June 12: Buhari yóò la ọ̀na 2,000 kìlómítà, èèyàn 100 yóò yọ nínú òṣì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lasiko ayajọ June 12, ti i se ayajọ ijọba Tiwantiwa, aarẹ Muhammadu Buhari fi akoko naa sọ ọrọ apilkọ rẹ fun saa keji eyi to kun fun ọpọ ileri itunu fawọn ọmọ orilẹede yii.
Bẹẹ ba gbagbe, Aarẹ Buhari bẹrẹ saa keji iṣejọba rẹ ni ọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2019, amọ ti ko ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lẹyin ti wọn bura fun un tan.

Oríṣun àwòrán, @Buhari
Gbagede Eagle Square nibi ti Naijiria ti n sami ayẹyẹ iṣejọba Awa ara wa ni Abuja, ni aarẹ Buhari ti wa ba awọn ọmọ Naijira sọrọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu ọrọ rẹ fun ayajọ June 12, Buhari ṣeleri lati tubọ ri si eto aabo fun ẹ̀mí àti dukia.
Aarẹ Buhari ni, oun gba pe ajọṣepọ wa laarin ìṣẹ́, eto ọrọ ajé ti ko daa pẹlu iwa jẹgudujẹra, lai yọ eto aabo ti ko fini lọkan balẹ silẹ.
Aarẹ Buhari tun ni, ko si nkan to le di Naijiria lọwọ idagbasoke gẹgẹ bii ti China, India ati Indonesia.
Kókó inu ọrọ Aarẹ Buhari:
Aarẹ Buhari bẹrẹ nipa ṣiṣe alaye kikun lori pataki Naijiria ninu idagbasoke iṣejọba alagbada nilẹ Adulawọ.
O mẹnuba awọn aṣeyọri ijọba rẹ ni saa to kọja (2015 si 2019).

Oríṣun àwòrán, @pius
Aarẹ Buhari ni oun ti jagun Boko Haram de ibi to lapẹrẹ lati 2015.
O ni nitootọ iṣẹ yii pọ lati gbogun ti awọn ajinigbe ati agbesunmọmi, ṣugbọn eyi ti di ankoo fawẹẹli gbogbo agbaye.

Oríṣun àwòrán, @others
O ni ijọba oun ti mojuto ọrọ atunṣe eto ẹkọ ati idagbasoke eto ọrọ aje Naijiria, yatọ si titun awọn opopona ṣe.

Oríṣun àwòrán, @others
Ileri ti Buhari fẹ gbajumọ ni saa keji iṣejọba rẹ:
Nitootọ Aarẹ Buhari ko soju abẹ niko ni pato lori ileri rẹ, ṣugbọn o ṣapejuwe awọn koko ti ijọba oun yoo gbajumọ lasiko yii bii:
- Aṣepari awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba rẹ ti bẹrẹ tẹlẹ.
- Fifopin si ìṣẹ́ àti òṣì ọgọrun un miliọnu eniyan ti wọn ba ni adari rere.
- Rii wi pe iṣọkan wa laarin eto idajọ Naijiria.
- Ṣiṣe atunṣe si eto ilera alabọde ati ti ile iwosan ijọba nlanla.
- Riran awọn olokowo keekeeke lọwọ.
- Ṣiṣe atilẹyin fun awọn onile iṣẹ nlanla.

Oríṣun àwòrán, @others
Awọn olori orilẹ-ede to wa nijoko nibẹ pẹlu Buhari lasiko ayajọ ijọba tiwa n tiwa naa ni aarẹ orilẹ-ede Rwanda, Chad, Niger ati Gambia.













