Ban on Okada: Báwọn èèyàn kan ṣe tako òfin kí ọ̀kadà má rìn l‘Eko, làwọn míì faramọ́ọ

Àkọlé fídíò, Ban on Okada: Báwọn èèyàn kan ṣe tako òfin kí ọ̀kadà má rìn l‘Eko, làwọn míì faramọ́ọ

BBC Yoruba bọ sigboro lati gbọ tẹnu awọn araalu lori ofin kan tijọba ipinlẹ Eko kede laipẹ yii eyi to fi ofin de lilo ọkada ati kẹkẹ Marwa lawọn oju popo kan nipinlẹ naa.

Ọjọ kinni osu keji ọdun 2020 si ni ofin naa yoo ti bẹrẹ si ni fidi mulẹ́, ijọ̀ba ibilẹ mẹẹdogun si ni ọrọ ọhun kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ero awọn ọdọ lori isẹlẹ naa ni pe ole ati awọn onijibiti ọmọ Yahoo yoo pọ si ti ofin naa ba fi fidi mulẹ.

Ero awọ̀n eeyan to ba BBC sọrọ lori isẹlẹ yii si lo yatọ, bi awọn kan se faramọ ofin ọhun, ni awọn miran tako.