Godwin Asediba, ọmọ orílẹ́èdè Ghana, gba àmì ẹ̀yẹ BBC Komla Dumor ti ọdún 2025

Aworan Godwin Asediba, lati ori de ejika rẹ. O gẹ irun ori rẹ lọ silẹ, irungbọn rẹ naa ko si gùn pẹlu. O n rẹ́rìn-ín, o si n wo oju kamẹra lọọkan.
Àkọlé àwòrán, Godwin Asediba ṣalaye pe ipe lati tẹsiwaju ninu iṣẹ iroyin ni ami ẹyẹ ti oun gba naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Akọroyin ọmọ orilẹede Ghana, Godwin Asediba, ti gba ami ẹyẹ ileeṣẹ BBC ti a mọ si ''BBC News Komla Dumor Award'', ti ọdun 2025 yii.

Godwin to jẹ atọpinpin labẹnu akọroyin, onisinima ati atọkun iroyin ni ẹnikẹwaa to gba ami ẹyẹ yii. Ileeṣẹ TV3 ati 3FM ni Ghana lo n ba ṣiṣẹ. Bakan naa si ni awọn iroyin to ṣiṣẹ lori ẹ ti farahan kaakiri agbaye.

Lọpọ igba, awọn iroyin to ni i ṣe pẹlu ọmọniyan ni Godwin, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) maa n ṣiṣẹ le lori. Erongba rẹ lori awọn iṣẹ bẹẹ si ni lati gba idajọ ododo fun awọn eeyan ti ajunilọ ba n fi ọwọ ọla gba loju lawujọ.

Ami ẹyẹ naa to ti pe ọdun mẹwaa ti awọn eeyan ti n gba bayii, n waye ni iranti Dumor, akọroyin ọmọ ilẹ Ghana to tun jẹ atọkun eto fun iroyin agbaye BBC, ẹni to ku lojiji lẹni ọdun mọkanlelogoji (41), ni 2014.

''Ìgbési ayé Komla ń rán wa létí pé ó yẹ ká máa sọ ìtan Africa ní kíkún''

Ninu ọrọ Godwin Asediba, ẹni to ti ṣiṣẹ takuntakun lati fi iroyin tun orukọ ilẹ Africa ṣe lagbaaye pẹlu idaniloju ati igboya, o ni :

"Igbesi aye Komla funra rẹ ati ilana to fi silẹ fun wa, n ran wa leti pe o yẹ ka ma sọ itan Africa ni kíkún, a ko si gbọdọ bẹru lati duro ṣinṣin lori ododo." Bẹẹ ni Asediba wi.

O ni bi oun ṣe gba ami ẹyẹ yii ki i ṣe aṣeyọri lasan fun oun, bi ko ṣe pe yoo jẹ koun tun maa tẹsiwaju ninu iṣẹ iroyin, ninu jijẹ iwuri fun awọn ẹlomi-in ati mimu ayipadawa waye nibi to ba ti yẹ.

Nigba ti wọn n ṣalaye iwoye wọn nipa Asediba, igbimọ idajọ to fun un ni ami ẹyẹ naa sọ pe iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ abẹnu rẹ to n ṣe lo wu awọn lori, ati igbagbọ rẹ lai yẹsẹ ninu iroyin ododo.

Iroyin kan to ṣiṣẹ le lori to si jẹ amuyangan fun Godwin ju, ni eyi to ṣe nipa bi awọn ile igbokusi to tobi ju ni Ghana ṣe di akọti, to si le ko ewu ba alaafia araalu.

Ni bayii, Asediba ti ṣetan lati lọ si ilu London, nibi ti yoo ti ṣiṣẹ fun oṣu mẹta pẹlu ikọ iroyin amohunmaworan BBC, ti redio ati ti ori ayelujara.

Yoo tun gba idanilẹkọọ pẹlu, awọn agba ọjẹ ni BBC yoo si tun bu omi ọgbọn fun un mu.

''Àmi ẹ̀yẹ Komla Dumor ń ṣàwárí àwọn akọ̀ròyìn ilẹ̀ Africa tó ní ẹ̀bùn''

Komla Dumor
Àkọlé àwòrán, Ọdun kan ṣiwaju iku rẹ, Komla Dumor, farahan ninu iwe iroyin 'New African magazine', nibi ti wọn ti ṣafihan awọn akinkanju ọmọ ilẹ Africa ọgọrun-un (100 most influential Africans)
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Lati ọdun kẹwaa sẹyin, ami ẹyẹ Komla Dumor yii ti ṣe iranlọwọ lati ṣawari awọn ọmọ ilẹ Africa to ni ẹbun iṣẹ iroyin gidi. Ohun iwuri lo jẹ lati ri bi wọn ṣe n fi apẹẹrẹ ti ko ni i parẹ lelẹ ni BBC ati ni awọn aaye mi-in."

Juliet Njeri, Adari ẹkun ilẹ Africa nileeṣẹ BBC lo sọ bẹẹ.

O fi kun un pe:

"Ayẹyẹ ẹlẹẹkẹwa yii n jẹri si ilana Komla Dumor to fi silẹ: Bi Komla ṣe fẹran ki eeyan ni igboya, ki eeyan fi otitọ gbe iroyin kalẹ ati ki eeyan gbe ti Africa si ookan aya rẹ, ko le ku , o ṣi wa bẹẹ."

Lara eto ti wọn ti la kalẹ fun Asediba to gba ami ẹyẹ naa bayii ni pe yoo rin irinajo lọ si ilẹ Africa kan, lati royin iṣẹlẹ kan ti wọn yoo gbe jade ni BBC fun gbogbo awọn ololufẹ ikanni naa kaakiri agbaye.

Awọn to ti gba ami ẹyẹ yii ṣiwaju ni: Rukia Bulle, Paa Kwesi Asare, Dingindaba Jonah Buyoya, Victoria Rubadiri, Solomon Serwanjja, Waihiga Mwaura, Amina Yuguda, Didi Akinyelure ati Nancy Kacungira, ẹni akọkọ to gba ami ẹyẹ naa.

Lọdun to kọja, Bulle rin irinajo lọ si Senegal lati royin nipa ẹgbẹ ẹlẹsin Islam kan ti a mọ si Baye Fall. Irisi awọn ẹgbẹ naa yatọ si ti awọn Musulumi ti aye ti mọ, o si mu ki wọn da yatọ lawujọ ẹsin naa.

Obinrin kan n wo foonu rẹ pẹlu aworan BBC News Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images/BBC