Yewande Oyediran: Kò sí ohun tó burú nínú bí Ajimobi ṣe dá Yewande tó pa ọkọ rẹ̀ sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @others
Yewande ni obinrin ti wọn fi ran lọ sẹwọn pe o pa ọkọ rẹ ni Ibadan tẹlẹ.
Alaga ẹgbẹ́ awọn agbẹjọro obinrin l'orilẹ̀-ede Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Oyo, Arabinrin Deborah Collins ti sọ fun BBC Yoruba pe ko si nkan to buru ninu igbesẹ ijọba.
O ni bi ijọba ipinlẹ Oyo l'abẹ iṣakoso Abiola Ajimobi ṣe da Yewande Oyediran to pa ọkọ rẹ silẹ ko buru nitori bi ọrọ naa ṣe jẹ.
Lopin ọsẹ to kọja ni iroyin gbe e pe gomina Abiola Ajimọbi da Yewande silẹ nigba to ku bi ọsẹ kan ti yoo kuro ni ipo gomina.
Yewande, to jẹ agbẹjọro ni wọn fi ẹsun kan pe o pa ọkọ rẹ, oloogbe Lowo Oyediran lọjọ keji, oṣu Keje, ọdun 2016 ni agbegbe Akobo, nilu Ibadan.
Ẹsun ti wọn ni Yewande fi kan ọkọ rẹ ni pe o ni ololufẹ ikọkọ, eyi to fa ede aiyede laarin awọn mejeeji, ko to o di pe Yewande fi ọbẹ gun ọkọ rẹ,eyi to pada yọri si iku.
Ṣaaju ọjọ naa ni Yewande ti fi sisọọsi gun ọkọ rẹ nitori ẹsun kan naa.
Ẹjọ naa dele ẹjọ, igbẹjọ rẹ si 'fihan pe ko mọọmọ pa ọkọ rẹ.'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin igbẹjọ naa ni Adajọ Munta Abimbola da ẹjọ ẹwọn ọdun meje fun un, ninu eyi to ti lo ọdun meji.
Iroyin idasilẹ Yewande fa awuyewuye lori ayelujara.
Ọpọ lo n sọ pe nitori o jẹ obinrin ni wọn ṣe da a silẹ.
Awọn miran sọ pe niroti pe awọn obi rẹ jẹ gbajumọ nipinlẹ Oyo ni. Bakan naa lawọn kan sọ pe nitori pe o jẹ agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Oyo ni.
Ninu alaye rẹ, alaga FIDA, Deborah Collins sọ pe ijọba ṣe nkan ti ofin fun un ni agbara lati ṣe ni.
"Kii ṣe Yewande nikan ni ijọba da silẹ, oun ati awọn ẹlẹwọn mi ti apapọ wọn kẹ ẹẹdẹgbẹta ni wọn da silẹ."
Kii ṣe pe mo n gba ẹnu rẹ sọrọ, ẹnikẹni lo le sọ niwaju ile ẹjọ pe mo ṣe nkan ti mo ṣe labẹ pe wọn mu inu bi mi. Kii ṣe pe boya tori o jẹ agbẹjọro tabi obinrin.
Ko si ẹni ti ijọba ko le da silẹ."
Collins ṣalaye pe dida ẹlẹwọn silẹ ṣaaju ọjọ to yẹ ko kuro, ko ni nkan ṣe pẹlu iye ọjọ to ti lo lẹwọn ayafi ti idajọ to gbe e de ẹwọn ba sọ pe iru ẹni bẹ ko ni anfaani si itusilẹ latọwọ ijọba.
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Ìlú ò rẹ́rìn ín rárá, Alaafin Adeyemi III fárígá fún Buhari nínú lẹ́tà tuntun
- Ọrọ̀ ajé Nàíjíríà tún leè dagun tí Buhari bá fi ìyànsípò àwọn mínísítà falẹ̀ si - Onímọ̀
- Ìjọba Nàìjíríà gbọdọ̀ ṣàlàyé ìdí tí 13.2m ọmọdé kò ṣe lọ sílé ẹ̀kọ́ - SERAP ké tọ iléẹjọ́ àgbáyé


















