Human trafikking: Obìnrin Nàìjíríà tí wọ́n fẹ́ lù ní gbànjo lórí 'Facebook' ní Lebanon sọ pé òun kò wá sílé mọ́

awọn ọwọ kan ninnu ṣẹkẹṣẹkẹ

Oríṣun àwòrán, other

Ọmọbìnrin Naijiria ti wọn lu aago gbanjo le lori, lori ayelujara Facebook lorilẹ-ede Lebanon, ti sọ pe oun ko pada sile mọ.Oludari ajọ to n mojuto ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa lo sọ bẹ ẹ.Ẹgbẹrun kan Dọla ni wọn ta obìnrin naa, ko to o di pe ijọba orilẹ-ede Lebanon doola rẹ, ti wọn si mu u lọ si ileesẹ aṣoju Naijiria nibẹ.

Iṣẹlẹ pipolowo obìnrin naa fun tita fa awuyewuye ni Naijiria, ti ọwọ si pada tẹ ọkunrin to ta a.Sugbọn, obìnrin ẹni ọgbọn ọdun naa ti sọ pe oun ti ri isẹ miran ni Lebanon.Abike Dabiri-Erewa sọ pe gbogbo igbiyanju oun lati yi lọkan pada ni ko so èso rere."Koda, Akọwe ijọba ipinlẹ Oyo, to jẹ ipinlẹ to ti wá, ba a sọrọ. Ireti wa ni pe wọn ko ni ma a fi awọn ọmọ Naijiria to n lọ sisẹ ni Lebanon ṣe òwò ẹrú."O sọ pe ọmọ Naijiria mọkandinlaadọrin ninu mọkandinlọgọrin to wa ni Lebanon ni ijọba ti ko pada sile. Gbogbo wọn lọ si wa ni iyasọtọ lọwọ lọwọ.Koda, ileesẹ aṣoju orilẹ-ede Lebanon ti f'opin si fifun awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ ẹ lọ ṣe ọmọ ọdọ ni Lebanon, ni iwe irinna.