Àwọn gómìnà ílẹ̀ Yorùbá ṣèpàdé, béèrè fún àgbéga ẹkùn ìwọ̀ oòrùn, bí Sanwo-Olu ṣe ń ké tantan pé Yorùbá ló ni Eko

Àwọn gómìnà àti àgbààgbà nílẹ̀ Yorùbá to péjú síbi ìpàdé ìjíròrò ni Akure. Lára wọn ni igbákejì gómìnà ni ìpínlẹ̀ Ogun, Naimot Salako-Oyedele, gomina Babajide Sanwo-Olu, Oloye Bisi Akande, gomina ìpínlẹ̀ Ondo, Lucky Ayedatiwa.

Oríṣun àwòrán, Dawn Commission/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide San-Olu ti sọ pe ẹya Yoruba lo ni ipinlẹ Eko ati pe ipinlẹ naa ni aṣaaju ni Naijiria nigba ti awọn ipinlẹ mii n tẹle lẹyin.

Sanwo-Olu, to jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina nilẹ Yoruba, lo sọ ọrọ naa nibi ipade ẹgbẹ àwọn gómìnà naa, to waye niluu Akure.

Ajọ to wa fún ìdàgbàsókè ẹkùn ìwọ̀ Oòrùn Nàíjíríà, (Development Agenda for Western Nigeria, DAWN) ati ajọ kan to n wa ilọsiwaju ilẹ Yoruba, Afẹnifẹre, lo ṣagbatẹru ìpàdé náà.

Gomina ipinlẹ Eko sọ pe gbogbo ẹya to wa ni Naijiria ni ipinlẹ Eko gba lalejo gẹge bii ipinlẹ ti ọrọ aje ti milẹ julọ ni Naijiria.

Babajide Sanwo-Olu nibi ipade awọn gomina niluu Akure

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu

"Ilẹ Yoruba, ẹ má sọ ohun ti aye mọ yin mọ nu, eyii tii ṣe ẹkọ to yaranti, ọlaju ati ijọba rere"

Sanwo-Olu tẹsiwaju pé "Ipinlẹ Eko gbalejo gbogbo ẹya, ede ati ẹsin, paapaa julọ, àmọ́ o jẹ ipinlẹ apapọ ilẹ Yoruba."

Sanwo-Olu wa rọ ilẹ Yoruba ki wọn ma ṣe sọ ohun ti aye mọ wọn mọ nu, eyii tii ṣe ẹkọ to yaranti, ọlaju ati ijọba rere.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ilẹ Yoruba ni ọpọ n ri bii apẹrẹ ilọsiwaju ati idagbasioke ni Naijiria, o gbọdọ ji giri ko si gba ogo rẹ pada nipa gbigba alaafia ati irẹpọ laaye.

Ninu ọrọ rẹ, gomina ọhun lo ọrọ Aarẹ South Africa nigba kan ri to sọ pe ala lasan ni iran ọjọ iwájú lai si iṣẹ ṣiṣe jẹ.

Sanwo-Olu ni awọn adari nilẹ Yoruba ko kan gbọdọ maa ni iran nipa ọjọ iwaju nikan, wọn gbọdọ ṣiṣẹ fun ọjọ iwaju rere ti wọn n ni iran rẹ ọhun.

Àwọn èèkànlú nílẹ̀ Yorùbá àti ọba àlàyé to péjú síbi ìpàdé ní Akure nínú èyí tí Aláàfin tilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade wá.

Oríṣun àwòrán, Dawn Commission/Instagram

Awọn gomina ilẹ Yoruba beere fun idagbasoke agbegbe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nibi ipade naa to waye nilu Akure, ni apapọ awọn gomina naa ti pe fun idagbasoke agbegbe gẹgẹ bi ọna kan gboogi ti ilọsiwaju fi lede de ba Naijiria.

Ipade ọhun ti wọn pe ni 'Southwest Leaders' Dialogue ' ti gomina Lucky Aiyeatiwa gbalejo rẹ, ni wọn fi jiroro lori bi ilọsiwaju ati idagbasoke ilẹ Yoruba yo ṣe ya kankan.

Nigba to n sọrọ, gomina Aiyedatiwa ni ijọba gbọdọ ro eto oṣelu awarawa lagbara nipa awọn atunṣe to yẹ ati nipa ijiroro pẹlu awọn gomina.

Ni ti Sanwo-Olu, o ni awọn gomina agbegbe, paapaa nilẹ Yoruba, gbọdọ pawọpọ, ki wọn si fẹnuko lati jiroro lori bi idagbasoke yoo ṣe ba agbegbe naa labẹ iṣakoso wọn.

Gomina Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun, ti igbakeji rẹ, Noimot Salako-Oyedele, ṣoju fun sọ pé, ijọba awarawa yoo gberu si ti awọn adari ba ti ṣetan lati jiroro pẹlu awọn araalu.

Olori ẹgbẹ Aeniferem, Pa Reuben Fasoranti, ti sẹnetọ Femi Okunrounmu ṣoju fun, rọ awọn omina naa ki wọn gbe ibaṣepọ laarin gbogbo wọn leke ju eto oṣelu lọ.