9th Assembly: Saraki kí àwọn adarí aṣòfin tuntun kú oríire

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki
Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba ana ti gba awọn adari ile aṣofin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan sípò nimọran.
Ninu ọrọ ikini rẹ to fi ranṣẹ, o ki Aarẹ ile aṣofin agba tuntun, Ahmed Lawan ati igbakeji rẹ, Ovie Omo-Agege, Adari ile aṣoju-ṣofin tuntun, Femi Gbajabiamila ati igbakeji rẹ, Idris Wase gẹgẹ bi wọn ṣe bẹrẹ irinajo wọn nile igbimọ aṣofin ikẹsan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bukola Saraki ti jẹ gomina ipinlẹ Kwara ri ko to di aarẹ ile igbimọ aṣofin agba.
O gba wọn nimọran lati maa fi awọn Naijiria ati ọrọ to ba kan wọn ṣe ọkunkundun ki wọn si da abo bo ẹka iṣofin Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ẹwẹ, iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe aarẹ tuntun funrarẹ, Lawan ni ohun yoo ṣe daadaa si awọn ẹlẹgbẹ oun lai fi ti oṣelu ẹya tabi ẹsin ṣe. O sọ eyi nigba to n sọ ọrọ akọsọ rẹ lẹyin eto ifilọọlẹ ile igbimọ aṣofin ikẹsan eyi to gbe e wọle.