yanju ọrọ yii nigba to ṣalaye pe oun ko figba kankan fọwọsi ilana ọlọpaa agbegbe o.
Lẹyin ti o gba abajade iwadii ti igbimọ naa gbe kalẹ ni Aarẹ Buhari ti paṣẹ fun ileeṣẹ eto idajọ nijọba apapọ, ajọ to n risi ibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria, NHRC pẹlu ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria lati lọ tan imọlẹ si ọna ti wọn yoo gba lati ṣe amulo awọn aba ti igbimọ naa gbe kalẹ ninu iwadi rẹ.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Ibeere to wa n gbẹnu ọpọ kan ni pe, o daa o, bi aarẹ ko ba gbe igbesẹ yii, awọn wo lo wa wa nidi iroyin ẹlẹjẹ eyi to fun araalu ni ọpọ idunnu fun akoko diẹ lọjọ aje ọjọ kẹta oṣu kẹfa ọdun 2019?
Gbogbo agbaye lo mọ pe ọrọ idasilẹ ọlọpaa agbegbe ti pẹ lori igba agbeyẹwo lagbo oṣelu lorilẹede Naijiria. Gulegule awọn ọlọpaa, paapaa julọ ẹka adamọlẹkun ariṣe kandu-kandu, SARS ti mu ki ipe fun idasilẹ ọlọpaa agbegbe tubọ peleke sii.
Lootọ iroyin sọ pe idasilẹ ọlọpaa agbegbe (State and LG police) wa lara awọn ohun ti igbimọ yii da laba fun Aarẹ Buhari ninu abajade iwadii rẹ ṣugbọn gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Garba Shehu ṣe sọ, eyi ko tumọ si pe aarẹ ti buwọlu u. O ni o di igba ti iwe aṣẹ ijọba, 'whitepaper' ba jade ki ẹnikẹni to lee sọ ohun gan ti aarẹ fẹ lori rẹ.












