Ibadan NTA Tanker explosion: Ọkọ̀ méjì jóná ráùráú níbi tí ọkọ̀ tó gbé bẹntiróò ti gbiná ní Ibadan

Ọkọ agbepo kan to kun dẹmu dẹmu ti yọ lori titi to si gbana ni olu ilu ipinlẹ Oyo lỌjọbọ,
Adugbo NTA lopopona Bus Stop ni ijamba ina yi ti ṣẹlẹ.
Ina to sọ latara ibugbamu epo inu ọkọ yi ṣokunfa bi ọkọ meji kan ti wọn wa lagbegbe naa ṣe jona raurau.
Ọga ileeṣẹ panpana nilu Ibadan Ismail Adeleke to fi ọrọ yi lede sọ pe ohun ati awọn oṣiṣẹ panapana ko fi ọrọ falẹ ti wọn si sare lọ sibẹ lati pa ina naa.
Gẹgẹ bi alaye to ṣe, o ni niṣe ni ina naa bẹrẹ lati inu ẹnjini ọkọ naa lasiko ti awakọ n wakọ lọ.
Ibẹrubojo to de ba pẹlu bo ti ṣe ri ina yi lo mu bẹ jade kuro ninu ọkọ.
''Ọkọ naa yọ lori titi to si da epo inu rẹ silẹ.Bi epo ṣe n danu ni ina naa n tọ lẹyin.Ọkọ meji jona ninu iṣẹlẹ yi ṣugbọn ẹmi kankan ko bọ''
Kaakiri loju opo ayelujara lawọn eeyan n ṣe alabapin fọnran fidio ina yi lasiko to n jo.
Amọ ọga panapana tẹsiwaju pe nigba ti yoo fi di ago mọkanla awọn ti ribi pa ina naa tanyanyan.
















