Òṣìṣẹ́ tí kò bá ní nọ́mbà ìgbélùú kò ní gba owó oṣù - ìjọba Kwara

Oríṣun àwòrán, realaarahman/Instagram
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ti kéde pé òṣìṣẹ́ tó bá kọ̀ láti fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àjọ Kwara State Residents Registration Agency (KWSRRA) kò ní gba owó oṣù Kọkànlá.
Kọmíṣánnà fétò ìsúná ìpínlẹ̀ Kwara, Dókítà Hauwa Nuru nínú àtẹ̀jáde kan ní òṣìṣẹ́ ìjọba Kwara tí kò bá ní nọ́mbà ìdánimọ̀ KWSRRA kò ní gba owó oṣù àti àjẹmọ́nú fún oṣù Kọkànlá.
Ní oṣù Keje, ọdún 2024 ni ìjọba gbé ètò kan kalẹ̀ pé kí gbogbo àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Kwara lọ fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àjọ KWSRRA.
Ìjọba Kwara í èyí yóò fún àwọn ní àǹfàní láti mọ bí àwọn yóò ṣe mójútó ọrọ̀ ìpínlẹ̀ náà tí yóò fi karí tẹrú tọmọ àti pàápàá láti mójútó ìpèsè ààbò.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ tó ń rí ètò ìsùná Kwara, Babatunde Abdulrasheed nínú àtẹ̀jáde tó fi léde lórúkọ Kọmíṣánnà lọ́jọ́ Ajé ní ó pọn dandan fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ láti kópa nínú ètò ìforúkọsílẹ̀ náà.
Bákan náà ni wọ́n ní ètò yìí kò yọ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà sílẹ̀, pé kí wọ́n ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú KWSRRA tí wọ́n bá fẹ́ gba owó oṣù wọn.
“Ṣíṣe ìforúkọsílẹ̀ pẹ̀lú KWSRRA jẹ́ ìgbésẹ̀ láti ní ìmọ̀ kíkún nípa àwọn èèyàn tó wà ní Kwara àti láti lè pèsè àwọn àǹfàní fáwọn èèyàn dáadáa.”
Kọmíṣánnà náà fi kun pé gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tí kò ì tíì fi orúkọ sílẹ̀ nílò láti lọ sí ibùdó ìforúkọsílẹ̀ KWSRRA ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n là kalẹ̀ fún wọn.
Ẹ̀wẹ̀, àjọ KWSRRA ni àwọn ti ya ọjọ́ méjì sílẹ̀ ìyẹn ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹtàlá àti ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2024 fáwọn òṣìṣẹ́ tí kò forúkọsílẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ láti lọ ṣe bẹ́ẹ̀.
Àtẹ̀jáde kan tí ọ̀gá àgbà àjọ KWSRRA fi léde ní kí àwọn òṣìṣẹ́ tó bá fẹ́ fi orúkọ sílẹ̀ láwọn ọjọ́ yìí lọ sí gbọ̀ngán Banquet Hall tó wà ní òpópónà ilé ìjọba ní ìlú Ilorin, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.
Ní aago mẹ́wàá òwúrọ̀ ni wọ́n ní ètò náà máa bẹ̀rẹ̀ láọn ọjọ́méjéèjì náà.















