Boko Haram Insurgency: Ẹ̀yin oníròyìn ẹ rọra máa pariwo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa àwọn adigunjalè, ẹ ń kóbá iṣẹ́ agbófinró - Àjọ NBC

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ajọ to n ri si igbohunsafẹfẹ ni Naijiria ti paa laṣẹ fun awọn ileeṣẹ mohunmaworan ati rẹdio lati ma maa tu gbogbo ẹkunrẹrẹ nipa awọn adigunjale atawọn ajinigbe sita mọ ninu iroyin wọn.
Aṣẹ naa sọ wipe ki wọn ye maa pariwo ninu atupalẹ awọn iwe iroyin ti wọn ba n ṣe nipa iṣẹ ibi awọn agbesunmọmi. Eyi ti wọn ni o ti di aṣa awọn tẹlifisan ati rẹdio laraarọ ṣaaju akọja eto wourọ wọn.
Ninu lẹta ti wọn kọ jade ọhun eyi ti oludari ẹka imojuto wọn, Francisa Aiyetan buwọlu lorukọ oludari agba ajọ NBC, Balarabe Ilelah, o ka pe:
"Ọpọlọpọ akọle awọn iwe iroyin olojoojumọ lo kun fun awọn ọrọ aabo. Bo tilẹ jẹ pe mimu iroyin ọrọ aabo wa si eti igbọ awọn ọmọ Naijiria, wọn ni lati ko ara wọn nijanu tori ọpọ ẹkunrẹrẹ ti wọn n fi sita lee ni ipa buruku lori akitiyan awọn oṣiṣẹ eleto aabo to jẹ pe iṣẹ tiwọn gan ni lati mojuto ọrọ aabo".
Ajọ naa wa rọ awọn oniṣẹ iroyin lati pawọpọ pẹlu ijọba lati koju ipenija aabo tonipa:
"Ki wọn ma maa fọn gbogbo iṣẹ awọn agbesunmọmi, adunkoko mọni, ajinigbe atawọn adigunjale agbebọn ati bẹẹ bẹẹ lọ sita.
"Ki wọn maa gba awọn alejo tabi alalaye lori eto wọn nimọran lati ma jẹ ki ọkan awọn araalu kun fun ibeere ipinya lọna ati ṣalaye ohun ti wọn ba n gbe yẹwo".
- Chidinma ò gbudọ̀ kú o sátìmọ́lé Ọlọ́pàá o! Àwọn aṣòfin f'ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Ìwọ́de tí apá ọlapáà ò ní ká ń bọ̀ l'Eko tí wọn bá kọ̀ láti fi àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- Ṣé ìwọ mọ ìtàn Ọdẹ tó tẹ Ẹ̀pẹ́ dó láti ìgbà ìwásẹ̀?
- 'Restructuring' la fi ta Buhari fún ìran Yorùbá, ṣùgbọ́n ó dùn mi pé irọ́ ni Buhari pa- Olagunsoye Oyinlola
- Títí di bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, èmi gan an kò mọ irú ẹni tí Wole Soyinka jẹ́- Ojọ̀gbọ́n Wole Soyinka
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Wo bí o ṣe le fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ tàbí gba ọ̀rọ̀ lórí WhatsApp láì lo fóònù rẹ
Ajọ naa tun ran awọn oniroyin leti pe ki wọn maa tẹle alakalẹ ofin NBC to sọ pe:
"Oniroyin ko gbudọ gbe ohun to lee tu ilu ka jade lori afẹfẹ tabi to lee dẹru ba awọn araalu tabi fa ipinya".
"Ninu ṣiṣe iroyin to lọ mọ aawọ, oniroyin yoo ṣiṣẹ gẹgẹ bii olulaja nipa gbigbọ tihin ati tọhun yekeyeke lai fi sibikan".
O ti le lọdun mẹwaa ti Naijiria ti n ba ipenija aabo yi paapaa lapa Iwọ Oorun -Ariwa ti Iwọ Oorun Afirika.
Ọpọ igba ni ijọba apapọ ti ni awọn ti bori ikọ Boko Haram amọ sibẹ sibẹ, ipaniyan, ijinigbe ati igbesunmọmi ko dopin.
Ni ida keji naa, asiko aarẹ Muhammadu Buhari nipasẹ agbẹnusọ iṣejọba yii, Minisita Lai Muhammed laipẹ yii ti gbiyanju lati fi oniruuru ọna dari iṣẹ awọn oniroyin nipa bi wọn ṣe ni ki ile aṣofin ṣe atunṣe awọn ofin to ba iroyin wi eyi ti awọn ti ọrọ kan naa lẹka iroyin si yari patapata eleyii to gbode kan ti wọn pe ni "information blackout". Eyi tun waye laipẹ ti ijọba kede gbigbẹsẹle lilo oju opo Twitter fun ọrọ kikọ tabi wiwa iroyin lorilẹede Naijiria.

















