Awọn ọmọlẹ́yìn El-Zakzaky: Ọlọ́pàá ló ń fa rúkèrúdò lásìkò ìwọ́de wọn

Awọn ọlọ́pàá ju tajutaju si aarin àwọn ọmọ ẹgbẹ Shi'ite

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Àkọlé àwòrán, Wahala bẹ́ sílẹ̀ nílùú Àbúja lọ́jọ́ ajé láàárín àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀sìn shi'ite
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀sìn shi'ite ti fi ẹ̀sùn kan iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀èdè Nàìjíríà pé àwọn gan an ló ń ṣokùnfà rúkèrúdò tó máa ń wáyé ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ṣe ìwọ́de wọn.

Wahala bẹ́ sílẹ̀ nílùú Àbúja lọ́jọ́ ajé láàárín àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀sìn Shi'ite.

Àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀sìn Shi'ite naa ni wọ́n ń pè fún ìtúsílẹ̀ aṣíwájú ìjọ náà, Sheikh Ibrahim Elzakyzaky tí ìjọ ba fi sí àtìmọ́lé láti bíi ọdún mẹ́ta sẹ́yìn

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú BBC Yoruba, agbẹnusọ fún ìjọ ẹ̀sìn Islam naa, Ibrahim Musa ní ìwọ́de alá àláfíà lawọn máa ń ṣe ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá ló máa ń fi ipá àti ìbọn kò wọ́n lójú.

Àwọn ọmọlẹ́yìn Elzakyzaky ń pè fún ìtúsílẹ̀ aṣíwájú ìjọ náà nibi iwọde kan

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọmọlẹ́yìn Elzakyzaky ń pè fún ìtúsílẹ̀ aṣíwájú ìjọ náà tí ìjọba fi sí àtìmọ́lé lọ́dún 2015

"Lójú àwọn ọlọ́pàá yìí, tí o bá ti leè sọ fún wọn pé ọmọ ìjọ Shi'ite ni ẹ́, wàhálà ni wọn yóò gbé dìde.

Ìtúsílẹ̀ Sheikh ni a ń béèrè, ṣùgbọ́n ìjọba kò fẹ́ tẹ̀lé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n dáa sílẹ̀."

Agbẹnusọ fún ìjọ ẹ̀sìn Islam naa, ni kò sí ẹni tó kú gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn kan ṣe ń sọ káàkiri.

"Ìbọn ba èèyàn wa kan lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń gbàdúrà pé kó máà kú.

Kò dín ní ogún àwọn obìnrin àti ọmọdé lára mẹ́rìnléláàdọ́fà tí àwọn ọlọ́pàá kó sí àhámọ́ láti ọjọ́ ajé."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Kíni ọlọ́pàá àti ẹgbẹ́ alátakò ń sọ?

Àmọ́ṣá, ileeṣẹ ọlọ́pàá ilu Abuja ní àwọn afurasi ti wọ́n mú yóò fojú bá ile ejo ní kété ti àwọn ba parí ìwádìí.

Ní báyìí, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti bèèrè fún ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, o ni irufẹ itaporogan bẹ́ẹ̀ láàárín ọlọ́pàá àti àwọn ọmọlẹyìn Elzakyzaky kì bá tí wáyé, kání íjọba tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n túu sílẹ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: