Báyìí ni wọ́n ṣe búra fún gómìnà tuntun ní ìpínlẹ̀ Edo, Monday Okpebholo

Oríṣun àwòrán, Others
Monday Okpebholo ni wọn ti bura fun gẹgẹ bii gomina tuntun fun ipinlẹ Edo, eyi to fopin si ọdun mẹjọ iṣejọba Godwin Obaseki.
Ayẹyẹ naa waye ni lọjọ Isẹgun ni paapa iṣere Samuel Ogbemudia niluu Beninh, to olu ilu ipinlẹ Edo lẹyin oṣu meji ti ẹgbẹ oṣelu APC gbe igbaroke ninu eto idibo.
Bakan naa ni wọn tun bura fun Dennis Idahosa gẹgẹ bii igbekeji Gomina ipinlẹ Edo.
Ninu ọrọ rẹ Okpebholo dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Edo fun atilẹyin wọn lori aṣeyọri rẹ, to si ni ijọba awarawa ti gbe igbaroke.
“Ẹ jẹ ki n bẹrẹ pẹlu ki n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aanu ati ibukun rẹ. Ijọba awarawa ti gbe igbaroke,” Gomina ṣalaye.
“Lonii, ẹ ti fun mi niu oore ọfẹ lati tukọ ipinlẹ wa fun ọdun mẹjọ, A ko ni da igbekẹle ti ẹ ni ninu emi ati igbakeji Rt Hon Dennis Idahosa. Igbayegbadun araalu ni yoo jẹ wa logun.”
Bakan naa lo se ileri pe o yoo mojuto eto aabo nipinlẹ, ti yoo sis e gbogbo ohun to tọ lati se alekun ọrọ aje ipinlẹ naa.
Ayẹyẹ naa ni ọpọ eekan eeyan wa ni jokoo bi Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima, ẹni to soju Aarẹ Bola Tinubu, awọn gomina, Ọmọ ile igbimọ aṣofin ati awọn eeyan mii.
Ajọ eleto idibo INEC kede Okpebholo Monday oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo gomina ipinlẹ Edo to waye lọjọ Abamẹta tii ṣe ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹsan an ọdun 2024 yii.
Ọgbẹni Monday la oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Asue Ighodalo mọlẹ pẹlu 291,667 si 247,274 lati wọle ibo naa.
Oludije ẹgbẹ oṣelu LP, Olumide Akpata lo ṣe ipo kẹta ninu eto idibo naa pẹlu ibo 22,763.

Oríṣun àwòrán, Others

Oríṣun àwòrán, Others















