Election Update 2019: Amúgbálẹgbẹ̀ẹ́ Saraki ní ọ̀gá òun kò kí olùdíje APC kú oríire

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki
Aarẹ ile aṣofin, Bukọla Saraki ko ni si ni ile aṣofin naa fun saa iṣejọba to n bọ, eyii kii sii ṣe iroyin mọ; ṣugbọn iroyin to yọ nibẹ bayii ni pe lẹyin to padanu idibo ẹkun aṣofin apapọ ti aringbungbun Kwara, Saraki ko ki Oloriẹlgbẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC to bori ku oriire o.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Sẹnetọ Bukọla Saraki lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan ti, Yusuph Ọlaniyọni to jẹ amugbalẹgbẹ fun un lori ọrọ iroyin sita.
ninu eyi ti o ti n yọ ara rẹ kuro ninu iroyin kan ti awọn kan n pin kaakiri ikanni ibanisọrọ Whatsapp pe ẹgbẹ oṣelu PDP ati Saraki ti gba ijakulẹ wọn, wọn si ti ki ẹgbẹ oṣelu APC atawọn oludije rẹ ku oriire.
Atẹjade naa to fi sita ni ọjọ aje tun ṣalaye siwaju sii pe laipẹ laijina ni agọ asofin agba Saraki yoo sọrọ lori iha ti wọn kọ si eto idibo naa.
"Ki araalu keti ikun si iroyin ẹlẹjẹ tawọn ẹgbẹ PDP n gbe kaakiri ori ikanni ibanisọrs Whatsapp.
Nitori naa ki ẹgbẹ oṣelu APC yee gbe iroyin sita lati ki ara rẹ ku oriirẹ ki wọn maa so ms ẹgbẹ wa lọrun."
Bi ẹ ko ba gbagbe, ni alẹ ọjọ aiku ni INEC kede esi idibo sile aṣofin agba lẹkun aringbungbun Kwara ninu eyi ti oludije ẹbẹ oṣelu APC, Oloriẹgbẹ ti fagba han Bukọla Saraki.









