8TH Assembly: FRSC kò yan Saraki sọjú pé kó dá nọ́mbà ọkọ̀ tó lò padà

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bukola Saraki
Ko si idi kankan fún wa lati yan Saraki sọju -FRSC
Ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ lorilẹ-ede Naijiria, FRSC ti sọ pe oun ko yan adari ile igbimọ aṣofin ana ṣoju.
O fidi eyi mulẹ lẹyin ti ajọ naa sọ fun awọn aṣofin ti ko pada sile lati da nọmba mọtọ ti wọn lo pada.
Alukoro fun ajọ FRSC, Bisi Kareem to ba BBC sọrọ fidi rẹ mu lẹ pe awọn aṣofin ti ko pada sile le lo nọmba yii laarin ọdun 2015 titi di oṣu kẹfa, ọdun 2019.
Sẹnẹtọ mọkandinlaadọrin pẹlu aṣoju ṣofin mọkanlelaadọjọ ni FRSC n beere pe ki wọn dá awọn nọmba ọkọ yii pada.
Bisi Kareem ṣalaye pe ko si otitọ kan ninu iroyin to n tan kalẹ pe ajọ FRSC yan Saraki ṣọju ni.
Ọgbẹni Kareem sọ pe ọrọ naa ko nii ṣe pẹlu Saraki nikan, gbogbo ọmọ ile ti ko pada sile lo kan.
Alukoro fun ajọ FRSC fikun ọrọ rẹ pe ajọ naa sọ fun akọwe ile igbimọ aṣofin agba lati awọn nọmba ọhun nitori oun lo sun mọ wọn ju.
Awọn ilumọọka Sẹnẹtọ bi Tayo Alasoadura, Yele Omogunwa ti wọn ṣoju ipinlẹ Ondo pẹlu Godswill Akpabio lati ipinlẹ Akwa Ibom lo fidi rẹmi ninu ibo ile igbimọ aṣofin agba to lọ.















