Àyípadà ojú ọjọ́ ń dá kún bí epo ṣe ń dàpọ̀ mọ́ omi ní South Sudan

Obìnrn tó ń rìn nínú oko - Bentiu, South Sudan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Maura Ajak and Stephanie Stafford
    • Role, BBC Africa Eye
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Àwọn darandaran tó ń bu omi nínú omi adagún kan ní South Sudan mọ̀ nípa ewu tí omi náà jẹ́ fún ìlera wọn tí wọ́n bá mu ún.

“Omi náà dọ̀tí nítorí ilẹ̀ epo ni ibí yìí, kẹ́míkà wà nínú rẹ̀,” èyí ni ọ̀rọ̀ láti ẹnu olórí àwọn darandaran náà, Chilhok Pout.

Obìnrin kan, Nyatabah tó ń sin àwọn màálù ní ìlú Unity State tí ó kún fún epo rọ̀bì ṣàlàyé pé bí èèyàn bá mu omi náà ó máa ń mú èèyàn wúkọ́.

“A mọ̀ pé omi tí kò dára ni àmọ́ kò sí ibòmíràn tí a lè lọ, ọ̀fun ti fẹ́ gbẹ wá kú.”

Onímọ̀ ẹ̀rọ nípa epo rọ̀bì sọ fún BBC pé ẹ̀kún omi ń gbé àwọn ìdọ̀tí wọ orísun omi ní agbègbè náà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ní ìpínlẹ̀ náà ni omi wà lábẹ́ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn tí ẹ̀kún omi wáyé níbẹ̀ èyí tí àwọn onímọ sáyẹ́ǹsì fi orí rẹ̀ sọ àyípadà ojú ọjọ́.

David Bojo Leju sọ pé àdánwó ńlá ni ẹ̀kún omi jẹ́ àti pé àwọn ìdọ̀tí tó n jáde látara epo jẹ́ nǹkan ńlá tó ń ṣekúpa ọ̀pọ̀lọpọ̀ tó sì ń tàn ká ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Ilẹ̀ tí epo ti ba omi jẹ́

Oríṣun àwòrán, David Bojo Leju

Orílẹ̀èdè South Sudan ni orílẹ̀èdè tí wọ́n dá silẹ̀ gbẹ̀yìn ní àgbáyé, ó sì wà lára àwọn orílẹ̀èdè tí ìṣẹ́ àti òṣì ń bá fínra bí ó ṣe jẹ́ pé epo rọ̀bì ni ìjọba orílẹ̀ èdè náà gbára lé.

Unity State, ìpínlẹ̀ tó kún fún epo rọ̀bì, ni ẹ̀kún omi máa ń wáyé níbẹ̀ loòrè kóòrè. Ní ọdún 2019 ni ó burú jùlọ nígbà tí òjò àrọ̀rọ̀dá gba ilé àti oko tó fi di pé àwọn ẹ̀kún omi náà sodo sábẹ́ àwọn iyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣe sọ, lọ́dún 2022 ni ìṣẹ̀lẹ̀ peléke jùlọ tó sì jẹ́ pé ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ìpínlẹ̀ Unity State ló wà lábẹ́ omi àti pé ìdá ogójì ilẹ̀ orílẹ̀ èdè náà lò ṣì wà lábẹ́ omi ní ìpínlẹ̀ náà báyìí.

Ọ̀gbẹ́ni Bojo Leju ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ epo Greater Pioneer Operating Company (GPOC), iléeṣẹ́ tó jẹ́ àjọṣepọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀ Malaysian, Indian àti China tí ìjọba South Sudan sì ní ìdókoòwò ìdá márùn ún nínú rẹ̀.

Lẹ́yìn tí ọ̀pá epo kan bẹ́ lọ́dún márùn ún sẹ́yìn, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkójọ àwọn fídíò àti fọ́tò àwọn omi tó kún fún epo àti ilẹ̀ dúdú ní ìpínlẹ̀ Unity State tó fi mọ́ Roriak níbi tí àwọn darandaran ń gbé.

Ó ní bí epo ṣe máa ń dàpọ̀ mọ́ omi jẹ́ nǹkan tó máa ń wáyé léra wọn àti pé òun wà lára àwọn tó máa ń kó iyẹ̀pẹ̀ kúrò ní ojú ọ̀nà kí wan má ba à ri.

Ó ní òun sọ àwọn nǹkan tó ń kọ òun lóminú fún àwọn alákoso iléeṣẹ́ àwọn àmọ́ díẹ̀ ni nǹkan tí wọ́n ṣe sí wọn.

Bojo Leju tún fi kun pé àwọn omi tí wọ́n máa ń dà sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fa epo kúrò níbẹ̀ ni wọn kìí ṣe ìtọ́jú rẹ̀ dada.

Ọkùnrin kan tó ń rìn ní Roriak, South Sudan
Àkọlé àwòrán, Àwọn darandaran ní omi ń pa awọn màálù àwọn

Àwọn ìròyìn nípa bí epo ṣe máa n wà nínú àwọn omi jù bí ó ṣe yẹ lọ ló máa n jẹ jáde nínú àwọn ìpàdé wa ní ojoojúmọ́ tó sì jẹ́ pé àwọn omi yìí ni a máa ń dà sí àyíká padà.

“Ìbéèrè ni pé níbò ni àwọn omi yìí ń lọ?

“Padà sínú odò táwọn èèyàn ń mu àti ibi tí wọ́n ti ń pa ẹja. Ọ̀pọ̀ àwọn omi inú ike ni kò dára fún mímu.”

Nígbà tí òjò ńlá bẹ̀rẹ̀ ní ọdú 2019, wọ́n da àwọn kẹ́míkà kan sí ibi tí epo rọ̀bì dà sí àmọ́ omi náà pọ̀ jù ú lọ.

Ní Roriak, kò sí àkọ́ọ́lẹ̀ nípa bí omi tí àwọn darandaran ń mu ṣe dára tó ṣùgbọ́n wọ́n wà nínú ìbẹ̀rù pé omi náà ń mú kí àwọn màálù wọn máa ṣe àárẹ̀.

Wọ́n ní àwọn màálù àwọn ti ń bí ọmọ tí kò lórí tàbí ọwọ́.

Mínísítà fétò ọ̀gbìn fún Unity State di ẹ̀bi àwọn màálù ẹgbẹ̀rún ọgọ́rùn ún (100,000) ní ọdún méjì sẹ́yìn ru ẹ̀kún omi pẹ̀lú epo.

Àwòrán bí ilẹ̀ ṣe rí

Ní igbó kan tó súnmọ́ Roriak, àwọn ọkùnrin kan àti obìnrin ń gé igi láti fi ṣe èédú. Wọ́n rìn fún wákàtí mẹ́jọ láàárín omi tó dọ̀tí kí wọ́n tó dé ibi ti wọ́n ń lọ.

Wọ́n ní omi tó ti dàpọ̀ mọ́ epo nìkan ni àwọn le rí ní agbàgbè náà.

Obìnrin kan, Nyakal sọ pé kò sí bí awọn ṣe lè se omi náà tó ó máa ń fa ìgbẹ́ gbuuru àti inú rírun.

Ẹlòmíràn, Nyeda tó ń gbé ní ẹ̀bá olú ìlú ìpínlẹ̀ náà, Bentiu ní omi tó dára ṣọ̀wọ́n àti pé aṣọ fífọ̀ àti iná dídá nìkan ni òun máa n fi omi tí àwọn bá pọn lẹ́nu kọ̀ǹga dẹ̀rọ ṣe àmọ́ àwọn máa ń ra omi múmu ni.

Nyeda
Àkọlé àwòrán, Nyeda fi àwọn ọmọ rẹ̀ méje sílé láti lọ dáko èédú

Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera àtàwọn olóṣèlú sọ fún BBC pé àìsí omi tó ṣe é bùmu bùwẹ̀ ń ṣe àkóbá fún ìlera àwọn èèyàn.

Ní ilé ìwòsàn kan ní Bentiu, ìyá kan bí ọmọ tí imú àti ẹnu rẹ̀ já papọ̀.

Dókítà Samuel Pout, ọ̀kan lára àwọn dókítà tó ń tọ́jú ọmọ náà ní wọn kò ní àǹfàni sí omi tó dára àti pé omi tó ti dàpọ̀ mọ́ epo ni wọ́n máa ń mu àti pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ibẹ̀ ni ìṣòro náà ti wọ́ wa.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ni wọ́n ti bí pẹ̀lú ìpèníjà kan tàbí òmíràn bíi orí kékeré tàbí àiní ọwọ́ tó sì jẹ́ pé àwọn ọmọ náà máa ń jáde láyé láàárín ọjọ́ sí oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá bí wọn.

Dókítà Pout ń fẹ́ kí ìjọba máa ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó bá ti wáyé.

Àwòrán ọmọ tí imú rẹ̀ já papọ̀ pẹ̀lú ẹnu rẹ̀
Àkọlé àwòrán, Àwọn ẹbí ọmọ yìí ń gbé ní agbègbè tí omi ti dàpọ̀ mọ́ epo

Dókítà Nicole Deziel, onímọ̀ ìlera nípa àyíká sọ pé epo tó ń bá àwọn nǹkan àyíká jẹ́ le dákún àwọn tó ń ìnira lásìkò ìbímọ.

Àwọn kẹ́míkà kan tí wọ́n máa ń jáde lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe epo le ṣàkóbá fún bí oyún ṣe le dàgbà.

Ìjọba ti ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ kan láti ṣàyẹ̀wò ipa táwọn epo náà ń ní àmọ́ wọn kò ì tíì fi àbájáde wọn léde lẹ́yìn ọdún kan táwọn èèyàn ti ń retí rẹ̀.

Mary Ayen Majok tó jẹ́ àgbà olóṣèlú látinú ẹgbẹ́ òsèlú tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ ti ń fi ìkọnilóminú hàn lórí ipa ti epo ń ní lát bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.

Igbakejì olori ilé aṣòfin ní South Sudan ni Majok ṣàlàyé pé ọ̀kan lára ìbátan òun bí ọmọ tó ní ìpéníjà ara. Ó ní òun gbàgbọ́ pè ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kojú ìṣòro bẹ́ẹ̀ àmọ́ tí wọn kò lè sọ̀rọ̀ nítorí ìbẹ̀rù ojú tí àwọn èèyàn yóò máa fi wò wọ́n àti àìrí ètò ìlera tó pójú owó.

Ó ní South Sudan jogún ẹ̀ka tí kò dára nígbà tí wọ́n dá orílẹ̀èdè náà sílẹ̀ lọ́dún 2011 lẹ́yìn tí wọ́n gba òmìnira lọ́wọ́ Sudan.

Àwọn obìnrin tó ń ṣe èédú ní Roriak sọ pé àwọn máa ń se omi kí àwọn tó mu ún àti pé ó máa ń mú àwọn ṣe àárẹ̀ síbẹ̀ náà
Àkọlé àwòrán, Àwọn obìnrin tó ń ṣe èédú ní Roriak sọ pé àwọn máa ń se omi kí àwọn tó mu ún àti pé ó máa ń mú àwọn ṣe àárẹ̀ síbẹ̀ náà

Bojo Leju sọ pé tí èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ nípa epo rọ̀bì, níṣe ló dàbí ìgbà tí èèyàn bá tọwa bọ ọkàn ìjọba ni.

Ó bá BBC sọ̀rọ̀ ní Sweden tó sálọ sí. Ó ní ọdún 2020 ni àwọn agbẹjọ́rò láti South Sudan tí wọ́n fẹ́ gbé ìjọba lọ sílé ẹjọ́ kàn sí òun láti wá jẹ́rìí.

Àmọ́ ó ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò fi òun sí àhámọ́, la ìbọn mọ́ òun lórí, tí wọ́n sì mú òun ní tipátipá láti tọwọ́bọ ìwé àdéhùn.

Látii ìgbà náà ló ti sá kúrò ní South Sudan. Àwọn agbẹjọ́rò náà kò ṣe ẹjọ́ náà mọ́.

BBC kàn sí iléeṣẹ́ GPOC láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n àmọ́ wọ́n kọ̀ láti fèsì.

David Bojo Leju

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò ní mọ̀ bóyá ẹ̀kúnwọ́ omi Unity State yóò dáwọ́ dúró.

Níṣe ni ojú ọjọ́ ní South Sudan tún ń gbóná si tí ìrètí sì wà pè yóò tún gbóná ju bó ṣe wà lọ.

Ó túmọ̀ sí pé àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ náà kò ní ṣe é gbé.

Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìbẹ̀rù ẹ̀kúnwọ́ omi àti epo tó ń dàpọ̀ mọ́ omi yìí, ọ̀pọ̀ ló ní ìrètí pé àwọn máa padà sí ìgbé ayé tí wọn yóò le máa sin ẹran wọn pẹ̀lú ìrọrùn.

Máàpù tó ń ṣàfihàn Roriak, Bentiu àti ibùdó táwọn èèyàn tí kò nílé ń gbé ní Unity State, South Sudan