"Ìgbà tí mo wà l'ọ́mọdé ni a ti gbádùn iná ọba gbẹ̀yìn n'Ibarapa" - Eleruwa

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Abẹwo ti Minisita fun ohun amuṣagbara, Adebayo Adelabu, ṣe si agbegbe Ibarapa lọjọ meloo kan sẹyin lo tun wu ọrọ sita nipa ipenija ina mọnamọna to n koju awọn eeyan agbegbe Ibarapa n'ipinlẹ Oyo, to si jẹ pe ọpọlọpọ akọba ni ipenija yii ti ṣe fun eto ọrọ aje wọn.
Awọn ilu meje to parapọ di Ibarapa ni: Eruwa, Lanlate, Igboora, Idere, Ayete, Tapa, ati Igangan.
Yatọ si ina ọba to n ṣe ṣẹgeṣege, awọn ọna to yẹ ki ọkọ maa rin ni agbegbe naa ko tun ja geere.
Kayeefi to wa ninu iroyin yii ni pe awọn ọmọ bibi ilẹ Ibarapa kan ko tii gbadun ina ọba ati ọna to ja geere ri lati igba ti a ti bi wọn.
Eyi lo mu ki a kan si Kabiyesi Eleruwa ti ilu Eruwa, Ọba Samuel Adegbola lati beere bi nnkan ṣe ri, lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti n fi ara da iṣoro ina ọba ati ọna ti ko ṣe e rin.
Alaye ti Ọba Adegbola ṣe fun akọroyin wa ni pe ọpọ awọn aṣoju ijọba ti o ti re kọja lo ṣe ileri ti wọn ko si mu u ṣẹ, ṣugbọn awọn ko le di ẹbi ru ẹnikẹni.
Kabiyesi ni nnkan to ṣe pataki bayii ni ki awọn ti ọrọ naa kan ba wọn wa ojutuu si awọn ipenija to n koju ilẹ Ibarapa, bẹrẹ lati ibi ipese ina ọba oni odiwọn 32.KVA ti wọn sọ kalẹ si Lanlate ati Igangan.
"Ẹkọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń mú u wá ní Eruwa, ṣùgbọ́n lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, gbogbo Ibarapa méjèèje kò tiẹ̀ ríná lò rárá."

Oríṣun àwòrán, OTHERS
ni itẹsiwaju alaye rẹ, Kabiyesi Eleruwa ni
"Ina ọba fẹ ẹ kọja pe o n ṣe ṣegeṣege, a le sọ pe a ko ni rara ni Ibarapa.
"Ẹkọọkan, wọn maa n mu u wa ni Eruwa nibi ti a maa n ri i lo, ki i de gbogbo awọn ilu Ibarapa to ku, sugbọn lẹnu ọjọ mẹta yii, ati Eruwa o, ati Lanlate o, ati gbogbo Ibarapa mejeeje o, a ko tiẹ ri ina lo rara."
Ọba Adegbola tẹsiwaju pe ipenija yii ti di okunfa wahala ati idaamu fun igbayegbadun ọmọniyan ni agbegbe naa.
A beere lọwọ Kabiyesi boya akọsilẹ tiẹ wa ninu itan pe Ibarapa ti gbadun ina ọba ri fun ọsẹ kan gbako, wọn ni," Mi o ri iru ẹ ri, boya nigba ti mo kere ti mi o da nnkan kan mọ. Pe ina maa wa fun odidi ọṣẹ kan ti ko ni ṣẹju? Mi o tiẹ ri oni ọjọ mẹta ri ti ko ṣẹju."
Ọba Adegbọla ni aisi ina ọba ni agbegbe naa ti mu ki eto ọrọ aje dẹnu kọlẹ, nitori ti ko ba si ina, bi ẹni pe ko si igbayegbadun rara ni pẹlu bi o ṣe jẹ pe gbogbo iṣẹ ti awọn eeyan n ṣe lo nilo ina ọba.
Ninu ọrọ ti Adelabu sọ lasiko abẹwo rẹ, o se ileri pe oun ṣetan lati fopin si ipenija ọlọdun mẹẹẹdogun to n ba ina ọba finra ni agbegbe naa.
Adelabu ni laipẹ, awọn eeyan Ibarapa yoo bẹrẹ si i ri ayipada lori ọwọja ipese ina ọba ni agbegbe wọn, nitori ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ to n risi ipese ina ọba ti tẹwọgba owo iranwọ ti yoo jẹ lilo fun aṣeyọri iṣẹ ni awọn ibudo ohun amuṣagbara mẹta ọtọọtọ to n bẹ ni agbegbe naa.
Lasiko to n fesi lori ileri Minisita fun ohun amuṣagbara naa, Eleruwa ni iroyin to daa ni pe wọn ti fẹ mu oke iṣoro agbegbe naa kuro ti o si le mu ki eeyan gbe ilu sẹyin ki o maa jo.
Kabiyesi gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki wọn le mu ileri naa ṣẹ ti ko si ni jẹ afẹnusọ lasan.














