EFCC dá ilé, ọkọ̀ àti dúkìá míì padà fún ẹni tí Abọrẹ̀ kan lù ní jìbìtì n‘Ibadan èyí tó lé ní ₦200m

Àwòrán ọkọ̀, ilé tí EFCC dá padà fún Attiogbe pẹ̀lú àwòrán Alli tó gb;e ère dání ní apá ọ̀tún

Oríṣun àwòrán, EFCC/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àjọ tó ń gbógúnti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, Economic and Financial Crime Commission, EFCC, ti gba àwọn ohun ìní bíi ilé mẹ́ta, ọkọ̀ bọ̀gìnì méjì àti owó tó lé ní mílíọ̀nù kan náírà lọ́wọ́ ẹnìkan tó pe ara rẹ̀ ní oníṣègùn, Fatai Olalere Alli, tí wọ́n tún ń pè ní Baba Abore tàbí Baba Osun.

EFCC nínú àtẹ̀jáde kan tó wà lójú òpó ayélujára wọn sọ pé àwọn ohun ìní náà ni àwọn ti dá padà fún ọkùnrin kan, Daniel Babatunde Attiogbe tí Baba Abore náà lù ní jìbìtì ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo.

Àtẹ̀jáde náà ní àwọn dá àwọn ohun ìní náà padà lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dájọ́ pé Alli jẹ̀bi ẹ̀sùn lílu Attiogbe ní jìbìtì owó tó lé ní igba mílíọ̀nù náírà (₦200m), tí ilé ẹjọ́ sì pàṣẹ pé kí dá àwọn ohun ìní náà padà fún-un.

Wọ́n ní Alli ní òun fẹ́ bá Attiogbe ṣe oògùn láti lé ikú òjijì dànù fún-un ṣùgbọ́n tó lù ú ní jìbìtì ọ̀bítíbitì owó.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Lára àwọn ohun ìní tí wọ́n ní kí wọ́n dá padà fún Attiogbe ni ilé ńlá, ilé alája méjì oní yàrá mẹ́fà tó wà ní Kasumu, Odo-ona Elewe, Ibadan, ilé onílẹ̀ kan tó ní yàrá mẹ́ta tó wà ní Plot 182, Block D, Lapiti Layout, Akanran Road, Amuloko àti ilé onílẹ̀ oní yàrá mẹ́ta tó wà ní Idi Ayunre, ìjọba ìbílẹ̀ Oluyole, ìpínlẹ̀ Oyo.

Bákan náà ni wọ́n tún ní kí wọ́n dá ọkọ̀ Honda Pilot SUV tó ní nọ́mbà àkọ́ọ́lẹ̀, Reg. No. LND 696 CK, Chassis No. 2HKY18414H621545 àti Toyota Corolla pẹ̀lú nọ́mbà àkọ́ọ́lẹ̀ Chassis No. 2T1BU40E49C142502 pẹ̀lú mílíọ̀nù kan náírà (₦1.1) padà fún ẹni Attiogbe.

Adarí ẹ̀ka EFCC ní Ibadan, Hauwa Garba Ringim ṣàgbékalẹ̀ àwọn ohun ìní náà fún Attiogbe lórúkọ alága àjọ EFCC, Ola Olukoyede.

Nígbà tó ń ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìwé ilé àti ọkọ̀ náà, Olukoyede tẹmpẹlẹmọ pé àjọ náà máa ń tẹ̀lé àwọn ìlànà tó tọ́.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Títẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́ jẹ́ ohun tó pọn dandan fún wa gẹ́gẹ́ bí àjọ ìjọba àpapọ̀ tí a sì mọ pàtàkì rẹ̀ – ohun tí à ń ṣe lónìí nìyẹn. Èyí ṣàfihàn pé EFCC máa ń tẹ̀lé àlàkalẹ̀ òfin lórí gbogbo àwọn ìṣe rẹ̀."

Ó fi kun pé EFCC máa tẹ̀síwájú láti kojú àwọn ọ̀daràn tí wọ́n ń lu èèyàn ní jìbìtì, kí wọ́n sì mú ìgbéga bá Nàìjíríà.

"A máa ri dájú pé àwọn oníjìbìtì tí wọ́n ń sọ Nàìjíríà ní orúkọ tí kò dára la máa fojú wọn winá òfin."

Nígbà tó ń gba àwọn ìwé ẹ̀rí náà, Attiogbe fi ìdùnnú hàn sí EFCC fún bí wọ́n ṣe mú ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ìdájọ́ orílẹ̀ èdè dúró ire.

Ó ní òun ti fẹ́ gbàgbé àwọn ohun ìní òun sọ́wọ́ oníjìbìtì náà àmọ́ EFCC dá ìrètí òun padà lẹ́yìn tí òun kọ ìwé ìpẹjọ́ sí wọn.

Gbígba àwọn dúkìá náà padà ló wáyé lẹ́yìn tí Adájọ́ Uche Agomoh tí ilé ẹjọ́ gíga Ibadan gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lọ́jọ́ Kẹtàlá, oṣù Kọkànlá, ọdún 2024 pé Alli jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án, tí wọ́n sì jù ú sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta.

Bákan náà ni wọ́n ní kó tọwọ́ bọ ìwé pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ pé òun kò ní lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn mọ́.

Aworan Abọrẹ to n lu eeyan ni jibiti, o wọ asọ ankara alawọ goolu ati dudu, o gbe sigidi, afọsẹ, ikoko kekere kan ati oku eku nla to ti gbẹ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, EFCC