Bíṣọ́ọ̀bù ìjọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ lẹ́yìn tí àlùfáà rẹ̀ ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú àwọn ọmọdé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Biṣọọbu agba Canterbury ti kede pe oun yoo fi ipo oun silẹ lẹyin iroyin kan to fẹsun kan ọkan lara awọn alufaa abẹ rẹ pe o n ṣe aṣemaṣe pẹlu awọn ọmọde.
Iwadii kan ti wọn ṣe nipa ijọ ilẹ Gẹẹsi fi han pe o ye ki Justin Welby fi ẹjọ John Smyth sun ọlọpaa lẹyin to gbọ pe o n ṣe aṣemaṣe pẹlu awọn ọmọdekunrin lọdun 2013, amọ o kọ lati ṣe bẹẹ.
Ninu atẹjade kan, Welby ni akoko ti to fun oun lati gbe igbesẹ naa lẹyin ti oun kọ lati ṣe ohun to tọ lasiko ti ọrọ naa kọkọ to oun leti.
O ni “Mo gbagbọ pe ki n fi ipo mi silẹ ni ohun to tọ bayii, paapaa fun ijọ ilẹ Gẹẹsi.
“Mo gbagbọ pe igbesẹ mi yoo fi han pe ijọ ilẹ Gẹẹsi ko fa sẹyin ninu ilakaka rẹ fun ijọ ti abo wa fun awọn ọmọ ijọ.
“Bi mo ṣe n fi ipo mi silẹ yii, mo n ṣe bẹẹ pẹlu ibanujẹ ọkan fun awọn ọmọ ti wọn fọwọ kan lọna aitọ.”
Agbẹnusọ fun Keir Starmer to jẹ olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi sọ pe olootu ijọba faramọ igbesẹ alufaa naa, amọ awọn ti ọrọ naa kan gbọngbọn lo jẹ oun logun julọ.
Wayi o, yoo to oṣu mẹfa gbako ki wọn to le yan ẹlomiran dipo biṣọọbu naa.
Ọsẹ to kọja ni iwadii kan fi han pe ijọ ko gbe igbesẹ kankan lati fiya jẹ Smyth fun ohun to ṣe ṣaaju iku rẹ lọdun 2018.
Ninu iwe to kọ lati fi ipo silẹ, Welby sọ pe wọn sọ fun oun lọdun naa lọhun pe ọrọ naa ti to ọlọpaa leti ni ko jẹ ki oun tun gbe igbesẹ mii mọ.
O ni ohun itiju nla gbaa ni ọrọ na jẹ fun ijọ Ọlọrun nilẹ Gẹẹsi.
Ọkan lara awọn ti oloogbe naa fọwọ kan lọna aitọ, Mark Stibbe ti sọ pe igbesẹ to tọ ni Welby gbe bo ṣe kọwe fi ipo rẹ silẹ.















