Donald Trump yan bàbá olówó, Elon Musk sípò àmójútó àtúntò àti ìjáfáfá ìṣèjọba l'Ámẹ́rikà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nilẹ Amẹrika, Donald Trump, ti kede baba olowo to ni ikanni X, Elon Musk, gẹgẹ bii ọkan lara awọn ti yoo ṣiṣẹ ninu ijọba rẹ.
Yatọ si Musk, Trump tun yan Vivek Ramaswamy, ti oun naa jẹ baba olowo gọbọi lati maa ba Musk ṣiṣẹ papọ.
Ileeṣẹ ti yoo ri daju pe ijọba ko ni fi owo ilu ṣofo, "Department of Government Efficiency" ni Trump yan Musk si, gẹgẹ bii ọkan lara awọn adari rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ pupọ ninu ohun ti ileeṣẹ naa yoo maa ṣe ati irufẹ agbara ti yoo ni, Musk funra ti sọrọ lori iyansipo naa ati ẹka ileeṣẹ ijọba ọhun.
Gẹgẹ bi ohun ti Musk sọ, ijọba ilẹ Amẹrika yoo wọ oko gbese lọ ti ko ba si ẹka ileeṣẹ ọhun.
O ni ileeṣẹ naa kii ṣe ọta ijọba awarawa amọ yoo gbogun ti awọn kudiẹ-kudiẹ to n mu iṣẹ ijọba falẹ.
Ninu atẹjade kan ti Musk pin loju opo X rẹ, eyii ti Sẹnetọ Rand Paul fi lede ṣaaju sọ pe ijọba Amẹrika na owo ti iye rẹ to $477,121 lati ṣe iwadii arun kogboogun lara ọbọ.
Musk ni ileeṣẹ naa yoo fopin si bi wọn ṣe n fi ọpọ owo ṣofo.
O fi kun pe gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe nileeṣẹ ọhun ni yoo maa wa lori ayelujara fun gbogbo araalu lati ri.
O pari ọrọ rẹ pe ileeṣẹ bii ọgọrun ti to lati ṣakoso ilẹ Amẹrika.
Lọwọ yii, nnkan bii irinwo ileeṣẹ ijọba pẹlu oniruru ẹka lo wa nilẹ ọhun.















