Ṣé lóòtọ́ ni Iyabo Ojo ti di ìyàwó Igbo? Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí òun fúnrarẹ̀ wú jáde

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo/Instagram

Gbajugbaja oṣerebinrin, Iyabo Ojo ti kede pe oun ti ni ololufẹ tuntun, to n mu inu oun dun, mu ayọ oun kun.

Ọjọ diẹ sẹyin ni Iyabo kọkọ kede iroyin ayọ naa fun awọn ololufẹ lori ayelujara Instagram rẹ̀.

Ninu fidio kan to fi sita, lo ti dupẹ lọwọ ọkunrin ọhun pe o ṣeun to nifẹ oun pupọ, to si tun n mu ki inu oun dun, ki ara oun ya gaga.

O ni “o ga o! Ọmọbinrin ẹya Yoruba yii ti pada fi ọkan rẹ fun ọkunrin ẹya Igbo.”

Lati asiko naa ni awọn ololufẹ arẹwa oṣerebinrin naa ti n ki i ku oriire.

O ṣeeṣe ki ọpọlọpọ o ma gbagbọ pe iya ọlọmọ meji ọhun ti igbeyawo rẹ akọkọ forsiṣanpọn, tun ti ni ololufẹ mii.

Amọ nigba to tun di ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ni Iyabo Ojo tun fi ọgbọn kede pe oun ti ni ololufẹ tuntun.

Ninu fidio iranti kan to fi sita lati ṣaami ọdun keji ti iya rẹ kú, ni Iyabo ti sọ pe o wu oun ko jẹ pe iya oun wa laye lati ri i pe ọmọ rẹ tun ti pada yo ifẹ lẹyin ọpọlọpọ ọdun.

“O wu mi ko jẹ pe ẹ ṣi wa nibi, lati ri i pe ọmọ yin obinrin tun ti yo ifẹ lẹyin ọpọlọpọ ọdun.

“Mo mọ pe nkan ti ẹ ma a sọ ni pe ṣebi mo sọ fun ọ pe o ṣi ma a ri ọkunrin ti wa a nifẹ.”

Iyabo ṣalaye pe nkan pataki julọ ti iya oun n fẹ fun oun ni lati pada ni ololufẹ.

Igbeyawo akọkọ ti Iyabo Ojo ṣe tuka

Iyabo Ojo ati ọkọ aarọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Other

Ipinya ti wa ninu igbeyawo iyawo Iyabọ Ojo lati ọjọ pipẹ, to si jẹ pe oun lo n da awọn ọmọ mejeeji naa tọ ni Naijiria.

Ọpọlọpọ igba ni oṣerebinrin naa ti sọ ni gbangba pe oun ko ju bi ọmọ ọdun mọkanlelogun nigba ti oun ṣe igbeyawo akọkọ.

Ṣugbọn igbeyawo naa ko pẹ pupọ ti oun ati ọkọ rẹ fi tuka ni ọdun 2001, lẹyin ti wọn bi ọmọ meji.

Oṣerebinrin naa sọ pe ọpọlọpọ nkan ni oun farada ninu igbeyawo naa ko to o di pe oun pinnu lati kuro nigba ti o kọja agbara.

Ni awọn asiko kan sẹyin, ni iroyin si ti jade pe o n fẹ awọn ọkunrin kan.

Ni ọdun 2021, iroyin jade pe Iyabo n fẹ Sẹnetọ nigba kan ri lati ipinlẹ Kogi, Dino Melaye.

Aṣiri ọrọ naa lu sita nigba ti ọrẹ timọtimọ rẹ nigba kan, Omo Brish, fi fọnran ohun kan sita lasiko ti aarin wọn daru.

Ninu fọnran naa ni iroyin sọ pe Iyabo ti n sọ fun Dino pe ko dẹ́kun lati ma a parọ ni gbangba pe awọn ko fẹ ara wọn.

Bakan naa lo tun kilọ fun Melaye ninu fnran naa pe oun yoo ṣẹ epe fun ti ko ba jawọ lati ma a fẹ akẹẹgbẹ oun, Biodun Okeowo.

Ṣaaju ni iroyin kọkọ jade ni ọdun 2020 pe Melaye ati Iyabo ti mu ọjọ igbeyawo wọn.

Bo tilẹ jẹ pe oṣerebinrin naa ko tii fi aworan ọkunrin tuntun to jẹ ololufẹ rẹ sita, tabi orukọ rẹ, awọn ololufẹ rẹ ti n ki i ku oriire.