Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Tuntun ti de o, ijọba Naijiria pe awọn ọmọ tọjọ ori wọn ko i pe mejidinlogun lẹjọ?
Haa, ki lẹṣẹ wọn?
Iwọde ebi n pa wa to waye loṣu kẹjọ ni wọn ni wọn kopa nibẹ, Wọn ni wọn ditẹ mọ’jọba
Ọjọ Ẹti, ọjọ kinni, oṣu Kọkanla, lawọn ọmọde naa foju kan kootu,
Awọn kan tiẹ daku ninu wọn bi mo ṣe gbọ.
Iyoku iroyin wa ni BBC.COM/YORUBA
Ile aṣofin ipinlẹ Oyo yi juwe ile fun alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun Oyo
Ee ti jẹ, ki lo ṣe?
Ọjọbọ ni awọn aṣofin sọ pe ki Olusola Oluokun fi isẹ silẹ naa nitori pe o ṣe fidio lori ayelujara lai wọ aṣọ
Wọn ni iwa rẹ doju ti ipo to wa
Ogun ṣẹ ko ni i gberi mọ lawọn eeyan Botswana n wi bayii o.
Lẹyin ti wọn bọ lọwọ ẹgbẹ oṣelu to ti n dari lati ọdun mejidinlọgọta sẹyin
Ìṣẹ́, oṣi, ebi ni wọn ni ẹgbẹ Botswana Democratic Party (BDP) ba de lati 1966
Ewo ni wọn waa dibo fun bayii?
