Ìrìnàjò yóò bẹ̀rẹ̀ padà lójú ọ̀nà rélùweè Abuja si Kaduna

Oríṣun àwòrán, nrc
Ajọ to n mojuto eto irinna ojurin ni Naijiria, NRC, sọ pe irinajo yoo bẹrẹ pada ni oju ọna irin Abuja si Kaduna, lọjọ Aje.
Ikede naa jẹyọ ninu atẹjade kan ti oludari ajọ NRC, Ọgbẹni fidet Okhiria fi sita lọjọ Satide.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti sọ pe ọkọ oju’rin akọkọ yoo gbera kuro ni ibudokọ to wa ni rigasa nipinlẹ Kaduna, lọ si Abuja ni deede agogo mẹjọ owurọ.
Bakan naa ni ọkọ oju’rin mii naa yoo gbera ni ibudokọ Idu niluu Abuja lọ si Kaduna ni aago mẹwaa ku iṣẹju mẹẹdogun owurọ ọjọ Aje.
Awọn oludari ajọ NRC sọ pe lara eto aabo ti awọn ṣe ni pe dandan ni fun gbogbo arinrinajo to fẹ wọ reluwe, lati fi nọmba idanimọ NIN wọn han ni ibudokọ, ati tikẹẹti ti wọn ra.
Ninu oṣu Kọkanla ni ijọba ti kọkọ kede pe irinajo yoo bẹrẹ pada, ṣugbọn wọn tun pada sun siwaju.

Oríṣun àwòrán, nrc
Ajọ NRC da eto irinna oju’rin duro ni Kaduna si Abuja, lẹyin ti awọn agbesunmọmi kọlu ọkọ ojurin kan lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2022.
Awọn agbesunmọmi naa fi ado oloro ba oju ọna irin naa jẹ, ti wọn si tun ju ado oloro lu ọkọ ojurin to n lọ, ki wọn to bẹrẹ si ni yinbọn mọ awọn arinrinajo.
O le ni aadọjọ ti wọn ji gbe ninu wọn, ti wọn si pa eeyna mẹsan-an mii.
Ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni wọn fi awọn arinrinajo to kù si ahamọ wọn silẹ.














