''Ẹ̀yin olùgbé bèbè omi l'Akute, Alagbole, Isheri, Magboro, Lefenwa àtàwọn ibòmíì l'Abeokuta, ẹ bìlà torí ẹ̀kún omi ń bọ̀''

Awọn ọdọkunrin n fi firiiji to ti bajẹ gbe arabinrin kan kọja lori omi latari ẹkun omi to waye nipinlẹ Ogun sẹyin
Àkọlé àwòrán, Kọmiṣọna fun ọrọ ayika nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Ola Oresanya, to fi ikede naa sita ṣalaye pe ẹkun omi yii maa n ṣẹlẹ nigba kugba ti wọn ba ti ṣi omi daamu Oyun eyi to maa n ṣan lọ si odo Ogun.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Ogun ti kilọ fawọn olugbe bebe omi lawọn agbegbe bii Akute, Alagbole, Isheri, Magboro, Makogi, Orimerunmu, Iro ati Kajola lati kuro ni ibugbe wọn fun igba diẹ tori ẹkun omi ọlọjọ mẹrinla to yoo ṣẹlẹ lati ogunjọ oṣu Kẹwaa yii titi di ọdọ kẹta oṣu Kọkanla to n bọ.

Ijọba ni ẹkun omi ọhun to n bọ lati odo Ogun yoo tun dawọn agbegbe kan bii Lafenwa, Enugada, Adedotun, Iberekodo, Akin-Olugbade ati Ago-Odo niluu Abeokuta gan an ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ogun.

Ikede yii wa lara akitiyan ijọba lati daabo bawọn olugbe bebe omi ti ẹkun omi to maa n ṣẹlẹ lati odo Ogun le ṣakoba fun nipinlẹ naa.

Kọmiṣọna fun ọrọ ayika nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Ola Oresanya, to fi ikede naa sita ṣalaye pe ẹkun omi yii maa n ṣẹlẹ nigba kugba ti wọn ba ti ṣi omi daamu Oyun eyi to maa n ṣan lọ si odo Ogun.

Kọmisọna fun ọrọ ayika ni arọọrọda ojo lati apa ariwa orilẹede Naijira lo maa n fa a ti daamu Oyun fi maa n kun akunwọsilẹ.

Kọmiṣọna rọ awọn olugbe agbegbe tọrọ kan lati fi ile wọn silẹ fun igba diẹ, ki wọn si lọ sibi to jina si bebe omi lasiko yii lati le dena ijamba to le ṣẹlẹ.

Ọgbẹni Oresanyi sọ pe lara nnkan ti ijọba ṣe lati daabo bawọn olugbe awọn agbegbe tọrọ kan ni gbigbẹ awọn odo ti omi maa n ṣan lọ lati odo Ogun ki omi to maa ya lu awọn ilegbee ma ba pọju.

Ọkunrin meji n rin ninu omi nibi iṣẹlẹ omiyale to waye ni ipinlẹ Ogun
Àkọlé àwòrán, Ikede yii wa lara akitiyan ijọba lati daabo bawọn olugbe bebe omi ti ẹkun omi to maa n ṣẹlẹ lati odo Ogun le ṣakoba fun nipinlẹ naa.

Kọmiṣọna ọrọ ayika ṣalaye siwaju sii pe bii miliọnu mẹtadinlogun lita omi ni wọn n ṣi lọjọ kan lati daamu Oyan ni iru akoko yii lọdun to kọja.

Amọ, kọmiṣọna ni ko ni ju miliọnu mejila lita omi ti wọn yoo maa ṣi lojumọ lọ bayii, eyi to tumọ si pe ẹkun omi ti ọdun yii le ma to ti ọdun to kọja bo tilẹ jẹ pe ojo rọ arọsẹyin.

Ọgbẹni Oresanya wa rọ awọn olugbe agbegbe tọrọ kan wi pe ki wọn ma bẹru, nitori omi naa maa lọọlẹ ni nnkan bii ọjọ mẹwaa si akoko yii.

Kọmiṣọna ni ijọba o lagbara lati da ẹkun omi yii duro tori ipinlẹ Ogun ni gbogbo omi to n bọ lati apa ariwa Naijiria maa n gba lọ sinu ọsa.

O wa rọ awọn to n sin ẹja lati kore ẹja wọn bayii ki omi maa ba gbe ẹja wọn lọ.