Gbèsè, ẹ̀tàn lásán ló kún inú àbá ìṣúná tí Tinubu gbé síwájú ilé aṣòfin- PDP, LP figbe ta

Aworan aarẹ

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Awọn ẹgbẹ alatakomeji to lewaju lorileede Naijiria ti s ero wọn lori bi aarẹ Bola Tinubu ṣe gbe aba iṣuna 2024 kalẹ niwaju ile aṣofin.

Wọn ṣapejuwe aba iṣuna yi gẹgẹ bi ''itanjẹ ti ko ni afojusun iyipada ọrọ aje kankan''

LỌjọru ni aarẹ Bola Tinubu ṣe agbekalẹ aba iṣuna triliọnu mẹtadinlọgbọn Naira din diẹ yi kalẹ nibi ijoko apapọ awọn ile aṣofin Naijiria.

Aba iṣuna naa ti aarẹ pe orukọ rẹ ni ''aba iṣuna ireti akọtun '' ni wọn gbe kalẹ lori afojusun owo agba epo rọbi dọla mẹrindinlọgọrun ti ireti si wa pe Naijiria yoo le pese agba miliọnu 1.78 epo rọbi lojumọ kọọkan.

Iye ti wọn gbe isiro owo paṣiparọ dọla si Naira si jẹ dọla kan si 750 dọla.

Ninu ọrọ rẹ aarẹ Tinubu sọ pe iṣuna yi yoo da lori nkan mẹta tii ṣe aabo,ipese iṣẹ ati mimu adinku ba iṣẹ ohun oṣi lawujọ.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party fi sita,wọn ni aba iṣuna yi jẹ aisan to lagbara ti wọn ko gbọdọ jẹ ko lọ bẹ tori pe yoo sọ orileede Naijiria sinu ọfin iṣẹ ati airoju''

Atẹjade yi da lori iye owo ti wọn yoo fi san gbise tii ṣe N8.25tn ati alafo owo ẹya ti yoo wa nilẹ nipa yiya N18tn ti wọn fẹ fi ẹyawo ati alekun owo ori di gbese rẹ.

Aba iṣuna akọkọ ti Aarẹ Tinubu yoo fi ṣowọ ree

Ẹgbẹ oṣelu PDP tẹnumọ pe ''O han pe aba iṣuna yi to kun fun mudunmudun fun aarẹ ati awọn olori APC ti ni erongba lati wa owo nipaṣẹ yiya ati fifikun owo ori lara awọn ọmọ Naijiria lọna ati ko Naijiria sinu ọfin gbese ti yoo si ko inira ba awọn to ku diẹ kaato fun ni Naijiria''

Ninu aba iṣun yi, wọn ya triliọnu mẹwaaNaira din diẹ N9.92tn ti wọn ya sọtọ fun gbigbọ bukata ojojumọ ti 8.7tn si wa lọtọ fawọn iṣẹ pataki.

Akọkọ aba iṣuna ree ti aarẹ Tinubu yoo gbe wa siwaju ile lati igba to to gba ijọba lọwọ aarẹ tẹlẹ Muhammadu Buhari loṣu Karun un.

Aarẹ ko kede iye ti wọn ya sọtọ fawọn ẹka ati ileeṣẹ ijọba orileede Naijiria.

Igbesẹ yi yatọ si tatẹyinwa ti awọn aarẹ a maa kede owo ina fawọn wọnyi.

O rọ awọn ti ọrọ kan lati ri pe wọn ṣe agbeyẹwo ki aba iṣuna naa si ri ibuwọlu laarin ọgbọn ọjọ.

Owo yiya ati gbese ti ṣu wa-Labour Party

Ninu aba iṣuna yi, ijọba APC sọ pe awọn nireti pe eto ọrọ aje Naijiria yoo gbooro si pẹlu o kere ju, ida mẹrindinlọgọrin ninu ida ọgọrun.

Bẹẹ naa ni aarẹ Tinubu sọ pe ijọba oun yoo gbiyanju ki iye ọwọngogo nkan duro ni ida 21.4 lọdun 2024 dipo ida 27.33 to wa loṣu Kẹwaa ọdun yi.

Amọ ṣa ẹgbẹ oṣelu PDP nikan kọ lo bẹnu atẹ lu aba iṣuna yi.

Ẹgbẹ alatako mii Labour Party sọ pe awọn ko ri apẹrẹ ibi ti APC yoo ti ri owo san awọn gbese to wa nilẹ.

''Gbese ti ṣu wa.Nkan taa fẹ ni ki a beere fun idarijin gbese taa ni lọna ati ṣe iranwọ fun orileede wa tori awọn ileeṣẹ to yẹ ko gbe wa larugẹ ni ko ṣiṣẹ mọ''

Ọrọ ti Tanko Yunusa agbẹnusọ ẹgbẹ Labour Party sọ ree.

O fikun pe ''Ti wọn ba le ṣe eleyi, wọn o mu iyipada wa ṣugbọn nisinyi, ọrọ ọkọ ti wọn fẹ ra lo jẹ wọn logun awa o si nilo ọkọ oju omi lati ọwọ wọn.''

Gbese ko da fun orileede wa-ọmọ ile aṣofin

Ni oṣu Kẹsan ọdun 2023, ibi gbese Naijiria de duro ni N87.38tn

Aba iṣuna yi fojusun pe awọn yoo san N8.25tn pada ni 2024.

Eyi si jẹ ida marundinlaadọta gbogbo gbese Naijiria labẹ ile.

Ọmọ ile aṣojuṣofin kan to n ṣoju ẹkun idibo Fagge ni ipinlẹ Kano labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP Muhammad Bello Shehu sọ pe wahala wa pẹlu owo yiya.

Wọn o ni gba owo taa ba da pada ni Naira,dọla ni wọn yoo gba pada.Ipo wo si ni paṣiparọ dọla wa bayii ni Naijiria?Njẹ a tiẹ ni dọla taa le fi pamọ si akoto wa fun ilẹokere bii?''

Nigba taa bi leere pe bawo ni a o ṣe ri owo na ti a ko ba ya owo o fesi pada pe

''A ni lati ṣe iṣuna wa ni ibamu pẹlu iye owo taa ni lapo.Ni bayii a gbe aba iṣuna kalẹ lori pipawo wọle lori agba epo 1.78m lojumọ.Njẹ ifkanbalẹ wa lagbegbe taa ti wa epo yi ti yoo jẹ ka le ri iye taa fẹ yi?''