Irọ́ lẹ pa, àwa kọ la ju àwọn ọmọ Naijiria sínú òṣì - Ẹgbẹ́ àwọn gómìnà

Oríṣun àwòrán, other
Awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria ti sọ pe iyalẹnu lo jẹ, bi minisita keji fun àtò ilu ati owo isuna, Clem Agba, ṣe fi ẹsun kan wọn pe awọn ni wọn ju Naijria sinu ìṣẹ́ àti òṣì.
Oṣu to kọja ni ajọ to n ri si onka ni Naijriia, sọ pe aadoje miliọnu eeyan to jẹ akuṣẹ, lo n gbe ni Naijria.
Eyi jẹ ida mẹtalelọgọta ninu ida ọgọrun gbogbo eeyan to n gbe ni Naijria.
Ọjọru to kọja ni minisita naa sọ fun awọn akọroyin, niluu Abuja pe owo ti ijọba apapọ na si ẹka yiyọ awọn eeyan kuro ninu oṣi, ko so eso rere, nitori pe awọn gomina ko fọwọsowọ pọ.
Ọgbẹni Agba sọ pe ‘awọn iṣẹ akanṣe nla’ ni awọn gomina sọ pe awọn n ṣe, dipo ki wọn o mu igbeaye idẹrun ba araalu to n gbe ni igberiko.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ awọn gomina fi sita, wọn ni ọrọ buruku to le da wahala silẹ ni minsita sọ.
Akọwe wn, Abdulrazaque Bello-Barkindo sọ pe irọ to jina si ootọ ni ọrọ naa, ti ko si lẹsẹ nilẹ rara.
Wọn ni ojuṣe ijọba ni lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu, amọ ijọba apapọ Naijiria kuna ninu eyi.
“Eyi lo mu ki awọn ajinigbe, agbebọn ati awọn agbesunmọmi sọ Naijriia di papa ipaniyan, ijinigbe ni ibi gbogbo.
“Nitori naa, awọn agbẹ ati oniṣowo ko raaye ṣe iṣẹ wọn daadaa, to si n yọri si airowo naa.”












