Wo àkọ̀tun ìṣòro míì tó ń họjú mọ́ PDP, bó ṣe sún ìpàdé àpapọ̀ rẹ̀ síwájú

Asia oni awọ mẹta: awọ pupa, funfun ati eweko tii se ami idamọ fun ẹgbẹ iselu PDP ni ọpọlọpọ eeyan mu lọwọ

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni bayii to ku ọsẹ diẹ ki ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu PDP waye, ogiri ẹgbẹ naa ti n lanu, alangba si ti n raye wọle.

Idi ni pe aawọ abẹnu to n ba ẹgbẹ oselu naa finra tun n peleke si.

Lasiko yii, gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Jigawa, Sule Lamido, sọ pe, oun ko faramọ bi awọn kan ṣe kede Tanimu Turaki (SAN) gẹgẹ bii ẹni ti awọn n fẹ gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu naa lai dibo yan an.

Ọrọ naa ṣeeṣe ko da rogbodiyan silẹ ninu ẹgbẹ ọhun to bẹẹ ti wọn yoo gbe ara wọn lọ ile ẹjọ.

Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ti ẹgbẹ naa wọgile ayẹwo awọn to n dije du ipo to yẹ ko waye lọjọ Isẹgun, ṣaaju ipade gbogbogbo wọn niluu Ibadan.

Igbesẹ yii lo n waye ni nnkan bii oṣu kan, ki ipade gbogbogbo ẹgbẹ ọhun waye, eyii to mu ki awọn onwoye ohun to n lọ ninu ẹgbẹ alatako naa maa woye boya wahala tun mii tun ti n rugbo bọ ninu ẹgbẹ naa.

Maa gba ile ẹjọ lọ, ti wọn ko ba jẹ ki n ra fọọmu lati dije sipo alaga ẹgbẹ PDP ṣaaju ipade gbogbogbo - Lamido dunkoko

PDP ni igbesẹ lati wọgile ayẹwo naa waye latari awọn nnkan to n waye, kọja agbara awọn.

Ninu atẹjade kan lọjọ Aje, alaga igbimọ to n ṣeto ipade gbogbogbo ẹgbẹ naa, to tun jẹ gomina ipinlẹ Adamawa, Umaru Fintiri, sọ pe awọn yoo kede ọjọ tuntun ti ipade gbogbogbo naa yoo waye.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ilu Ibadan lo yẹ ki ipade gbogbogbo naa ti waye, eyii ti igbagbọ wa pe ọpọlọpọ awọn alẹnulọrọ ninu oṣelu Naijiria, bii gomina, sẹnetọ atawọn mii yoo peju si, ni imurasilẹ ẹgbẹ naa fun eto idibo Aarẹ ọdun 2027.

Lọjọ Aje ni gomina ipinlẹ Jigawa, to tun jẹ eekan ẹgbẹ PDP, Lamido dunkoko pe oun yoo gba ile ẹjọ lọ, ti wọn ko ba gba oun laaaye lati ra fọọmu awọn to fẹ dije sipo alaga ṣaaju ipade gbogbogbo naa ti yoo waye lọjọ karundinlogun ati ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 yii niluu Ibadan.

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja, lẹyin to kuna lati ra fọọmu naa, Lamido kilọ fun akọwe ẹgbẹ ọhun, Samuel Anyanwu ati ojugba rẹ, Umaru Bature, ki wọn mase da si ọrọ naa rara.

Nigba ti wọn n sọrọ, Anyanwu ati Bature sọ pe awọn ko tii ri fọọmu kankan ti wọn tẹ jade fun awọn to ba fẹ dije ni imurasilẹ fun ipade gbogbo ẹgbẹ naa.

Amọ ṣa, oludije ti awọn eeyan iha ariwa faramọ fun ipo alaga ẹgbẹ naa ti gba fọọmu tirẹ.

O si ṣeleri lati ṣe daadaa si gbogbo ọmọ ẹgbẹ ti wọn ba le dibo yan oun lasiko ipade gbogbogbo wọn niluu Ibadan.

Nyesom Wike wọ aṣọ ilẹ Gẹẹsi ati file

Oríṣun àwòrán, Nyesom Wike

Seyi Makinde àtàwọn gómìnà PDP ń kọ iyán mi kéré, ẹgbẹ̀ náà yóò wó lulẹ̀ - Wike

Ẹwẹ, minisita fun ọrọ FCT, Nyesom Wike, ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti di ile ti wọn kọ sori iyanri ti yoo wo lulẹ latari bi awọn gomina inu ẹgbẹ naa ṣe pa oun ti sẹgbẹ kan.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade kan niluu Abuja, o ni o ṣeni laanu pe awọn gomina inu ẹgbẹ ọhun ko iyan oun kere, wọn ko si fi ọrọ ẹgbẹ naa lọ oun mọ bo tilẹ jẹ eekan inu ẹgbẹ ọhun ni oun n ṣe.

O ni "Ṣe mi o ti sọ ṣiwaju pe koto ti ẹ gbẹ silẹ, pe ẹyin funra yin ni ẹ maa jin si? Iwa ti awọn gomina ẹgbẹ yii n wu lasiko yii ni yoo fa iṣubu ẹgbẹ oṣelu naa.

"Emi ni minisita fun FCT, ṣugbọn ẹ n sọ fun mi pe nitori mi o ki n ṣe gomina, ẹ maa ṣe ipade awọn alẹnulọrọ inu ẹgbẹ PDP amọ ẹ ko ni pe mi sibẹ, ẹ si ro pe ẹgbẹ naa ko ni ku."

Lẹyin naa lo ni ko si ootọ kankan ninu ọrọ ti awọn eeyan n sọ kiri igboro pe ẹgbẹ oṣelu APC lo n da rugudu silẹ ninu ẹgbẹ PDP.

O pari ọrọ rẹ pe ipade gbogbogbo PDP to yẹ ko waye amọ to n falẹ ko kan APC bi ko ṣe awọn funra wọn ti wọn ko ṣe awọn ohun to tọ ki wọn ṣe.