Àwọn agbébọn tún ṣèkọlù sí Eruku ní Kwara, jí àgbẹ̀ kan gbé lọ lẹ́yìn ìkọlù ilé ìjọ́sìn CAC

Awọn agbebọn fasọ boju pẹlu ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn agbebọn tun ti ya bo ilu Eruku ni ijọba ibilẹ Ekiti ni Ipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti arakunrin agbẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ Annas Aasanru gbe lọ.

Loni ọjọ Aje ni agbẹnusọ ọlọpaa fun Ipinlẹ Kwara SP Adetoun Ejire-Adeyemi, fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC News Yoruba.

Ni ana ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ yii waye ni ilu naa, o si jẹ ẹlẹẹkeji iru ẹ ninu osu Kọkanla ọdun yii.

Ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin lawọn olujọsin 38 ti wọn ji gbe ni ilu ọhun gba ominira lakata ajinigbe.

Ijọba ipinlẹ Kwara ṣe itọju awọn eeyan naa lẹyin ti wọn lo ọjọ marun-un ni igbekun awọn ajinigbe.

Gẹgẹ bi eeyan kan lati ilu naa to ni ki a fi orukọ bo oun lasiri ṣe sọ, awọn agbebọn naa to jẹ mẹrin niye ya bo oko kan to wa lọna to jasi ilu Koro nibi ti wọn ti gbe agbẹ naa lọ.

O ni "awọn afurasi ajinigbe naa fi ada ati ibọn ṣe ikọlu si Aasanru ninu igbo to sa wọ.''

O sọ pe, ni ọjọ Aiku ni wọn fi to awọn ọlọpaa ilu Eruku, leti pe awọn agbebọn mẹrin tun ya bo Eruku, wọn si gbe ọkunrin kan, ẹni ogoji ọdun gbe lọ.

Ara ilu naa fikun ọrọ rẹ pe lẹyọ-osọka ni ajọ eleto abo ti ko awọn ọmọ ogun to fi mọ fijilante lọ si bẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ wi pe gbogbo ipa ni ọlọpaa n sa lati doola ẹni ti wọn ji gbe naa.