Ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun yóò pèsè ìmọ̀ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama - ìjọba àpapọ̀

Awọn akẹkọọ ni yara ikawe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ti ní àwọn ti gbé ìlànà tuntun kalẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama láti lè ri dájú pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń jáde pẹ̀lú ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́ méjì.

Mínísítà fétò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Tahir Mamman ṣàlàyé pé ìlànà tuntun náà yóò pọn kún ìmọ̀ àti níní ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti ipele ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama.

Níbi ètò àpérò lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tó wáyé nílùú Abuja lọ́jọ́bọ̀ ni Mamman ti ṣàlàyé ìgbésẹ̀ náà.

Ó ní ìlànà náà yóò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àǹfàní láti lè ní iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n le máa ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá jáde kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ girama.

Ó sọ pé èyí yóò mú kí wọ́n lè ní ìgbé ayé tó rọrùn.

Mamman wòye pé ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lóde ní Nàìjíríà nílò àtúngbéyẹ̀wò pàápàá bí ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣe ti gba ayé kan báyìí.

Ó fi kun pé iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ báyìí ń ṣe àmúṣẹ mímú àyípadà tó ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà láti lè ri pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àǹfàní sí ẹ̀kọ́ tó pójú owó.

Bákan náà ló sọ àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ lórí òfin tuntun tí ìjọba gbé jáde pé akẹ́kọ̀ọ́ tí yóò bá ṣe ìdánwò àṣekágbá ilé ẹ̀kọ́ girama gbọdọ̀ ti pé ọdún méjìdínlógún.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Mínísítà náà ṣàlàyé pé ìjọba kò sọ pé dandan akẹ́kọ̀ọ́ ti gbọdọ̀ pé ọdún méjìdínlógún kó tó ṣe àwọn ìdánwò bíi WAEC, NECO tàbí NABTEB àmọ́ ó gbọ́dọ̀ ti pé ọdún yìí kó tó wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga.

Ẹ ó rántí pé níní oṣù Keje ọdún yìí ni Mamman kéde pé àwọn kò ní gba akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá ì tíì pé ọdún méjìdínlógún láti ṣe ìdánwò wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì.

Èyí fà awuyewuye nígbà náà pàápàá lórí ayélujára bí àwọn ènìyàn ṣe ń sọ pé ìgbésẹ̀ náà kò dára tó.

Mamman wá ṣàlàyé pé òfin náà kìí ṣe nǹkan tuntun, pé ó ti wà láti ọdún 1993 àti pé àwọn kàn fẹ́ ṣe àmúṣẹ rẹ̀ ni.

Ó ní èyí kò túmọ̀ sí pé akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá ì tíì pé ọdún méjìdínlógún kò ní ṣe ìdánwò WAEC, NECO tàbí NABTEB ṣùgbọ́nwọn kò ní le wọilé ẹ̀kọ́ gíga.

Mínísítà tún sọ̀rọ̀ lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ẹ̀bùn nípa mímọ ìwé ju ọjọ́ orí wọn lọ.

Ó ní àwọn ń gbé ìgbésẹ̀ láti rí dájú pé àwọn ṣe àmójútó irú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ lójúnà àti lè fàyè gbà wọ́n láti ri pé wọ́n wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga láì tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Mínísítà kejì lórí ètò ẹ̀kọ́, Dókítà Yusuf Sununu Tanko tẹmpẹlẹmọ ìdí tí ìjọba gbọdọ̀ ṣe mú ẹ̀kọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ ní òkúnkúndùn.

Sununu ní ìjọba gbọdọ̀ tètè gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti fi ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti ri pé wọ́n ń pèsè iṣẹ́ fúnra wọn láti kékeré.