Ìyàwó tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó pa ọkọ rẹ̀, tí wọn fipá fún ní omi ìwẹ̀ òkú ọkọ rẹ̀ mu, figbe ta

Aṣoju ijọba lori ọrọ naa ati awọn eeyan nile ti wọn ti huwa yii

Oríṣun àwòrán, Imo State Gov/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Aṣoju ijọba lori ọrọ naa ati awọn eeyan nile ti wọn ti huwa yii
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Laipẹ yii ni iroyin gbode nipa obinrin kan ti wọn fipa fun ni omi oku ọkọ rẹ lati mu, ni ilu kan ti wọn n pe ni Awo-Omamma, nijọba ibilẹ Oru, ipinlẹ Imo.

Chika Ndubuisi ni orukọ obinrin ti ọkọ rẹ ku naa, ti awọn ẹbi ọkọ si fẹsun kan pe oun lo pa ọmọ awọn.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn ẹbi ọkọ Chika ko fun un ni omi oku naa mu nikan, wọn tun fi ọlọpaa mu un pẹlu.

Wọn ni dandan ni ko jẹwọ fawọn pe oun mọ nipa iku ọkunrin naa.

Eyi ni awọn ara adugbo gbe de etigbọọ ijọba ipinlẹ Imo, nileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin, ti ọrọ naa si di ohun ti ijọba lọwọ si.

Ìjọba Imo bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀

Nigba to n ṣalaye nipa ohun ti ijọba ipinlẹ Imo yoo ṣe lori iṣẹlẹ yii, Kọmiṣanna fun ọrọ obinrin nipinlẹ naa, Nkechinyere Ugwu, koro oju si ohun ti awọn ẹbi ọkọ Chika ṣe fun un.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, ileeṣẹ ijọba naa ṣapejuwe iwa ti wọn hu bii eyi to buru jai.

Wọn fi kun un pe wọn yoo jiya ti ofin la kalẹ fun ẹni to ba ṣe iru eyi.

"Iwa yii buru jai, o lodi si ofin pẹlu nibikibi lagbaaye."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ijọba naa ka.

Kọmiṣanna fi kun un pe gbogbo ẹni to lọwọ si ifiyajẹni naa ni yoo foju ba kootu pata.

O ni ijọba Imo ki i fi ọrọ obinrin ṣe awada, debi ti awọn kan yoo maa da ofin ṣe lọwọ ara wọn.

Nipa Chika ti wọn fiya jẹ, ileewosan ni obinrin naa wa lọwọ, to n n gba itọju lori ilera rẹ ati iporuru ọkan ti wọn ko o si.

Ojú wo ni òfin fi wo ìwà ipá yìí?

Lati mọ oju ti ofin fi wo ki eeyan fipa mu ẹnikeji lati mu omi oku, BBC ba amofin kan lati ipinlẹ Enugu, Nnenna Anozie, sọrọ.

Amofin Anozie ṣalaye pe iwa to lodi sofin orilẹeede yii ni lati fi omi oku fun ẹlomiran mu.

O ni ajọ Violence against Persons Prohibition Law (VAPP-Law) wulẹ ti ni agbekalẹ ijiya fun ẹni to ba ṣe iru rẹ fun eeyan.

O fi kun un pe ofin Naijiria la ẹtọ kaluku kalẹ lai ruju, ẹnikẹni to ba kọja aala yoo si jiya labẹ ofin naa.

"Awọn to lọwọ si ifiyajẹni yii le lọ si ẹwọn ọdun marun-un, tabi ki wọn san owo itanran. "

Amofin Nnnena Anozie lo ṣalaye bẹẹ