Kí ni aáwọ̀ abẹ́nú tó ń lọ nínú ikọ̀ Amotekun l‘Ondo, tí àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́ta kan ṣe ń fi ẹ̀sùn àṣìlò ipò kan adarí àjọ náà?

Oríṣun àwòrán, Collage
Ẹnu ti bẹrẹ si n kun ajọ eleto abo Amotekun ipinlẹ Ondo bayii lẹyin to jawe ẹ lọ gbele yin fun mẹta ninu awọn oṣiṣẹ rẹ.
Amotekun ipinlẹ Ondo ti ṣe aṣeyọri fun ọpọ ọdun ni bi ọwọ rẹ ṣe maa n tẹ awọn afurasi ajinigbe, alọkolohunkigbe ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Amọ ẹnu ọjọ mẹta yii ni ẹnu bẹrẹ si n kun ajọ naa lori ayelujara lẹyin ti awọn oṣiṣẹ rẹ kan n bere ẹtọ wọn, eyii ti wọn ni ajọ naa fi n dun wọn.

Oríṣun àwòrán, Ekujumi Julius
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ
Nnkan bii ọsẹ melo kan ṣeyin ni fakinfa bẹrẹ laarin ajọ Amotekun ipinlẹ Ondo ati awọn oṣisẹ rẹ mẹta, kan ti wọn fi ẹsun aṣilo ipo kan adari wọn, Adetunji Adeleye.
Awọn eeyan naa ni Amotekun ko fun awọn ni iwe igbanisisẹ lati igba ti wọn ti gba awọn siṣẹ lati oṣu Kẹjọ, ọdun 2020, eyii to n tumọ si pe awọn ko lẹtọọ si awọn ajẹmọnu kan lati ọdọ ijọba.
Yatọ si awọn ọrọ wọnyii, wọn tun sọ awọn ọrọ mii, ti wọn si tun fi awọn ẹsun mii kan ajọ Amotekun ipinlẹ Ondo.
Awọn oṣiṣẹ Amotekun ti ọrọ naa kan ni Abu Taiwo, Akinsipe Victor, ati Ekujumi Julius.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Mo n wa ọkọ mi lati ọsẹ kan – Iyawo ọkan lara oṣiṣẹ Amotekun ti wọn le lẹnu iṣẹ pariwo
Wayi o, iyawo ọkan ninu awọn oṣisẹ Amotekun naa ti ṣe ifẹhonuhan niluu Akure, ninu eyii to ti ke si ijọba lati ba oun wa ọkọ oun to di awati.
Obinrin ọhun, to jẹ iyawo Victor Temitope Akinsipe (to jọ bii pe oyun wa ninu rẹ) nikan lo ṣe ifẹhonuhan naa loju ọna obiripo Shoprite to wa niluu Akure, ọna naa lo lọ si ọọfisi gomina ati olu ọọfisi ajọ Amotekun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọkọ oun kuro nile lẹyin to gba ipe lati ọọfisi Amotekun pe ko wa fun ipade laafia lẹyin gbọnmisi-omi-o-to to waye laarin oun atawọn alaṣẹ Amotekun, ṣugbọn lati akoko naa ni ọkunrin ọhun ti di awati.

Oríṣun àwòrán, Tope Tomekun
Awọn oṣiṣẹ mẹta fẹsun igbiyanju lati gbẹmi wọn kan Amotekun
Lori iroyin yii kan naa, agbẹjọro kan, Tope Temokun ti kọwe si ijọba ipinlẹ Ondo lori ẹsun pe awọn adari Amotekun fẹ gbẹmi awọn eeyan mẹta naa.
Ninu lẹta ti Tomekun kọ si Gomina Lucky Aiyedatiwa lọjọ kẹtadinlọgbọn, osu Kẹwaa, ọdun 2025 yii, o ni ẹtọ awọn eeyan naa ni wọn n beere lọwọ ijọba amọ awọn adari Amotekun n lepa ẹmi wọn.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, Akinsipe Victor Temitope, Ekujumi Julius ati Abu Taiwo ti na papa bora bayii lẹyin ti awọn kan ti wọn gbagbọ pe Adeleye bẹ lọwẹ n fi ibọn le wọn kiri igboro.
Lẹyin naa lo ke si gomina Aiyedatiwa ko ri daju pe nnkankan ko ṣẹlẹ si awọn eeyan naa.
Titi di asiko ti a n ko iroyinyi jọ, Adeleye tabi Amotekun ipinlẹ Ondo ko tii sọ ohunkohun lori ẹsun naa.

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ondo
Ki ni Adari Amotekun sọ nipa awọn osisẹ rẹ mẹtẹẹta naa?
Ẹwẹ, lẹyin ọpọlọpọ gbas-gbos lori ayelujara, Adari Amotekun Ondo, Adetunji Adeleye kede awọn eeyan naa gẹgẹ bii afurasi ti wọn n wa lẹyin to kọkọ jawe ẹ lọ rọọkun nile fun wọn.
Adeleye ni eredi igbesẹ naa ko ṣẹyin bi wọn ṣe n ba orukọ ajọ naa jẹ lori ayelujara.
O ni "Ti wọn ko ba ṣẹ si ofin, gbogbo aye yoo ri.
Amọ ko si ẹnikẹni to le maa ba orukọ ajọ wa jẹ lori ayelujara, lati ọwọ awọn to n da iṣẹ ara wọn jẹ.
Paapaa ni bayii ti a ti mọ pe awọn kan lo wa lẹyin wọn."
Bakan naa, Adeleye fikun pe
"A ti kede pe a n wa awọn osisẹ mẹtẹẹta naa, a si kọ lati jẹ ki wọn fa wa wọnu awuyewuye to rọ mọikọọkan wọn.
Ohun to da wa loju ni pe isẹ ara tiwọn ni wọn n da jẹ, digbi ni ikọ Amotekun duro.
Awa osisẹ ati adari ikọ naa ko si jẹ ki iwa ti awọn mẹtẹẹta n hu yii ko si oju wa kuro lori isẹ ta n se."












