Sunday Igboho: Lady K sọ ohun tó ojú rẹ̀ rí ní àtìmọ́lé àjọ DSS nílùú Abuja lẹ́yìn tí wọ́n gbe nílé Sunday Igboho
Oríṣun àwòrán, Koiki Media
Obinrin kan ṣoṣo to wa lara awọn mejila ti ajọ DSS ji ko lọ si Abuja nile Sunday Igboho, Ifeoluwa Amudat Babatunde ti ọpọ mọ si Lady K ti sọ nipa iriri rẹ loru ọjọ tawọn DSS kọlu ile Igboho lagbegbe Soka niluu Ibadan.
Iroyin ko to amojuba lọrọ ti Lady B sọ ninu fidio kan to fi si ori ayelujara laipẹ yii.
Lady K ni ori lo ko oun yọ lọjọ naa nigba tawọn DSS yabo ile Sunday Igboho ti wọn si da ibọn bolẹ.
- Ọ̀kùnrin to tú àṣírí ohùn Olóyè Sunday Igboho lórí fóònù ti bọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- Kéére o! Ìjọba tú òbìnrin kan ṣoṣo amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho tó kù láhàmọ́ DSS silẹ̀
- Wo bí wọ́n ṣe sin Ọba Satani pẹ̀lú ọkọ̀ àti orin tó fẹ́ràn jù
- Idán oríta nínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners Chapel, okùnrin kan kù gììrì mọ́ Bíṣọ́ọ̀bù Oyedepo lórí pẹpẹ ìwàásù
- Àtúntò Nàìjíríà ni mo tò fún o, ìdí tí ẹ ṣe ní láti gbọ́ sí àwọn tó ń jà fún Yoruba Nation lẹ́nu rèé - Sẹnetọ Olujimi
- Èmi àti ọmọ ẹgbẹ́ akọrin wa jọ yó ìfẹ́ ara wa ni - Pásítọ̀ ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábáni lòpọ̀
- Ta ni Ọba Sátánì tó fẹ́ ìyàwó 57 kó tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 74?
- 'Mi ò rí ọkùnrin bá lòpọ̀ fún ọdún kan gbáko lásìkò "lockdown" àmọ́ mo dán ǹkan wò'
''Ẹmi meji lo bọ sọnu lọjọ naa nigba ti ọpọ eeyan fara pa yana yana, emi gan an ti mo n sọrọ yii, Ọlọrun lo ko mi yọ.
Awọn sọja atawọn DSS kan ṣa deedee bẹrẹ si ni yinbọn ninu ile yii lai ṣẹ lai ṣe ohun kan kan.
Gẹgẹ bi sọrọ sọrọ, idi niyii ti mo fi bẹrẹ si ni ṣe afihan fidio bi wọn ṣe yinbọn nile Sunday Igboho loro ganjọ naa.
Mo wa gbee sori afẹfẹ ki gbogbo aye le mọ nkan to n ṣẹlẹ.
Mo fẹ ki awọn eeyan pe awọn ologun ti ṣe ikọlu sile Sunday Igboho, ibọn ti ba awọn ẹlomiran lapa, o ti ba awọn mii lẹsẹ.
Ni ago meji ku iṣẹju mẹwaa loru ti gbogbo eeyan ti sun tan lawọn ologun yii de ti wọn si ṣina bolẹ.
Nigba ti mo gbe sori afẹfẹ tan, ẹmi mi ko gbe mọ pẹlu iro ibọn to n dun lakọ lakọ, aya temi gan an n ja.
Mo bẹru pe ki ọta ibọn maa lọ wọ ile wa ba mi tori ṣe ni ọta ibọn n fo kaakiri inu ile naa.
Wọn le ni ọgọrun ti wọn wa sile Igboho, nibi ti mi sa pamọ si ni wọn ti wa ba mi pe awọn ti mu mi.
Mo tẹ le wọn jade kuro ninu yara ti mo wa, bi mo ṣe jade sita bayii ni wọn bẹrẹ si ni lu mi bi aṣọ ofi.
Wọn gba foonu mejeeji, wọn tun fi igi lu mi ki wọn to mu mi lọ si ibi ti wọn ko awọn yoku ti wọn ti mu sii.
Nibẹ naa ni wọn ti n wọ oku awọn eeyan nilẹ, wọn lu mi debi pe mo fi ẹsẹ ṣeṣe, mi o tii gbadun ẹsẹ naa di oni lẹyin ọpọ itọju ti mo ti gba.
Ọjọ 114 ni mo lo ni atimọle nigba ti wọn ko wa de Abuja.
Wọn sọ fun mi pe awọn ko ni fi mi silẹ maa lọ si ile nitori emi ni mo jẹ ki gbogbo eeyan mọ pe awọn lo ṣe ikọlu si ile Igboho lẹyin ti mo gbe sori afẹfẹ.
Wọn sọ fun mi pọnbele pe ninu ki awọn pa mi tabi ki awọn ran mi ni ẹwọn, mo gbọdọ mu ọkan nibẹ.
Pẹlu bi mo ti bẹ wọn to, wọn fiya jẹmi, wọn fun mi ni omi kẹmika mu, ẹwa ati raisi ti ko jina.
Wọn ti emi nikan mọ inu yara kan fun ọjọ 114 ninu ooru buruku.
Awọn DSS ni iya ẹṣẹ fidio ti mo ṣe ni mo n jẹ, iya to jẹ mi lọgba DSS, mi o ri iru rẹ ri.
Ṣugbọn awọn ọmọ kaarọ oo jiire ṣe atilẹyin fun mi, wọn gba agbẹjọro fun mi eleyii to ṣiṣẹ takun takun ti mo fi kuro latimọle.
Amọ, lati igba ti mo ti gba ominira, mi o gbadun pẹlu omi kẹmika tawọn DSS fun mi mu.
Mo ti nawo nawo lati tọju ara mi ṣugbọn n ko ti gbadun naa.
Mo tiẹ tun n gba oriṣiiriṣii ipe lori ago ti wọn n dunkoko mọ mi, mi o le rin ladugbo mọ.
Babatunde Abibat ti ọpọ mọ si Lady K to jẹ obinrin kan ṣoṣo ti ajọ DSS ko pọ mọ awọn ti wọn ko nilee ajijagbara Yoruba Nation, Sunday Adeyemọ ti gba itusilẹ bayii pẹlu ọkunrin kan ti wọn jọ wa lahamọ, Jamiu Noah Oyetunji.
Oríṣun àwòrán, Pelumi Olajengbesi
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available