Kylie Jenner ń gba 1.2m dọlà ni ìgbàkúgbà tó bá kọ ǹkan sórí Instagram rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Miliọnu kan dọla o le ni ilumọọka, Kylie Jenner n gba lati ile -iṣẹ Instagram nigbakigba ti o ba kọ nkan si oju opo rẹ.
Atẹjade tuntun kan lo gbe e jade wi pe oun lo n gbowo julọ ninu awọn ilumọọka lagbaye ni ọdun 2019.
Kylie to n ṣe aṣọ jade ni ọkanlelogoje miliọnu eniyan (141 million followers) to n tẹle e, ti owo si n wọle fun atẹjisẹ to ba kọ si awọn ọrẹ rẹ, tabi awọn ti oun tẹlẹ e ni ori ẹrọ ayelujara.
Awọn miran to n gba owo gọbọi ni Ariana Grande to n gba $966,000, nigba ti Cristiano Ronaldo n gba $975,000 fun igba kigba ti wọn ba ko nkan si oju opo Instagram wọn lẹẹkanṣoṣo.
Awọn mẹwaa to tẹlẹ wọn ni Selena Gomez, Dwayne 'The Rock' Johnson, Beyoncé, Taylor Swift, Neymarda ati Justin Bieber.
Amọ awọn eniyan miran ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu owo gọbọi ti awọn ilumọọka yii n gba.
Nigba ti awọn miran ni wi pe ko ṣe nkankan ati pe ko buru nitori awọn miran n gba owo lori iṣẹ ti wọn n se.










