Ìdí tí ilé ẹjọ́ fi gbẹ́sẹ̀ lé àkáǹtì owó mẹ́rin tó jẹ́ ti Mele Kyari, ọ̀gá àgbà tẹ́lẹ̀ fájọ NNPCL

Oríṣun àwòrán, NNPCL/X
Ile ẹjọ ijọba apapọ l'Abuja ti paṣẹ pe ki wọn gbẹsẹ le akaunti mẹrin ni banki Jaiz, ti wọn lo jẹ ti Mele Kyari, ọga agba tẹlẹ fajọ NNPCL, lori ẹsun jibiti ati kiko owo lọ si ilẹ okeere.
Adajọ Emeka Nwite lo paṣẹ yii lẹyin ti agbẹjọro ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ, Ogechi Ujam, rọ ile ẹjọ lati gbẹsẹ le awọn akaunti naa titi ti ajọ EFCC yoo fi pari iwadii rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan Kyari.
Adajọ Nwite sọ pe, oun ti ṣe agbeyẹwo ẹri ati atotonu ti agbẹjọro EFCC mu wa si ile ẹjọ.
O ni oun si gba wi pe ki wọn gbe awọn akaunti naa tipa tori ẹri ti agbẹjọro olupẹjọ mu wa fẹsẹ mulẹ.
Adajọ wa sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan an nigba ti iwadii n tẹsiwaju.
Ohun ti mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan Mele Kyari ree
Lọjọ kọkanla oṣu Kẹjọ yii ni ajọ EFCC gbe Kyari lọ ile ẹjọ lori ẹsun pe oun lo ni akaunti banki mẹrin eyi ti wọn fi n lu jibiti ti wọn si tun lo lati ko owo lọ si ilẹ okeere.
EFCC rọ ile ẹjọ lati gbẹsẹ le awọn akaunti owo naa bi ajọ naa ṣe n baṣẹ iwadii lọ lori ẹsun jibiti ati kiko owo lọ silẹ okeere ti wọn fi kan Kyari lori awọn apo ikowosi naa.
Awọn akaunti ọhun ni ''Jaiz Bank 0017922724 – Mele Kyari; Jaiz Bank 0018575055; Guwori Community Development Foundation ati Jaiz Bank 0018575141 – Guwori Community Development Foundation.''
EFCC ṣalaye wi pe iwadii awọn ti fi han pe owo to le ni N600,000,000 lo wa ninu awọn akaunti mẹrin ọhun lọna aitọ.
Amin Abdullahi to jẹ ọkan lara awọn oluwadi EFCC sọ pe ẹsun ti ajọ Guardians of Democracy and Rule of Law fi kan Kyari lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹrin wa lara nnkan ti EFCC ṣiṣẹ le lori.
Abdullahi loun wa lara awọn eeyan to ṣiṣẹ lori ẹsun ti wọn fi kan ọga agba NNPCL tẹlẹ naa.
''Emi atawọn akẹgbẹ mi ṣe oniruuru iwadii de awọn ile ifowopamọ kan lati fi idi ọrọ naa mulẹ,'' Abdullahi lo sọ bẹẹ.
O fikun ọrọ rẹ niwaju ile ẹjọ pe meji ninu awọn akaunti owo mẹrin naa ni orukọ Mele Kyari wa nibẹ, nigba ti orukọ ajọ ti kii ṣe ti ijọba wa lori meji to ku.
EFCC sọ pe iwadii tawọn ti ṣe fi idi rẹ mulẹ pe owo n wọ awọn akaunti mẹrin yii lati ajọ NNPC ati lati awọn ileeṣẹ epo rọbi to n ṣiṣẹ pọ pẹlu NNPCL loorekoore.
Abdullahi tun sọ pe iwadii awọn tun fi han pe Kyari n lo awọn mọlẹbi rẹ lati maa lo awọn akaunti ọhun.
O ni N661,464,601.50 ni iwadii fi han pe o wa ninu awọn akaunti mẹrin naa lorukọ Kyari.
Abdullahi ni wọn sọ ninu awọn akaunti naa pe ifilọlẹ iwe ati iṣẹ ajọ ti kii ṣe ti ijọba lawọn fawọn owo to n wọle sawọn akaunti naa ṣe.
Mo ṣetan lati jabọ iṣẹ iriju mi - Kyari
Ẹwẹ, ọga agba ajọ NNPCL tẹlẹ, Mele Kyari, ti sọ ṣaaju pe oun ko lọwọ ninu iwa ibajẹ tabi jibiti kankan nigba toun wa nipo adari NNPCL laarin ọdun 2019 si oṣu Kẹrin ọdun 2025 yii.
Kyari tun ni irọ ni iroyin to sọ pe ajọ EFCC mu oun lori ẹsun ṣiṣe $2.9bn to wa fun atunṣe ile ifọporọbi kumọkumọ.
Ọga agba NNPCL tẹlẹ sọ ninu ọrọ kan to fi lede loju opo X rẹ loṣu Karun un to kọja wi pe awọn eeyan kan lo fẹ ba orukọ oun jẹ.
Kyari ni oun nilo isinmi bayii lẹyin toun ti sin ilu fun bi ọgbọn ọdun.
''Mo le sọ pe mo ṣiṣẹ pẹlu ibẹru Ọlọrun gẹgẹ bii musulumi, nitori bi mi o ba jẹwọọ niwaju eeyan; mo maa jẹwọọ niwaju Ọlọrun Allah.
Nitori naa, mo ṣetan lati jabọ iriju mi lẹyin ti mo ti ṣiṣẹ sin ilu fun bii ọgbọn ọdun,'' Kyari lo sọ bẹẹ.
Ọrọ Kyari wa lara awọn eeyan ti ajọ EFCC n ṣe iwadii wọn lori owo ti ijọba ya sọtọ fun atunṣe ileeṣẹ ifọporọbi Naijiria.
Iwadii ti EFCC n ṣe da lori oṣiṣẹ NNPCL mẹrinla tẹlẹ atawọn mii to si wa nibẹ to fi mọ ọga agba meji ileeṣẹ ifọporọbi naa meji tẹlẹ.
Ṣaaju lọdun yii ni Aarẹ Bola Tinubu yan Bashir Ojulari gẹgẹ bii ọga agba NNPCL tuntun, ti o si tun yan Ahmadu Kida gẹgẹ bi alaga ajọ naa lati da ogo NNPCL pada.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















