Alakuko/Elega Schools: Aráàlú ní olùkọ̀ọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ti sá ní kíláàsì tí kò dára
Nibayii ti gbogbo agbaye n gbe eto ẹkọ larugẹ nitori ko si abuja mii lọrun ọpẹ lati de ibi giga, agbegbe meji ree nipinlẹ Kwara, ti akude n ba eto ẹkọ wọn.
Awọn agbegbe naa ni Iyana Alakuko ati Elega ti wọn wa nijọba ibilẹ Asa nipinlẹ Kwara, eyi to to kilomita mẹẹdogun silu Ilorin.
Ileewe kan soso lo wa ni Iyana Alakuko eyi tawọn ọmọ abule naa n lọ amọ awọn yara ikawe to wa nibẹ ko wu oju ri rara.
- O lè fi ₦50 jẹ rice, ẹ̀wa àti ẹran nílé òunjẹ mi kí o dẹ̀ wà OK- Maggi Rice
- Ṣé o le fi ọṣẹ tí wọ́n fi omi ara ìgbín ṣe fọ ojú?
- 'Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó lágbára jù wọ́n lọ lò ṣì ń wá iṣẹ́ nítorí náà kò dára tó'
- 'Ìjọba Kwara kàn fẹ́ fi ọ̀rọ̀ Hijab dá ìjà sílẹ̀ láàrin Krìstíẹ́ní àti Mùsùlùmí ni'
- Ìwádìí rèé nípa òrìṣà Ayélála, adájọ́ kíákíá tí kìí gba rìbá
- Ìjọba Buhari ti gbẹ́rù tó kọjá orí, bàtá tó bá ń ró lákọ fẹ́ ya ni!- Tunde Bakare
- Ọlọ́run fi ẹ̀mí Sunday Igboho ta gbogbo àwa tókù jí ni, ọ̀rọ̀ yìí ti kọjá ìsòpọ̀ Nàìjíríà - Oba Gbolahan Shomolu
Ori ilẹ ni awọn olukọ ati akẹkọ n joko si fun eto ẹkọ nitori pe wọn ko ni aga ati tabili ikẹkọ rara.
Koda yara ikawe oni yara meji naa lo wa fun awọn akẹkọọ lati ipele kinni de ikẹfa, ti awọn orule yara ikawe naa si ti lanu kalẹ.
Bakan naa ni ọmọ sori ni abule Elega nibi ti ileewe oni yara ikawe meji to wa nibẹ ti lanu kalẹ, to si ti fẹẹ da wo lulẹ.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Jesu Oyingbo rèé, pásítọ̀ tó láṣẹ ìbálòpọ̀ lóri ọmọ ìjọ obìnrin
- Igbó mímu lè ṣe kóríyá, kò lé fi kún orín ẹnu òṣèré - 9ice
- Ìtàn tó wà nídi òwe ‘Sebótimọ Ẹlẹ́wà Sàpọ́n’
- Ọba Adesoji Aderemi, Ọọ̀ni Ifẹ̀ tó gba ipò ọba mọ́ tòṣèlú
- MKO Abiola, iṣẹ́ aṣẹ́gità ló fi bẹ̀rẹ̀ okoòwò
- Iṣọla Oyenusi rèé, ẹnití ìfẹ́ obìnrin ṣun dé ìwà ìdigunjalè
- Taiwo Akinkunmi, ọmọ Ibadan tó ya àsìá Naijiria
Koda, ikan ti mu ọpọ orule to gbe awọn kilaasi naa ro eyi to lewu pupọ fun ẹkọ kikọ.
Nigba ti BBC Yoruba se abẹwo si awọn ile ẹkọ to wa ni abule Iyana Alakuko ati Elega, awọn olukọ ati araalu ni ọpọ olukọ ati akẹkọọ ni ko wa sile iwe mọ nitori ewu to wa nibẹ.
Wọn wa n rọ ijọba ipnilẹ Kwara lati dide iranwọ, ki awọn ile ẹkọ naa ma baa dẹnu kọlẹ tan patapata.




