Nítorí owú jíjẹ, ọkọ Zarka gé imú aya rẹ̀ dànú!
Oju mi ri to, lọwọ ọkọ mi ati ibinu rẹ- Zarka
Ọkọ Zarka lo ge imu aya rẹ jabọ lasiko ti wọn n ja.
Zarka sọ nipa gbogbo irora ti oju rẹ ri nile ọkọ rẹ to n jowu ju.
Dokita Zalmani Khan Ahmadzai atawọn miran lo ran Zarka lọwọ lori iṣẹ abẹ to fi le pada maa mi eemi sinu ati sita bi o ti yẹ.
Iṣẹ abẹ to gba wọn to wakati mẹta ni wọn ṣe fun Zarka.
- ìkà ni àwọn Ọlọ́pàá Nàìjíríà, wọ́n fìyà ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀dí jẹ́ mi fún ọdún 17- Adebayo Ojo
- Èèmọ̀! Ọmọbìnrin ọdún 25 gún ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ pa nítorí ó ní ko lọ ṣẹ́ oyún
- Wo ohun tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n ṣe fún Sunday Shodipe, afurasí ìṣekúpani l'Akinyele
- ìkà ni àwọn Ọlọ́pàá Nàìjíríà, wọ́n fìyà ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀dí jẹ́ mi fún ọdún 17- Adebayo Ojo
Zarka ni ọpọ ọdun ni ọkọ oun fi n fiya jẹ oun ninu ile rẹ.
wọn gba imọran pe ki lọkọ laya maa ni suuru ki wọn maa gbe ni irẹpọ lo dara.
Bẹẹ, ki koowa ṣọra iru ẹni ti wọn ba fẹ ba rin irinajo ifẹ tabi igbeyawo.
Ọkọ Zarka ti wa ni ọgba ẹwọn bayii ẹbi ọkọ rẹ si ti gba ọmọ kan ṣoṣo ti wón bi fun ara wọn lọwọ Zarka.

