Ìgbá mẹ́fà tí wọn dá àwọn ìpínlẹ̀ sílẹ̀ ní Nàíjíríà àti ìtàn tó rọ̀ mọ́ ìdásílẹ̀ wọn

Maapu orilẹede Naijiria pẹlu orukọ awọn ipinlẹ

Oríṣun àwòrán, @kotosiaface17

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Igbimọ to n ṣe agbẹyẹwo ofin nile igbimọ aṣofin Naijiria ti fẹnuko lati da ipinlẹ kọọkan silẹ ni gbogbo ẹkun idibo mẹfa to wa ni Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti igbimọ naa fi lede, ibi ipade kan ti wọn ṣe lopin ọsẹ niluu Eko ni wọn ti fẹnuko lori igbesẹ naa lẹyin ti wọn gba aba lati da ipinlẹ tuntun marunlelaadọta silẹ kaakiri Naijiria.

Igbimọ naa tun yan igbimọ kekere mii lati ti yoo pinnu lori awọn agbegbe ti wọn yoo ti yọ awọn ipinlẹ tuntun ọhun sita ninu awọn ẹkun idibo mẹfa naa to wa ni Naijiria.

Ṣaaju ni igbimọ naa ti kọkọ fẹnuko pe awọn yoo ṣe afikun iye ipinlẹ to wa ni guusu ila oorun Naijiria ki iye ipinlẹ to wa nibẹ le pe mẹfa bii ti awọn akẹgbẹ rẹ.

Ipinlẹ marun un to wa ni iha naa lọwọ yii ni Abia, Anambra, Ebonyi, Enugu, ati ipinlẹ Imo.

Itan nipa idasilẹ awọn ipinlẹ ni Naijiria

Lati ibẹrẹ, agbegbe mẹta ni awọn oyinbo amunisin pin Naijiria si ko to di orilẹede to ni ipinlẹ mẹrindinlogoji lonii yii.

Gbogbo igba si ni awọn araalu maa n bere idasilẹ ipinlẹ tuntun lagbegbe wọn fun itẹsiwaju agbegbe naa, yala nipa ọrọ aje ni o tabi oṣelu.

Ki Naijiria to gba ominira lọdun 1960, agbege mẹta pere lo wa ni Naijiria: ariwa, ila oorun ati agbegbe iwọ oorun.

Lọdun naa lọhun, awọn agbegbe yii lo ni ominira ti wọn ti wọn si n ṣakoso lori awọn ohun alumọni ilẹ wọn funra wọn.

Amọ latari oṣelu ati agbara, ijọba Naijiria wọn pin agbegbe mẹta naa si wẹwẹ.

Idasilẹ ipinlẹ akọkọ lọdun 1963

Lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹjọ, ọdun 1963 ni wọn da agbegbe 'Mid-Western Region' lati ara agbegbe iwọ oorun Naijiria silẹ.

Eyii to mu ki gbogbo agbegbe Naijiria di mẹrin.

Igbesẹ naa ni a le pe ni idasilẹ ipinlẹ akọkọ laarin ọdun 1960 si ọdun 1966.

Ipinlẹ mejila lọdun 1967

Lẹyin iditẹgbajọba akọkọ ati ekeji ni ọgagun Yakubu Gowon wọgile ijọba ẹlẹkunjẹkun.

O wa ṣe idasilẹ ipinlẹ mejila lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 1967.

Awọn ipinlẹ mejila naa ree;

  • Ipinlẹ Iwọ oorun Ariwa Naijiria (North-Western state)
  • Ipinlẹ Aarin Gbungbun Ariwa Naijiria (North-Central state)
  • IpinlẹIla Oorun Ariwa Naijiria (North-Eastern state)
  • Ipinlẹ Kano
  • Ipinlẹ Benue ati Plateau
  • Ipinlẹ Kwara
  • Ipinlẹ Iwọ Oorun Naijiria (Western state)
  • Ipinlẹ Eko
  • Ipinlẹ Aarin Gbungbun Iwọ Oorun Naijiria (Mid-Western state)
  • Ipinlẹ Aarin Gbungbun Ila Oorun Naijiria (East-Central State)
  • Ipinlẹ Ila Oorun Iwọ Oorun Naijiria (South-Eastern State)
  • Ipinlẹ Rivers

Igbesẹ naa wa lara ohun to ṣokunfa ogun abẹle to waye lọdun 1967 si 1970.

Idi ni pe awọn kan ri idasilẹ awọn ipinlẹ naa bii igba ti wọn n fi ọwọ rọ ẹkun ila oorun Naijiria sẹyin.

Eyii to mu ki wọn gbiyanju lati piny,a ki wọn si da duro gẹgẹ bii orilẹede Biafra.

Wọn tun da ipinlẹ mọkandinlogun silẹ lọdun 1976

Lọna ati mu irẹpọ wa laarin awọn ọmọ Naijirai, ọgagun Muritala Muhammed da ipinlẹ meje tuntun mii silẹ lọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun 1976.

Lara awọn ipinlẹ to ti wa nilẹ tẹlẹ ni Muhamed ti yọ tuntun to si yi orukọ awọn kan pada, eyii to sọ gbogbo ipinlẹ Naijiria di mọkandinlogun nigba naa.

Awọn ipinlẹ naa ni:

  • Anambra
  • Bauchi
  • Bendel
  • Benue
  • Borno
  • Cross River
  • Gongola
  • Imo
  • Kaduna
  • Kano
  • Kwara
  • Eko
  • Niger
  • Ogun
  • Ondo
  • Oyo
  • Plateau
  • Rivers
  • Sokoto

Ipinlẹ mọkanlelogun tun jẹ dida silẹ lọdun 1987

Nigba ti yoo di ọdun 1987, Aarẹ ologun, Ibrahim Babangida da ipinlẹ meji tuntun mii silẹ lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 1987.

Awọn ipinlẹ meji ọhun ni ipinlẹ Akwa Ibom lati ara Cross River ati ipinlẹ Katsina to yọ lara ipinlẹ Kaduna.

Igbesẹ naa lo waye lọna ati fun awọn ẹya to kere lanfani si idagbasoke.

Ipinlẹ Ọgbọn ni wọn da silẹ lọdun 1991

Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 1991, Babangida tun fi kun awọn ipinlẹ to wa ni Naijiria.

Lọdun naa ni Naijiria ni ipinlẹ ọgbọn, awọn ipinlẹ naa ree:

  • Abia lati ara ipinlẹ Imo
  • Adamawa lati ara ipinlẹ Gongola
  • Delta lati ara ipinlẹ Bendel
  • Enugu lati ara ipinlẹ Anambra atijọ
  • Edo lati ara ipinlẹ Bendel
  • Jigawa lati ara ipinlẹ Kano
  • Kebbi lati ara ipinlẹ Sokoto
  • Kogi lati ara ipinlẹ Benue ati ipinlẹ Kwara
  • Osun lati ara ipinlẹ Oyo
  • Taraba lati ara ipinlẹ Gongola
  • Yobe lati ara ipinlẹ Borno

Ipinlẹ mọkandinlogoji lọdun 1996

Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 1996 ni ọgagun Sani Abacha kede awọn ipinlẹ mii, eyii to sọ apapọ ipinlẹ Naijira di iye to wa lonii yii.

Awọn ipinlẹ naa ni:

  • Bayelsa lati ara ipinlẹ Rivers
  • Ebonyi lati ara ipinlẹ Abia ati Enugu
  • Ekiti lati ara ipinlẹ Ondo
  • Gombe lati ara ipinlẹ Bauchi
  • Nasarawa lati ara ipinlẹ Plateau
  • Zamfara lati ara ipinlẹ Sokoto

Pẹlu iye ipinlẹ ti Naijiria ni lonii yii, gbogbo igba lawọn eeyan n tun n bere idasilẹ awọnn ipinlẹ tuntun mii fun idagbasoke agbegbe wọn.

Maapu to n ṣe afihan awọn ipinlẹ orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ṣaaju ninu ọdun 2025 yii ni Ile aṣoju-ṣofin l'Abuja ti pe fun idasilẹ ipinlẹ mọkanlelọgbọn mii lorilẹede Naijiria.

Wo ìpínlẹ̀ 55 tuntun tí ilé aṣòfin àgbà Naijiria ń dábàá fún ìdásílẹ̀ wọn

Igbakeji aarẹ ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja, Jibrin Barau, ti kede pe igbimọ ile to n ṣiṣẹ lori atunṣe iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 n ṣagbeyẹwo aba fun idasilẹ ipinlẹ marundinlọgọta tuntun.

Họnọrebu Barau tun sọ pe igbimọ naa tun n ṣe agbeyẹwo aba fun idasilẹ ijọba ibilẹ ọrin le lugba din meji (278) ati atunṣe ala meji.

Barau sọrọ yii lẹyin apero ọlọjọ meji ti igbimọ ile aṣofin agba mejeeji ṣe niluu Eko.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu atẹjade kan ti oludamọran rẹ lori eto iroyin ati ilukoro Ismail Mudashir fi sita, Barau sọ pe aba yii fi han pe ile aṣofin n gbiyanju lati ṣe atunṣe iwe ofin Naijiria lọna ti yoo fi ṣe anfaani fun araalu.

Igbakeji aarẹ ile igbimọ aṣoju-ṣofin wa rọ awọn akẹgbẹ rẹ lati fi akojọpọ atunṣe akọkọ lori iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 ranṣẹ sawọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ kaakiri orilẹede Naijiria.

''O ti to ọdun meji bayii ti a ti wa lori iṣẹ atunṣe iwe ofin Naijiria tọdun 1999.

A ti bawọn araalu, awọn alẹnulọrọ ati oniruuru igbimọ sọrọ kaakiri Naijiria lati mọ ero wọn lori awọn nnkan ti ile igbimọ aṣofin agba n gbero lati ṣatunṣe ninu iwe ofin Naijiria.

Ipe fun idasilẹ ipinlẹ tuntun marundinlọgọta, idasilẹ ijọba ibilẹ ọọrin le lugba din meji (278) ati atunṣe ala meji ni a n gbe yẹwo,'' Barau ṣalaye.

Barau to jẹ alaga igbimọ naa nile aṣofin agba sọ pe igbimọ ọhun yoo sọ imọran wọn fun ile aṣofin agba mejeeji kete ti wọn ba ti pari iṣẹ wọn.

Igbimọ ile aṣofin agba buwọlu idasilẹ ipinlẹ tuntun lẹkun ila oorun guusu Naijiria

Lara nnkan ti igbimọ to n ṣatunṣe iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 ni idasilẹ ipinlẹ mi lẹkun ila oorun guusu Naijiria ti i ṣe ilẹ ẹya Igbo.

Igbimọ naa sọ pe awọn eeyan ẹkun ila oorun guusu nilo ipinlẹ kan sii.

Idasilẹ ipinlẹ yii ni yoo jẹ ki ẹkun ila oorun guusu naa ni ipinlẹ mẹfa bii ẹkun iwọ oorun guusu, ẹkun aaringbungbun ariwa ati ẹkun ila oorun ariwa.

Bakan naa ni igbimọ ọhun tun dabaa fun idasilẹ ipinlẹ tuntun kaakiri awọn ẹkun to wa lorilẹede Naijiria.

Ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin lori ọrọ idasilẹ ipinlẹ tuntun ni Naijiria

Ṣaaju ninu ọdun 2025 yii ni Ile aṣoju-ṣofin l'Abuja ti pe fun idasilẹ ipinlẹ mọkanlelọgbọn mii lorilẹede Naijiria.

Igbimọ to n ri si atunṣe iwe ofin Naijiria nile lo ṣe agbekalẹ aba fun idasilẹ ipinlẹ mọkanlelọgbọn ọhun.

Ni Ọjọbọ ọjọ kẹfa oṣu Keji ni igbimọ naa gbe aba naa kalẹ niwaju ile ti wọn si ka a seti awọn ọmọ ile to wa ni ijokoo.

Igbakeji adari ile aṣoju-ṣofin, Benjamin Kalu lo dari ijokoo naa ni Ọjọbọ.

Alaga igbimọ naa sọ pe awọn ti da aba pe ki ijọba da ipinlẹ mẹfa tuntun silẹ ni ẹkun araringbungbun Naijiria, mẹrin mii ni ẹkun ila oorun ariwa.

O ni igbimọ naa tun da aba fun idasilẹ ipinlẹ marun un ni iwọ oorun ariwa, marun un ni ẹkun ila oorun guusu, mẹrin fun ẹkun guusu-guusu ati meje ni ẹkun iwọ ooru ariwa.

Ti ile igbimọ aṣofin agba ba buwọlu aba yii, eyi yoo tumọ si pe orilẹede Naijiria yoo ni ipinlẹ mẹtadinlaadọrin.

Ipinlẹ mẹtadinlaadọrin yii yoo ju ti orilẹede Amẹrika to ni aadọta ipinlẹ lọ.

Igbimọ to n ṣatunṣe iwe ofin Naijiria nile sọ ninu lẹta ti wọn ka niwaju ile pe ''a n fi asiko yii sọ fun ile wi pe igbimọ to n ri si atunṣe iwe ofin Naijiria ti gba ẹbẹ fun idasilẹ awọn ipinlẹ tuntun ati ijọba ibilẹ tuntun.

Wọnyi ni awọn ipinlẹ ti ile aṣoju ṣofin n da aba fun idasilẹ wọn ni ẹkun jẹkun

Ẹkun Ararin gbungbun Ariwa Naijiria(North-Central)

Ipinlẹ Benue Ala lati ara ipinlẹ Benue

Ipinlẹ Okun lati ara Kogi

Ipinlẹ Okura lati ara Kogi

Ipinlẹ Confluence lati ara Kogi

Ipinlẹ Apa-Agba lati ara Benue ati

Ipinlẹ Apa lati ara Benue

Ipinlẹ Olu ilu Naijiria Abuja

Ẹkun ila - Oorun Ariwa Naijiria (North East)

Ipinlẹ Amana lati ara Adamawa

Ipinlẹ Katagum lati ara Bauchi

Ipinlẹ Savannah lati ara Borno

Ipinlẹ Muri lati ara Taraba

Ẹkun Iwọ oorun - Ariwa (North West)

Ipinlẹ Kaduna tuntun lati ara Kaduna

Ipinlẹ Gurara lati ara Kaduna

Ipinlẹ Tiga lati ara Kano

Ipinlẹ Kainji lati ara Kebbi

Ipinlẹ Ghari lati ara Kano

Ẹkun Ila oorun - Guusu (South East)

Ipinlẹ Etiti ti yoo sikẹfa awọn ipinlẹ lati ẹkun ila oorun guusu Naijiria

Ipinlẹ Adada lati ara Enugu

Ipinlẹ Urashi

Ipinlẹ Orlu

Ipinlẹ Aba lati ara Abia

Ẹkun Aarin gbungbun Guusu Naijiria (South South)

Ipinlẹ Ogoja lati ara Cross River

Ipinlẹ Warri lati ara Delta

Ipinlẹ Bori lati ara Rivers

Ipinlẹ Obolo lati ara Rivers ati Akwa Ibom

Ẹkun Iwọ Oorun Guusu Naijiria (South West)

Ipinlẹ Toru-Ebe lati ara Delta, Edo ati Ondo

Ipinlẹ Ibadan lati ara Oyo

Ipinlẹ Lagoon lati ara Eko

Ipinlẹ Ijebu lati ara Ogun

Ipinlẹ Oke Ogun lati ara Oyo

Ipinlẹ Ife-Ijesha lati ara Oyo ati Osun